Book of Common Prayer
Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ.
34 Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo;
ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.
2 Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa;
jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.
3 Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi;
kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.
4 Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;
Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.
5 Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;
ojú kò sì tì wọ́n.
6 Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀;
ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
7 Angẹli Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká
ó sì gbà wọ́n.
8 Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;
ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.
9 Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́,
nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
10 Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;
ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.
11 Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;
èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.
12 (A)Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;
kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?
13 Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi
àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.
14 Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere;
wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.
15 Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;
etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn.
16 Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú;
láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
17 Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́,
Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.
18 Olúwa súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;
ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.
19 Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀,
ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.
20 Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́;
kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.
21 Ibi ni ó mú ikú ìkà wá,
àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi.
22 Olúwa ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà;
kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.
Ìránṣẹ́ Olúwa Náà
49 (A)Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù:
gbọ́ èyí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré:
kí a tó bí mi Olúwa ti pè mí;
láti ìgbà bíbí mi ni ó ti dá orúkọ mi.
2 Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n,
ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́:
ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán,
ó sì fi mí pamọ́ sínú àpò rẹ̀.
3 Ó sọ fún mi pé, “ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe,
Israẹli nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn.”
4 (B)Ṣùgbọ́n èmi sọ pé, “Mo ti ṣe wàhálà lórí asán;
mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀mófo.
Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi ṣì wà lọ́wọ́ Olúwa,
èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi.”
5 Nísinsin yìí Olúwa wí pé
ẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀
láti mú Jakọbu padà tọ̀ mí wá
àti láti kó Israẹli jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,
nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú Olúwa
Ọlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi
6 (C)Òun wí pé:
“Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ mi
láti mú ẹ̀yà Jakọbu padà bọ̀ sípò
àti láti mú àwọn ti Israẹli tí mo ti pamọ́.
Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn kèfèrí,
kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wá
sí òpin ilẹ̀ ayé.”
Àwọn aposteli Kristi
4 (A)Nítorí náà, ṣe ló yẹ kí ènìyàn máa wò wá gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ àti ìríjú tí a fún ni oore-ọ̀fẹ́ láti mọ Kristi tí a fún ní oore-ọ̀fẹ́ láti mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run. 2 Òun kan náà tí ó tọ́ fún ìríjú, ni kí ó jẹ́ olóòtítọ́. 3 Ṣùgbọ́n ohun kíkíní ni fún mi pé, kí ẹ máa ṣe ìdájọ́ mi, tàbí kí a máa ṣe ìdájọ́ nípa ìdájọ́ ènìyàn; nítòótọ́, èmi kò tilẹ̀ dá ara mi lẹ́jọ́. 4 (B)Nítorí tí ẹ̀rí ọkàn mi kò dá mi ní ẹ̀bi; ṣùgbọ́n a kò ti ipa èyí dá mi láre, ṣùgbọ́n Olúwa ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ mi. 5 (C)Nítorí náà, kí ẹ má ṣe ṣe ìdájọ́ ohunkóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó fi ara sin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olúkúlùkù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
6 (D)Ẹ kíyèsi i pé, mo ti fi ara mi àti Apollo ṣe àpẹẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe tìtorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.” 7 Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, èétiṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á?
8 Ni báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba. Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn. Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtítọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín: tí a ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú yín! 9 (E)Nítorí mo rò pé Ọlọ́run ń fi àwa aposteli hàn ní ìkẹyìn bí ẹni tí a dá lẹ́bi ikú bí àwọn, nítorí tí a fi wá ṣe ìran wò fún àwọn ènìyàn àti àwọn angẹli àti gbogbo ayé. 10 (F)Àwa jẹ́ aṣiwèrè nítorí Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú Kristi! Àwa jẹ́ aláìlera, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ẹni àyẹ́sí, àwa jẹ ẹni ẹ̀gàn! 11 (G)Títí di wákàtí yìí ni a ń rìn kiri nínú ebi àti òǹgbẹ, a n wọ aṣọ àkísà, tí a sì ń lù wa, tí a kò sì ní ibùgbé kan. 12 (H)Tí a ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́, wọn ń gàn wa, àwa ń súre, wọn ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń forítì i. 13 Wọn ń kẹ́gàn wa, àwa ń bẹ̀bẹ̀. Títí di ìsinsin yìí ni a ti wà bí ohun ẹ̀gbin ayé, bí orí àkìtàn gbogbo ayé.
14 Èmi kò kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí láti fi dójútì yín, ṣùgbọ́n láti kìlọ̀ fún un yín bí àwọn ọmọ mi tí mo yàn fẹ́. 15 (I)Nítorí bí ẹ̀yin tilẹ̀ ní ẹgbàárùn-ún olùkọ́ni nínú Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ni baba púpọ̀; nítorí nínú Kristi Jesu ni mo jẹ́ baba fún un yín nípasẹ̀ ìhìnrere. 16 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ máa ṣe àfarawé mi.
96 (A)Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa:
Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.
2 Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀
ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́
3 Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.
4 Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;
òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ
5 Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè
ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run
6 Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀
agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.
7 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn
Ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa
8 Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;
ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀
9 Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;
ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.
10 Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba”
a fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí;
ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.
11 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo
jẹ́ kí pápá Òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun
gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.
12 Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀
àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀:
nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀
13 Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,
nítorí tí ó ń bọ̀ wá,
Ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé
yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé
àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.
Saamu. Fún ọpẹ́
100 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé
2 Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa:
Ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn
3 Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,
kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé
tirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn rẹ̀
àti àgùntàn pápá rẹ̀.
4 Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;
ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.
5 Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore
ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;
àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu àkọ́kọ́
35 (A)Ní ọjọ́ kejì, Johanu dúró pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 36 Nígbà tí ó sì rí Jesu bí ó ti ń kọjá lọ, ó wí pé, “Wò ó Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run!”
37 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì gbọ́ ohun tí ó wí yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì í tọ Jesu lẹ́yìn. 38 Nígbà náà ni Jesu yípadà, ó rí i pé wọ́n ń tọ òun lẹ́yìn, ó sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin ń wá?”
Wọ́n wí fún un pé, “Rabbi” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe Olùkọ́ni), “Níbo ni ìwọ ń gbé?”
39 Ó wí fún wọn pé, “Ẹ wá wò ó, ẹ̀yin yóò sì rí i.”
Wọ́n sì wá, wọ́n sì rí ibi tí ó ń gbé, wọ́n sì wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà. Ó jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹwàá ọjọ́.
40 (B)Anderu arákùnrin Simoni Peteru jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, tí ó sì tọ Jesu lẹ́yìn. 41 (C)Ohun àkọ́kọ́ tí Anderu ṣe ni láti wá Simoni arákùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí Messia” (ẹni tí ṣe Kristi). 42 (D)Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jesu.
Jesu sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Peteru).
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.