Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi.
55 Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run,
Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:
2 Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn.
Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo.
3 Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni,
nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú;
nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi,
wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.
4 Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú;
ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.
5 Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi;
ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.
6 Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!
Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.
7 Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré,
kí ń sì dúró sí aginjù;
8 Èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò,
jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.”
9 Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa, da ahọ́n wọn rú,
nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.
10 Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri;
ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.
11 Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀;
ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀.
12 Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi,
èmi yóò fi ara mọ́ ọn;
tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi,
èmi ìbá sápamọ́ fún un.
13 Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi,
ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,
14 pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀,
bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.
15 Kí ikú kí ó dé bá wọn,
Kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú,
Jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,
nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.
16 Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run;
Olúwa yóò sì gbà mí.
17 Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán
èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú,
o sì gbọ́ ohùn mi.
18 Ó rà mí padà láìléwu
kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi,
nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.
19 Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì pọ́n wọn lójú
àní, ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbàanì—Sela.
Nítorí tí wọn kò ní àyípadà,
tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.
20 Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ rẹ̀;
ó ti ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́.
21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́,
ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀;
ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ,
ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn.
22 (A)Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa
yóò sì mú ọ dúró;
òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.
23 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi
wá sí ihò ìparun;
Àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn,
kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn.
Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.
Ti Dafidi
138 Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;
níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
2 Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀
èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ
nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;
nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.
3 Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,
ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.
4 Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,
Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ
5 Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;
nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.
6 Bí Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;
ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.
7 Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;
ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.
8 Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;
Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé;
Má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
139 Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,
ìwọ sì ti mọ̀ mí.
2 Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi,
ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
3 Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi,
gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
4 Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,
kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
5 Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,
ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
6 Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù;
ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.
7 Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ?
Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ?
8 Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀;
bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú,
kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
9 Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀,
kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun;
10 Àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí
ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú.
11 Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀;
kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.”
12 Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ;
ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;
àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.
13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;
ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;
ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;
èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú
15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.
Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi
nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé:
àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,
ní ọjọ́ tí a dá wọn,
nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
17 Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,
iye wọn ti pọ̀ tó!
18 Èmi ìbá kà wọ́n,
wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:
nígbà tí mo bá jí,
èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.
19 Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́;
nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀.
20 Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ,
àwọn ọ̀tá rẹ ń pe orúkọ rẹ ní asán!
21 Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tó kórìíra rẹ?
Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?
22 Èmi kórìíra wọn ní àkótán;
èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.
23 Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ ọkàn mí;
dán mi wò, kí o sì mọ ìrò inú mi
2 Mose pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ó sì wí fún wọn wí pé:
Ojú rẹ ti rí gbogbo ohun tí Olúwa ti ṣe ní Ejibiti sí Farao àti, sí gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀ àti sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀. 3 Pẹ̀lú ojú ara rẹ ni ìwọ rí àwọn ìdánwò ńlá náà, àwọn iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá. 4 (A)Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí Olúwa kò fi ọkàn ìmòye tàbí ojú tí ó ń rí tàbí etí tí ó n gbọ́ fún ọ. 5 Nígbà ogójì ọdún tí mò ń tọ́ yín ṣọ́nà ní aginjù, aṣọ ọ̀ rẹ kò gbó tàbí bàtà ẹsẹ̀ rẹ. 6 O kò jẹ oúnjẹ tàbí mu wáìnì kankan tàbí rú ohun mímu mìíràn. Mo ṣe èyí kí o lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ.
7 Nígbà tí o dé ibí yìí, Sihoni ọba Heṣboni àti Ogu ọba Baṣani jáde wá láti bá ọ jà, ṣùgbọ́n a ṣẹ́gun wọn. 8 A gba ilẹ̀ wọn a sì fi fún àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase bí ogún.
9 Nítorí náà, ẹ pa májẹ̀mú yìí mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n, kí ẹ̀yin kí ó lè máa rí ire nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe. 10 Gbogbo yín ń dúró lónìí yìí níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ: àwọn olórí yín, àwọn ẹ̀yà yín, àwọn àgbàgbà yín àti àwọn ìjòyè yín, àní gbogbo àwọn ọkùnrin mìíràn ní Israẹli, 11 pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọ̀ rẹ àti ìyàwó ò rẹ àti àwọn àjèjì tí wọ́n ń gbé ní àgọ́ ọ̀ rẹ, tí ó ké pópòpó igi rẹ, tí ó sì gbé omi rẹ. 12 O dúró níhìn-ín yìí kí o lè wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, májẹ̀mú tí Olúwa ń ṣe pẹ̀lú rẹ lónìí yìí àti tí òun dè pẹ̀lú ìbúra, 13 láti jẹ́wọ́ rẹ lónìí yìí bí ènìyàn an rẹ̀, pé kí ó lè jẹ́ Ọlọ́run rẹ bí ó ti ṣèlérí àti bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba à rẹ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu. 14 Èmi ń ṣe májẹ̀mú yìí, pẹ̀lú ìbúra rẹ̀, kì í ṣe fún ìwọ nìkan 15 tí ó dúró níbí pẹ̀lú wa lónìí níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ṣùgbọ́n àti fún gbogbo àwọn tí kò sí níbí lónìí.
9 (A)Nísinsin yìí, nípa ti ìpín fún ni fún àwọn ènìyàn mímọ́, kò tún yẹ mọ́ fún mi láti kọ̀wé sí yin ju bẹ́ẹ̀ lọ. 2 (B)Nítorí mo mọ ìtara láti ṣe ìrànlọ́wọ́ yín, èyí tí mo ti ṣògo fún àwọn ará Makedonia nítorí yín, pé, àwọn ara Akaia ti múra tan níwọ̀n ọdún kan tí ó kọjá ìtara yín sì ti rú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè. 3 (C)Ṣùgbọ́n mo ti rán àwọn arákùnrin, kí ìṣògo wa nítorí yín má ṣe jásí asán ní ti ọ̀ràn yìí; pé gẹ́gẹ́ bí mó ti wí, kí ẹ̀yin lè múra tẹ́lẹ̀. 4 Kí ó má ba à jẹ́ pé, bí àwọn nínú ara Makedonia bá bá mi wá, tí wọ́n sì bá yín ní àìmúra sílẹ̀, ojú a sì tì wá kì í ṣe ẹ̀yin, ní ti ìgbẹ́kẹ̀lé yìí. 5 Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ́bi ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti a fi ìkùnsínú ṣe.
Ìfúnrúgbìn tọkàntọkàn
6 Ṣùgbọ́n èyí ni mo wí pé: Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn kín ún, kín ún ni yóò ká; ẹni tí ó bá sì fúnrúgbìn púpọ̀, púpọ̀ ni yóò ká. 7 (D)Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọkàn rẹ̀; kì í ṣe àfi ìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọdọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ. 8 (E)Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore-ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo. 9 (F)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé:
“Ó tí fọ́nká; ó ti fi fún àwọn tálákà;
Òdodo rẹ̀ dúró láéláé.”
10 (G)Ǹjẹ́ ẹni tí ń fi irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i. 11 Bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo, fún ìlawọ́ yín gbogbo tí ń ṣiṣẹ́ ọpẹ́ sí Ọlọ́run nípa wa.
12 Nítorí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìsìn yìí kò kún ìwọ̀n àìní àwọn ènìyàn mímọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ó túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpẹ́ sí Ọlọ́run. 13 (H)Nítorí ìdúró yin lábẹ́ ìdánwò iṣẹ́ ìsìn yìí, wọn yóò yin Ọlọ́run lógo fún ìgbọ́ràn yín ní gbígba ìhìnrere Kristi àti nípa ìlawọ́ ìdáwó yín fún wọn àti fún gbogbo ènìyàn. 14 Àti nínú àdúrà fún un yín, ọkàn wọn ń ṣe àfẹ́rí yín nítorí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ti ń bẹ nínú yín. 15 (I)Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nítorí aláìlèfẹnusọ ẹ̀bùn rẹ̀!
Àwọn ọmọdé àti Jesu
15 (A)Wọ́n sì gbé àwọn ọmọ ọwọ́ tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí i, wọ́n ń bá wọn wí. 16 Ṣùgbọ́n Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun: nítorí tí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run. 17 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbà ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.”
Ọlọ́rọ̀ alákòóso
18 (B)(C) Ìjòyè kan sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, wí pé, “Olùkọ́ rere, kín ni èmi ó ṣe tí èmi ó fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”
19 Jesu wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí bí kò ṣe ẹnìkan, èyí sì ni Ọlọ́run. 20 (D)Ìwọ mọ̀ àwọn òfin: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà, ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jalè, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jẹ́rìí èké, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.’ ”
21 Ó sì wí pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti pamọ́ láti ìgbà èwe mi wá.”
22 (E)Nígbà tí Jesu sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, “Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn tálákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra ní ọ̀run: sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
23 Nígbà tí ó sì gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi: nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀. 24 (F)Nígbà tí Jesu rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi, ó wí pé, “Yóò ti ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run! 25 Nítorí ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run lọ.”
26 Àwọn tí ó sì gbọ́ wí pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha lè là?”
27 (G)Ó sì wí pé, “Ohun tí ó ṣòro lọ́dọ̀ ènìyàn kò ṣòro lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”
28 (H)Peteru sì wí pé, “Sá wò ó, àwa ti fi ilé wa sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!”
29 Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí aya, tàbí ará, tàbí òbí, tàbí ọmọ sílẹ̀, nítorí ìjọba Ọlọ́run, 30 Tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.