Book of Common Prayer
Ti Dafidi.
26 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa,
nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,
mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa
Ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.
2 Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò,
dán àyà àti ọkàn mi wò;
3 Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,
èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.
4 Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé;
5 Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú
èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.
6 Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.
7 Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,
èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.
8 Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé,
àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.
9 Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,
10 Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi,
tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́;
rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.
12 Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;
nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.
Ti Dafidi.
28 Ìwọ Olúwa,
mo ké pe àpáta mi;
Má ṣe kọ etí dídi sí mi.
Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi,
èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.
2 Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú,
bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,
bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè
sí ibi mímọ́ rẹ jùlọ.
3 Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti,
pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn
ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.
4 San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn
àti fún iṣẹ́ ibi wọn;
gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn;
kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́.
5 Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀
òun ó rún wọn wọlẹ̀
kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.
6 Alábùkún fún ni Olúwa!
Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7 Olúwa ni agbára mi àti asà mi;
nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.
Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀
àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.
8 Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀
òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni ààmì òróró rẹ̀.
9 Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ;
di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.
Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa
36 (A)Ìré-òfin-kọjá ènìyàn búburú
jẹ́ kí n mọ̀ nínú ọkàn mi pé;
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí
níwájú wọn.
2 Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọn
títí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra.
3 Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òhun ẹ̀tàn;
wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀;
4 Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn:
wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára
wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.
5 Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ Olúwa, ó ga dé ọ̀run,
òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀.
6 Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,
àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá;
ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.
7 Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run!
Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ.
8 Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi;
ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ.
9 Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà:
nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.
10 Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n
àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!
11 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ agbéraga kí ó wá sí orí mi,
kí o má sì jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú sí mi ní ipò.
12 Níbẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbé ṣubú sí:
a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn kì yóò le è dìde!
Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Saamu Dafidi.
39 Mo wí pé, “èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi
kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀;
èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu
níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”
2 Mo fi ìdákẹ́ ya odi;
mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere;
ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i.
3 Àyà mi gbóná ní inú mi.
Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn;
nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀:
4 “Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,
àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí
kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.
5 Ìwọ ti ṣe ayé mi
bí ìbú àtẹ́lẹwọ́,
ọjọ́ orí mi sì dàbí asán
ní iwájú rẹ:
Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú
ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.
6 “Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.
Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;
wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,
wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.
7 “Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,
Olúwa,
kín ni mo ń dúró dè?
Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.
8 Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.
Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn
àwọn ènìyàn búburú.
9 Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;
èmi kò sì ya ẹnu mi,
nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.
10 Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi;
èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.
11 Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀
fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,
ìwọ a mú ẹwà rẹ parun
bí kòkòrò aṣọ;
nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.
12 “Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa,
kí o sì fetí sí igbe mi;
kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi
nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ
àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.
13 Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára,
kí èmi tó lọ kúrò níhìn-ín yìí,
àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”
Ní orí òkè Sinai
19 Ní oṣù kẹta tí àwọn Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, ni ọjọ́ náà gan an ni wọ́n dé aginjù Sinai. 2 Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n gbéra kúrò ní Refidimu, wọ́n wọ ijù Sinai, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀, níbẹ̀ ni Israẹli sì dó sí ní iwájú òkè ńlá.
3 Mose sì gòkè tọ Ọlọ́run lọ. Olúwa sì ké pè é láti orí òkè náà wá pé, “Èyí ni ìwọ yóò sọ fún ilé Jakọbu àti ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: 4 ‘Ẹ̀yin ti rí ohun tí mo ti ṣe sí àwọn ará Ejibiti, àti bí mo ti gbé e yín ní apá ìyẹ́ idì. 5 (A)Nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá ṣe ìgbọ́ràn sí mi dé ojú ààmì, tí ẹ sì pa májẹ̀mú mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin ó jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ni tèmi. 6 Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ilẹ̀ ọba àwọn àlùfáà fún mi, orílẹ̀-èdè mímọ́.’ Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ti ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.”
7 Mose sì tọ àwọn ènìyàn wá, ó sí pe àwọn àgbàgbà láàrín àwọn ènìyàn jọ. Ó sì gbé gbogbo ọ̀rọ̀ ti Olúwa pàṣẹ fún un láti sọ ní iwájú wọn. 8 Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì pa ohùn wọn pọ̀ wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa yóò ṣe ohun gbogbo ti Olúwa wí.” Mose sì mú ìdáhùn wọn padà tọ Olúwa lọ.
9 Olúwa sọ fún Mose pé, “Èmi yóò tọ̀ ọ́ wá nínú ìkùùkuu ṣíṣú dudu, kí àwọn ènìyàn lè gbọ́ ohùn mi nígbà ti mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọn kí ó lè máa gbà ọ́ gbọ́.” Nígbà náà ni Mose sọ ohun tí àwọn ènìyàn wí fún Olúwa.
10 Olúwa sì wí fún Mose pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn. 11 Kí wọn kí ó sì múra di ọjọ́ kẹta, nítorí ni ọjọ́ náà ni Olúwa yóò sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai ni ojú gbogbo àwọn ènìyàn. 12 (B)Kí ìwọ kí ó ṣe ààlà fún àwọn ènìyàn, kí ìwọ kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ kíyèsí ara yín, kí ẹ má ṣe gun orí òkè lọ, kí ẹ má tilẹ̀ fi ọwọ́ ba etí rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè náà, ó dájú, pípa ni a ó pa á: 13 A ó sọ ọ́ ní òkúta tàbí kí a ta á ní ọfà, ọwọ́kọ́wọ́ kò gbọdọ̀ kàn án. Ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko, òun kì yóò wà láààyè.’ Nígbà ti ìpè bá dún nìkan ni kí wọn ó gun òkè wá.”
14 Mose sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. 15 Ó sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ múra sílẹ̀ di ọjọ́ kẹta; Ẹ má ṣe bá aya yín lòpọ̀.”
16 (C)(D) Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹta, àrá àti mọ̀nàmọ́ná sì wà pẹ̀lú ìkùùkuu tí ó ṣú dudu ní orí òkè, ìpè ńlá sì dún kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ó wà ni ibùdó wárìrì.
1 Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Timotiu arákùnrin wa.
2 (A)Sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú Kristi tí wọ́n ń gbé ní ìlú Kolose.
Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún un yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa.
Àwọn ọpẹ́ àti àdúrà
3 (B)Nígbàkúgbà tí a bá ń gbàdúrà fún un yín ni a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jesu Kristi. 4 Nítorí a ti gbúròó ìgbàgbọ́ yín nínú Jesu Kristi, àti bí ẹ ti ṣe fẹ́ràn gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. 5 Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ń sàn nínú ìrètí tí a gbé pamọ́ fún un yín ní ọ̀run èyí tí ẹ̀yin sì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìhìnrere náà, 6 èyí tí ó ti dé ọ̀dọ̀ yín. Káàkiri àgbáyé ni ìhìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrín yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ́ ọ, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀. 7 (C)Ẹ̀yin ti kọ́ ọ lọ́dọ̀ Epafira, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa olùfẹ́, ẹni tí ó jẹ́ olóòtítọ́ ìránṣẹ́ Kristi ní ipò wa. 8 Ẹni ti ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín nínú ẹ̀mí.
9 (D)Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò sinmi láti máa gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípasẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí. 10 Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹ lè gbé irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run, 11 pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀síwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀. 12 Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yín láti jẹ́ alábápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀. 13 (E)Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn. 14 Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.
7 (A)Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ àwọn Farisi àti Sadusi tí wọ́n ń wá ṣe ìtẹ̀bọmi, ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀! Ta ni ó kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ́ sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? 8 Ẹ so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà. 9 (B)Kí ẹ má sì ṣe rò nínú ara yin pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Èmi wí fún yín, Ọlọ́run lè mu àwọn ọmọ jáde láti inú àwọn òkúta wọ̀nyí wá fún Abrahamu. 10 (C)Nísinsin yìí, a ti fi àáké lè gbòǹgbò igi, àti pé gbogbo igi tí kò bá so èso rere ni a óò ge lulẹ̀ ti a ó sì wọ jù sínú iná.
11 “Èmi fi omi bamitiisi yín fún ìrònúpìwàdà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn mi ẹnìkan tí ó pọ̀jù mí lọ ń bọ̀, bàtà ẹni tí èmi kò tó gbé. Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín. 12 (D)Ẹni ti àmúga ìpakà rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, yóò gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀, yóò kó alikama rẹ̀ sínú àká, ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.