Beginning
Ìyọnu Eṣú
10 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, mo ti ṣé àyà Farao le àti àyà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kí èmi kí o ba le ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrín wọn. 2 Kí ẹ̀yin ki ó le sọ fún àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ ọmọ yín; Bí mo ti jẹ àwọn ará Ejibiti ní yà àti bí mo ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn. Kí ìwọ ba á le mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”
3 Nígbà náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, tiwọn sí wí fún un pé, “Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run àwọn Heberu sọ: ‘Yóò ti pẹ́ to ti ìwọ yóò kọ̀ láti tẹrí ara rẹ ba ní iwájú mi? Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó sìn mi. 4 Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn lọ, èmi yóò mú eṣú wa sí orílẹ̀-èdè rẹ ní ọ̀la. 5 Wọn yóò bo gbogbo ilẹ̀. Wọn yóò ba ohun gbogbo tí ó kù fún ọ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́, tí ó fi dórí gbogbo igi tí ó ń dàgbà ni ilẹ̀ rẹ. 6 Wọn yóò kún gbogbo ilé rẹ àti ilé àwọn ìjòyè rẹ àti ilé gbogbo àwọn ará Ejibiti. Ohun ti baba rẹ tàbí baba baba rẹ kò tí ì rí láti ìgbà tí wọ́n ti wà ní ilẹ̀ náà títí di àkókò yìí.’ ” Nígbà náà ni Mose pẹ̀yìndà kúrò níwájú Farao.
7 Àwọn ìjòyè Farao sọ fún un “Yóò ti pẹ́ to tí ọkùnrin yìí yóò máa jẹ́ ìkẹ́kùn fún wa? Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí lọ, kí wọn kí ó le sìn Olúwa Ọlọ́run wọn. Ṣe ìwọ kò ṣe àkíyèsí síbẹ̀ pé, ilẹ̀ Ejibiti ti parun tán?”
8 Nígbà náà ni a mú Aaroni àti Mose padà wá sí iwájú Farao ó sì wí fún wọn pé “Ẹ lọ sìn Olúwa Ọlọ́run yín. Ṣùgbọ́n àwọn ta ni nínú yín ni yóò ha lọ.”
9 Mose dáhùn ó wí pé, “A ó lọ pẹ̀lú àwọn ọmọdé àti àgbà wa, pẹ̀lú àwọn ọmọ wa ọkùnrin àti ọmọ wa obìnrin pẹ̀lú agbo àgùntàn wa àti agbo màlúù wa nítorí pé a gbọdọ̀ ṣe àjọ fún Olúwa.”
10 Farao sì wí pé, “Mo fi Olúwa búra pé èmi kí yóò jẹ́ kí ẹ lọ, pẹ̀lú àwọn obìnrin yín àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, dájúdájú èrò ibi ní ń bẹ nínú yín. 11 Rárá! Ọkùnrin yín nìkan ni kí ó lọ, láti lọ sin Olúwa, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé èyí ni ẹ̀yin ń béèrè fún.” Wọ́n sì lé Mose àti Aaroni kúrò ní iwájú Farao.
12 Ní ìgbà náà ni Ọlọ́run sọ fún Mose, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè lórí Ejibiti kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣú bo gbogbo ilẹ̀, kí ó sì ba gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko wọn jẹ́, àní gbogbo ohun tí òjò yìnyín kò bàjẹ́ tan.”
13 Nígbà náà ni Mose na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ sórí ilẹ̀ Ejibiti, Olúwa sì mú kí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn fẹ́ kọjá lórí ilẹ̀ náà ni gbogbo ọ̀sán àti ni gbogbo òru ni ọjọ́ náà. Ní òwúrọ̀ afẹ́fẹ́ náà ti gbá ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣú wá; 14 (A)Wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n wà ní ibi gbogbo ní orí ilẹ̀ ní àìmoye, ṣáájú àkókò yìí kò sí irú ìyọnu eṣú bẹ́ẹ̀ rí, kò sì ní sí irú rẹ mọ́ lẹ́yìn èyí. 15 Wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ tí ilẹ̀ fi di dúdú. Wọ́n ba gbogbo ohun tókù ní orí ilẹ̀ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́; gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ní inú oko àti gbogbo èso tí ó wà lórí igi. Kò sí ewé tí ó kù lórí igi tàbí lórí ohun ọ̀gbìn ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.
16 Farao yára ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín àti sí i yín pẹ̀lú. 17 Nísinsin yìí ẹ dáríjì mi lẹ́ẹ̀kan sí i kí ẹ sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín kí ó lè mú ìpọ́njú yìí kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.”
18 Nígbà náà ni Mose kúrò ní iwájú Farao ó sì gbàdúrà sí Olúwa. 19 Olúwa sì yí afẹ́fẹ́ náà padà di afẹ́fẹ́ líle láti apá ìwọ̀-oòrùn wá láti gbá àwọn eṣú náà kúrò ní orí ilẹ̀ Ejibiti lọ sínú Òkun pupa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ eṣú kan kò ṣẹ́kù sí orí ilẹ̀ Ejibiti. 20 Síbẹ̀ Olúwa ṣe àyà Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ.
Òkùnkùn bo ilẹ̀
21 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run kí òkùnkùn bá à le bo gbogbo ilẹ̀ Ejibiti; àní òkùnkùn biribiri.” 22 (B)Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run, òkùnkùn biribiri sì bo gbogbo ilẹ̀ Ejibiti fún ọjọ́ mẹ́ta. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli ní ìmọ́lẹ̀ ní ibi tí wọn ń gbé. 23 Kò sí ẹni tí ó le è ríran rí ẹlòmíràn tàbí kí ó kúrò ní ibi tí ó wà fún ọjọ́ mẹ́ta. Síbẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli ni ìmọ́lẹ̀ ni gbogbo ibi tí wọ́n ń gbé.
24 Farao sì ránṣẹ́ pe Mose ó sì wí fún un pé, “Lọ sin Olúwa, kódà àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé lè lọ pẹ̀lú yín, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó fi agbo àgùntàn àti agbo màlúù yín sílẹ̀.”
25 Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Ìwọ gbọdọ̀ fún wa láààyè láti rú ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ sísun ní iwájú Olúwa Ọlọ́run wa. 26 Àwọn ohun ọ̀sìn wa gbọdọ̀ lọ pẹ̀lú wa, a kì yóò fi pátákò ẹsẹ̀ ẹran sílẹ̀. A ní láti lò lára wọn fún sínsin Olúwa Ọlọ́run wa, ìgbà tí a bá sì dé ibẹ̀ ni a ó to mọ̀ ohun ti a ó lò láti fi sin Olúwa.”
27 Ṣùgbọ́n Olúwa sé ọkàn Farao le, kò sì ṣetán láti jẹ́ kí wọn lọ. 28 Farao sọ fún Mose pé, “Kúrò ní iwájú mi! Rí i dájú pé o kò wá sí iwájú mi mọ́! Ọjọ́ tí ìwọ bá rí ojú mi ni ìwọ yóò kùú.”
29 Mose sì dáhùn pé, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wí, “Èmi kí yóò wá sí iwájú rẹ mọ́.”
Ikú àwọn àkọ́bí
11 Nísinsin yìí, Olúwa sọ fún Mose pé èmi yóò mú ààrùn kan sí i wá sí orí Farao àti ilẹ̀ Ejibiti. Lẹ́yìn náà yóò jẹ́ kí ẹ̀yin kí ó lọ kúrò níhìn-ín yìí, nígbà tí ó bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ yóò lé yín jáde pátápátá. 2 Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé kí tọkùnrin tobìnrin wọn béèrè fún ohun èlò fàdákà àti wúrà lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀. 3 (Olúwa jẹ́ kí wọn rí ojúrere àwọn ará Ejibiti, pàápàá, Mose fúnrarẹ̀ di ènìyàn pàtàkì ní ilẹ̀ Ejibiti ní iwájú àwọn ìjòyè Farao àti ní iwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú).
4 Nígbà náà ni Mose wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ‘Ní ọ̀gànjọ́ òru èmi yóò la ilẹ̀ Ejibiti kọjá. 5 Gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti ni yóò kùú, bẹ̀rẹ̀ lórí àkọ́bí ọkùnrin Farao tí ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, tí ó fi dé orí àkọ́bí ọmọkùnrin ti ẹrúbìnrin tí ń lọ ọlọ àti gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú. 6 Igbe ẹkún ńlá yóò sọ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Irú ohun búburú tí kò ṣẹlẹ̀ rí tí kò sí tún ni ṣẹlẹ̀ mọ́. 7 Ṣùgbọ́n láàrín àwọn ará Israẹli ajá lásán kò ní gbó àwọn ènìyàn tàbí àwọn ẹran wọn.’ Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ti fi ìyàtọ̀ sáàrín àwọn ará Ejibiti àti Israẹli. 8 Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ wọ̀nyí yóò tọ̀ mí wá, wọn yóò wólẹ̀ ni iwájú, mi wọn yóò sì máa wí pé, ‘Lọ àti àwọn ènìyàn tí ó tẹ̀lé ọ!’ Lẹ́yìn náà èmi yóò jáde.” Nígbà náà ni Mose fi ìbínú jáde kúrò ní iwájú Farao.
9 Olúwa ti sọ fún Mose pé, “Farao yóò kọ̀ láti fetísílẹ̀ sí ọ kí iṣẹ́ ìyanu mí le pọ̀ sí ní Ejibiti.” 10 Mose àti Aaroni ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí níwájú Farao, ṣùgbọ́n Olúwa sé ọkàn Farao le, òun kò sí jẹ́ kí àwọn Israẹli jáde kúrò ni orílẹ̀-èdè rẹ̀.
Àjọ ìrékọjá
12 (C)Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni ni ilẹ̀ Ejibiti pé, 2 “Oṣù yìí ni yóò jẹ́ oṣù àkọ́kọ́ fún yín, oṣù àkọ́kọ́ nínú ọdún yín. 3 Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli pé ni ọjọ́ kẹwàá oṣù yìí, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan yóò mú ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan fún ìdílé rẹ̀, ọ̀kan fún agbo ilé kọ̀ọ̀kan. 4 Bí ìdílé kan bá kéré jù fún odidi ọ̀dọ́-àgùntàn kan, kí wọn kí ó ṣe àjọpín ọ̀kan pẹ̀lú aládùúgbò wọn ti ó sun mọ́ wọn kí wọ́n lo iye ènìyàn tiwọn jẹ láti ṣe òdínwọ̀n irú ọ̀dọ́-àgùntàn tiwọn yóò lò ní ìbámu pẹ̀lú ìwọ̀n ti ẹni kọ̀ọ̀kan lè jẹ. 5 Ọ̀dọ́-àgùntàn tí ìwọ yóò mú gbọdọ̀ jẹ́ akọ ọlọ́dún kan tí kò lábùkù, ìwọ lè mú lára àgbò tàbí ewúrẹ́. 6 Ṣe ìtọ́jú wọn títí di ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli yóò pa ẹran náà ní àfẹ̀mọ́júmọ́. 7 Wọn yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò fi kan ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àti òkè ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé níbi tí wọ́n bá ti jẹ ẹran ọ̀dọ́-àgùntàn náà. 8 Ní òru ọjọ́ kan náà, wọn yóò jẹ ẹran tí a ti fi iná sun, pẹ̀lú ewé ewúro àti àkàrà aláìwú. 9 Ẹ má ṣe jẹ ẹran náà ni tútù tàbí ní bíbọ̀ nínú omi, ṣùgbọ́n kí ẹ fi iná sun orí, ẹsẹ̀ àti àwọn nǹkan inú ẹran náà. 10 Ẹ má ṣe fi èyíkéyìí sílẹ̀ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí ó bá ṣẹ́kù di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ẹ jó o níná. 11 Báyìí ni ẹ̀yìn yóò ṣe jẹ́ tí ẹ̀yin ti àmùrè ní ẹ̀gbẹ́ yín, sáńdà yín ní ẹsẹ̀ yín àti ọ̀pá yín ni ọwọ́ yín. Ẹ yára jẹ ẹ́, oúnjẹ àjọ ìrékọjá Olúwa ni.
12 “Ní òru ọjọ́ yìí kan náà ni Èmi yóò la gbogbo ilẹ̀ Ejibiti kọjá, èmi yóò sì pa gbogbo àkọ́bí àti ènìyàn, àti ẹranko, èmi yóò mú ìdájọ́ wà sí orí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Ejibiti. Èmi ni Olúwa.” 13 Ẹ̀jẹ̀ ni yóò jẹ́ ààmì fún un yín ní àwọn ilé tí ẹ̀yin wà, nígbà tí èmi bá rí ẹ̀jẹ̀ náà, Èmi yóò ré e yín kọjá. Ààrùn kan kì yóò kàn yín nígbà tí èmi bá kọlu Ejibiti láti pa wọ́n run.
14 (D)“Ọjọ́ òní ni yóò sì máa ṣe ọjọ́ ìrántí fún yín, ẹ́yin yóò sì máa láàrín àwọn ìran tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn ni ẹ̀yin yóò ti máa ṣe ní àjọ fún Olúwa; ní ìran-ìran yín bí ìlànà tí yóò wà títí ayé. 15 Fún ọjọ́ méje ni ẹ̀yin yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, ẹ ó gbé ìwúkàrà kúrò ni ilé yín, nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú láti ọjọ́ kìn-ín-ní di ọjọ́ keje ni kí a yọ kúrò ni Israẹli. 16 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; àti ní ọjọ́ keje àpéjọ mímọ́ mìíràn yóò wà fún yín. Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, bí kò ṣe oúnjẹ tí olúkúlùkù yóò jẹ; kìkì èyí ni gbogbo ohun tí ẹ̀yin lè ṣe.
17 “Ẹ ó sì kíyèsí àjọ àìwúkàrà, nítorí ní ọjọ́ náà gan an ni mo mú ogun yín jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. Nítorí náà ni kí ẹ máa kíyèsi ọjọ́ náà ní ìran-ìran yín bí ìlànà tí yóò wà títí ayé. 18 Àkàrà ti kò ni ìwúkàrà ni ẹ̀yin yóò jẹ láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀kànlélógún oṣù àkọ́kọ́. 19 Fún ọjọ́ méje ni ẹ kò gbọdọ̀ ni ìwúkàrà nínú ilé yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó ni ìwúkàrà nínú ni a ó yọ kúrò ni àárín àwùjọ Israẹli, ìbá à ṣe àlejò tàbí ẹni tí a bí ní ilẹ̀ náà. 20 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe. Ní ibikíbi tí ẹ̀yin bá ń gbé, kí ẹ̀yin kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.”
21 Ní ìgbà náà ni Mose pé gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ jáde lọ, kí ẹ sì yan ọ̀dọ́-àgùntàn fún àwọn ìdílé yín, kí ẹ sì pa ẹran àjọ ìrékọjá Olúwa. 22 Ẹ̀yin yóò sì mú ìdí-ewé hísópù, ẹ tì í bọ inú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà nínú ọpọ́n kí ẹ sì fi kun òkè à bá wọ ẹnu-ọ̀nà ilé yín àti ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìlẹ̀kùn yín. Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ jáde sí òde títí di òwúrọ̀. 23 (E)Ní ìgbà tí Olúwa bá ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Ejibiti láti kọlù wọn, yóò rí ẹ̀jẹ̀ ni òkè ẹnu-ọ̀nà àti ni ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà ilé yín, yóò sì ré ẹnu-ọ̀nà ilé náà kọjá, kì yóò gba apanirun láààyè láti wọ inú ilé e yín láti kọlù yín.
24 “Ẹ pa ìlànà yìí mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ ó máa ṣe títí ayérayé láàrín yín àti àwọn ìran yín. 25 Nígbà tí ẹ̀yin bá de ilẹ̀ tí Olúwa yóò fi fún un yín bí òun ti ṣe ìlérí, ẹ máa kíyèsi àjọ yìí. 26 Ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín, ‘Kí ni ohun tí àjọ yìí túmọ̀ sí fún un yín?’ 27 Ẹ sọ fún wọn ni ìgbà náà, ‘Ẹbọ ìrékọjá sí Olúwa ni, ẹni tí ó rékọjá ilé àwọn ọmọ Israẹli ni ìgbà tí ó kọlu àwọn ara Ejibiti. Tí ó si da wa sí nígbà ti ó pa àwọn ara Ejibiti.’ ” Àwọn ènìyàn sì tẹríba láti sìn. 28 Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose àti Aaroni.
29 (F)Ní ọ̀gànjọ́ òru Olúwa kọlu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ejibiti, láti orí àkọ́bí. Farao tí ó wà ní orí ìtẹ́ títí dé orí àkọ́bí ẹlẹ́wọ̀n tí ó wà nínú túbú àti àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú. 30 Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn ara Ejibiti dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, igbe ẹkún ńlá sì gba gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, nítorí kò sí ilé kan tí ó yọ sílẹ̀ tí ènìyàn kan kò ti kú.
Ìjáde lọ
31 Farao sì ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni ní òru, ó sì wí pé, “Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin àti àwọn ènìyàn Israẹli! Ẹ lọ láti sin Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹ ti béèrè. 32 Ẹ kó agbo àgùntàn yín àti agbo màlúù yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti sọ, kí ẹ sì máa lọ, kí ẹ sì súre fún mi.”
33 Àwọn ara Ejibiti ń rọ àwọn ènìyàn náà láti yára máa lọ kúrò ní ilẹ̀ wọn. Wọ́n wí pé, “Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ gbogbo wa ni yóò kú!” 34 Àwọn ènìyàn náà sì mú ìyẹ̀fun púpọ̀ kí wọn tó fi ìwúkàrà sí i, wọ́n gbe le èjìká wọn nínú ọpọ́n tí wọ́n ti fi aṣọ dì. 35 (G)Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ti sọ fún wọn. Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ ará Ejibiti fún ohun èlò fàdákà àti wúrà àti fún aṣọ pẹ̀lú. 36 Olúwa ti mú kí àwọn ènìyàn yìí rí ojúrere àwọn ará Ejibiti wọ́n sì fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún, wọ́n sì ko ẹrù àwọn ará Ejibiti.
37 Àwọn ọmọ Israẹli sì rìn láti Ramesesi lọ sí Sukkoti. Àwọn ọkùnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rìn tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ni iye láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé. 38 Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn ni ó bá wọ́n lọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn, agbo àgùntàn àti agbo màlúù. 39 Pẹ̀lú ìyẹ̀fun tí kò ní ìwúkàrà nínú tí wọ́n gbé jáde láti Ejibiti wá ni wọ́n fi ṣe àkàrà aláìwú. Ìyẹ̀fun náà kò ni ìwúkàrà nínú nítorí a lé wọn jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wọn kò si rí ààyè láti tọ́jú oúnjẹ fún ara wọn.
40 (H)Iye ọdún ti àwọn ará Israẹli gbé ní ilẹ̀ Ejibiti jẹ́ irínwó ọdún ó-lé-ọgbọ̀n (430). 41 (I)Ó sì ní òpin irínwó ọdún ó le ọgbọ̀n (430), ní ọjọ́ náà gan an, ni ó sì ṣe tí gbogbo ogun Olúwa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti. 42 Nítorí pé, Olúwa ṣe àìsùn ni òru ọjọ́ náà láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ní òru yìí ni gbogbo Israẹli ní láti máa ṣe àìsùn láti fi bu ọlá fún Olúwa títí di àwọn ìran tí ń bọ̀.
Òfin Àjọ ìrékọjá
43 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Ìwọ̀n yìí ni àwọn òfin fún àjọ ìrékọjá:
“Àjèjì kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀. 44 Ẹrú tí ẹ̀yin bá rà lè jẹ́ nínú rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ̀yin bá ti kọ ọ́ ní ilà, 45 Ṣùgbọ́n àtìpó àti alágbàṣe kò ni jẹ nínú rẹ̀.
46 (J)“Nínú ilé ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ ẹ́; ẹ kò gbọdọ̀ mú èyíkéyìí nínú ẹran náà jáde kúrò nínú ilé. Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan nínú egungun rẹ̀. 47 Gbogbo àjọ Israẹli ni ó gbọdọ̀ ṣe àjọyọ̀ ọ rẹ̀.
48 “Àjèjì ti ó bá ń gbé ní àárín yín ti ó bá fẹ́ kópa nínú àjọ ìrékọjá Olúwa, ni o gbọdọ̀ kọ gbogbo àwọn ọmọkùnrin ilé rẹ̀ ní ilà; ní ìgbà náà ni ó lè kó ipa gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí a bí ní ilẹ̀ náà. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí a kò bá kọ ní ilà, wọ́n kò ni jẹ nínú rẹ̀. 49 (K)Òfin yìí kan náà ni ó mú àwọn ọmọ tí a bí ni ilẹ̀ náà àti àwọn àlejò tí ń gbé ní àárín yín.”
50 Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose àti Aaroni. 51 Àti pé ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti gẹ́gẹ́ bí ìpín ìpín wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.