Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 1-4

ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ

Saamu 1–41

(A)Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
    tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
    tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa
    àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
    tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
    Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!
    Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà
    tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.

Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,
    ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
(B)Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀,
    àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?
Àwọn ọba ayé péjọpọ̀
    àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀
    Olúwa àti sí Ẹni ààmì òróró rẹ̀.
Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já,
    kí a sì ju ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”

Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín;
    Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀
    yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,
“Èmi ti fi ọba mi sí ipò
    lórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”

(C)Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa:

Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;
    lónìí, èmi ti di baba rẹ.
(D)Béèrè lọ́wọ́ mi,
    Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ,
    òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.
Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn
    ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”

10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n;
    ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.
11 Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rù
    ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.
12 Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú,
    kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín,
nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan.
    Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.

Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu.

Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí!
    Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé
    “Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.

Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;
    ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
Olúwa ni mo kígbe sókè sí,
    ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.

Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;
    mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.
Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn
    tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.

Dìde, Olúwa!
    Gbà mí, Ọlọ́run mi!
Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;
    kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.

Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.
    Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Dafidi.

Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,
    ìwọ Ọlọ́run òdodo mi,
Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi;
    ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.

Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú?
    Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké?
Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀;
    Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.

(E)Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀;
    Nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín,
    ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.
Ẹ rú ẹbọ òdodo
    kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wa?”
    Olúwa, Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,
Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi
    ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.

Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà,
    nítorí ìwọ nìkan, Olúwa, ni o
    mú mi gbé láìléwu.

Saamu 7

Ṣiggaioni ti Dafidi, èyí tí ó kọ sí Olúwa nípa Kuṣi, ará Benjamini.

Olúwa Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ;
    gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi,
kí wọn ó má ba à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún,
    wọ́n á ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gbà mí.

Olúwa Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí
    tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi
Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,
    tí mo ja ọ̀tá mi lólè láìnídìí:
Nígbà náà, jẹ́ kí ọ̀tá mi lé mi kí wọn sì mú mi;
    jẹ́ kí òun kí ó tẹ ọkàn mi mọ́lẹ̀
    kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. Sela.

Dìde, Olúwa, nínú ìbínú rẹ;
    dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀tá mi.
    Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo.
Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yíká.
    Jọba lórí wọn láti òkè wá;
    Jẹ́ kí Olúwa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.
Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,
    gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ.
(A)Ọlọ́run Olódodo,
    Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn,
tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú
    tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́.

10 Ààbò mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
    ẹni tí ń ṣe ìgbàlà òtítọ́ ní àyà.
11 Ọlọ́run ni onídàájọ́ òtítọ́,
    Ọlọ́run tí ń sọ ìrunú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.
12 Bí kò bá yípadà,
    Òun yóò pọ́n idà rẹ̀ mú;
    ó ti fa ọrun rẹ̀ le ná, ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀.
13 Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀;
    ó ti pèsè ọfà iná sílẹ̀.

14 Ẹni tí ó lóyún ohun búburú,
    tí ó sì lóyún wàhálà, ó bí èké jáde.
15 Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde
    jì sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀.
16 Wàhálà tí ó fà padà sórí rẹ̀;
    Ìwà ipá rẹ̀ padà sórí ara rẹ̀.

17 Èmi ó fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí òdodo rẹ̀,
    Èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa Ọ̀gá-ògo jùlọ.

Òwe 3:11-20

11 (A)Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwa
    má sì ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,
12 Nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí
    bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.

13 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,
    ẹni tí ó tún ní òye sí i
14 Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ
    ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.
15 Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;
    kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.
16 Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;
    ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.
17 Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura,
    òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.
18 Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á;
    àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.

19 Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;
20 Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà,
    àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.

1 Johanu 3:18-4:6

18 (A)Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ni ìṣe àti ní òtítọ́.

19 Àti nípa èyí ni àwa ó mọ̀ pé àwa jẹ́ ti òtítọ́, àti pé àwa ó sì fi ọkàn ara wa balẹ̀ níwájú rẹ̀. 20 Nínú ohunkóhun tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi; nítorí pé Ọlọ́run tóbi ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo. 21 (B)Olùfẹ́, bí ọkàn wa kò bá dá wa lẹ́bi, ǹjẹ́ àwa ni ìgboyà níwájú Ọlọ́run? 22 Àti ohunkóhun tí àwa bá béèrè, ni àwa ń rí gbà lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí tí àwa ń pa òfin rẹ̀ mọ́, àwa sì ń ṣe àwọn nǹkan tí ó dára lójú rẹ̀. 23 (C)Èyí sì ni òfin rẹ̀, pé kí àwa gba orúkọ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ gbọ́, kí a sì fẹ́ràn ara wá gẹ́gẹ́ bí ó tí fi òfin fún wa. 24 (D)Ẹni tí ó bá sì pa òfin rẹ̀ mọ́ ń gbé inú rẹ̀, àti òun nínú rẹ̀. Àti nípa èyí ni àwa mọ̀ pé ó ń gbé inú wa, nípa Ẹ̀mí tí ó fi fún wa.

Ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò

Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹ̀mí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò bí wọn ba ń ṣe tí Ọlọ́run: nítorí àwọn wòlíì èké púpọ̀ tí jáde lọ sínú ayé. Èyí ni ẹ ó fi mọ Ẹ̀mí Ọlọ́run: gbogbo ẹ̀mí tí ó ba jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi wá nínú ara, ti Ọlọ́run ni: (E)Gbogbo ẹ̀mí tí kò si jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wà nínú ara, kì í ṣe tí Ọlọ́run: èyí sì ni ẹ̀mí aṣòdì sí Kristi náà, tí ẹ̀yin ti gbọ́ pé ó ń bọ̀, àti nísinsin yìí ó sì tí de sínú ayé.

Ẹ̀yin ọmọ mi, ti Ọlọ́run ni yín, ẹ̀yin sì tí ṣẹ́gun wọn: nítorí ẹni tí ń bẹ nínú yin tóbi jú ẹni tí ń bẹ nínú ayé lọ. (F)Tí ayé ni wọ́n, nítorí náà ni wọn ṣe ń sọ̀rọ̀ bí ẹni ti ayé, ayé sì ń gbọ́ tí wọn. (G)Ti Ọlọ́run ni àwa: ẹni tí ó bá mọ Ọlọ́run, ó ń gbọ́ tiwa; ẹni tí kì í ṣe ti Ọlọ́run kò ni gbọ́ ti wa. Nípa èyí ni àwa mọ ẹ̀mí òtítọ́, àti ẹ̀mí èké.

Matiu 11:1-6

Jesu àti Johanu onítẹ̀bọmi

11 (A)Lẹ́yìn ìgbà tí Jesu sì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá, ó ti ibẹ̀ rékọjá láti máa kọ́ni àti láti máa wàásù ní àwọn ìlú Galili gbogbo.

(B)Nígbà tí Johanu gbọ́ ohun tí Kristi ṣe nínú ẹ̀wọ̀n, ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ (C)láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣe ìwọ ni ẹni tó ń bọ̀ wá tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”

Jesu dáhùn ó wí pé, “Ẹ padà lọ, ẹ sì sọ fún Johanu ohun tí ẹ̀yin gbọ́, àti èyí tí ẹ̀yin rí. Àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ wọn, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì. Alábùkún fún ni ẹni tí kò rí ohun ìkọ̀sẹ̀ nípa mi.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.