Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 63

Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda.

63 Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi,
    nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ,
òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi,
    ara mi fà sí ọ,
ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀
    níbi tí kò sí omi.

Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́,
    mo rí agbára àti ògo rẹ.
Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ,
    ètè mi yóò fògo fún ọ.
Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè,
    èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ.
A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ;
    pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.

Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi;
    èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.
Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,
    mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.
Ọkàn mí fà sí ọ:
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.

Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ni a ó parun;
    wọn ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.
10 Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubú
    wọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.

11 Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run
    ẹni tí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò ṣògo
    ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pamọ́.

Saamu 98

98 Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,
    nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀
    o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un
Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀
    o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.
Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli;
    gbogbo òpin ayé ni ó ti rí
    iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.

Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé,
    ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn
Ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,
Pẹ̀lú ìpè àti fèrè
    ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba.

Jẹ́ kí Òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo
    ohun tí ó wà nínú rẹ̀,
Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́,
    ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀;
Ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa
    Nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé
bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo
    àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.

Saamu 103

Ti Dafidi.

103 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀
Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́
    tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,
Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú
    ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,
Ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn
    kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.

Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún
    gbogbo àwọn tí a ni lára.

Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;
(A)Olúwa ni aláàánú àti olóore,
    ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo
    bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé;
10 Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa
    bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́
bí àìṣedéédéé wa.
11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
12 Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn
    bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.

13 Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;
14 Nítorí tí ó mọ dídá wa,
    ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.
15 Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko,
    ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó;
16 Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀,
    kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́.
17 (B)Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́
    Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ
18 Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́
    àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.

19 Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run,
    ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.

20 Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,
    tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́
21 Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo,
    ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
22 Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní
    ibi gbogbo ìjọba rẹ̀.

Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Deuteronomi 11:1-12

Fẹ́ràn Olúwa kí o sì gbọ́ tirẹ̀

11 Ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ sì pa ìfẹ́ rẹ̀, ìlànà rẹ̀, òfin rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ ní ìgbà gbogbo. Ẹ rántí lónìí pé, kì í ṣe àwọn ọmọ yín, ni ó rí ìbáwí Olúwa Ọlọ́run yín; títóbi rẹ̀, ọwọ́ agbára rẹ̀, nína ọwọ́ rẹ̀; iṣẹ́ ààmì rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe ní àárín àwọn ará Ejibiti: Sí Farao ọba Ejibiti àti gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ohun tí ó ṣe sí àwọn jagunjagun Ejibiti, sí kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹlẹ́ṣin rẹ̀: bí ó ṣe rì wọ́n sínú Òkun pupa, bí wọ́n ṣe ń lé e yín tí Olúwa fi pa wọ́n run pátápátá títí di òní olónìí yìí. Kì í ṣe àwọn ọmọ yín ni ó rí ohun tí ó ṣe fún un yín ní aginjù, títí ẹ fi dé ìhín yìí, (A)ohun tí ó ṣe sí Datani àti Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ẹ̀yà Reubeni, bí ilẹ̀ ti lanu ní ojú gbogbo ará Israẹli tí ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ìdílé wọn, gbogbo àgọ́ ọ wọn àti gbogbo ohun alààyè tí ó jẹ́ tiwọn. Ṣùgbọ́n ojú u yín gan an ni ó rí gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí tí Olúwa ti ṣe.

Nítorí náà, ẹ kíyèsi gbogbo àṣẹ tí mo ń fún yín lónìí, kí ẹ ba à lè lágbára àti lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí ẹ ó la Jordani kọjá lọ. Kí ẹ ba à lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa ti búra fún àwọn baba ńlá a yín, láti fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn: ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin. 10 Ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà kò rí bí ilẹ̀ Ejibiti, níbi tí ẹ ti wá, níbi tó jẹ́ wí pé ẹsẹ̀ yín ni ẹ fi ń rìn lọ bomirin irúgbìn tí ẹ gbìn bí oko ẹ̀fọ́. 11 Ṣùgbọ́n ilẹ̀ tí ẹ ó la Jordani kọjá láti gbà, jẹ́ ilẹ̀ olókè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí òjò ń rọ̀ sí latọ̀run. 12 Ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń mójútó ni, ojú Olúwa Ọlọ́run yín sì ń fi ìgbà gbogbo wà lórí rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún dé òpin ọdún.

Ìfihàn 10

Àwọn angẹli àti ìwé kékeré

10 Mó sì rí angẹli mìíràn alágbára ò ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, a fi àwọsánmọ̀ wọ̀ ọ́ ni aṣọ; òṣùmàrè sì ń bẹ ní orí rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dàbí oòrùn, àti ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ọ̀wọ́n iná. Ó sì ní ìwé kékeré kan tí a ṣí ní ọwọ́ rẹ̀; ó sì fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún lé Òkun, àti ẹsẹ̀ rẹ̀ òsì lé ilẹ̀. Ó sì ké lóhùn rara, bí ìgbà tí kìnnìún bá bú ramúramù. Nígbà tí ó sì ké, àwọn àrá méje náà fọhùn. Nígbà tí àwọn àrá méje fọhùn, mo múra àti kọ̀wé: mo sì gbọ́ ohùn láti ọ̀run wá ń wí fún pé, “Fi èdìdì di ohun tí àwọn àrá méje náà sọ, má sì ṣe kọ wọ́n sílẹ̀.”

(A)Angẹli náà tí mo rí tí ó dúró lórí Òkun àti lórí ilẹ̀, sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run: Ó sì fi ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láé búra, ẹni tí o dá ọ̀run, àti ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀, ayé ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀ pé, “Kí yóò si ìjáfara mọ́. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ohùn angẹli keje, nígbà tí yóò ba fún ìpè, nígbà náà ni ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí o tí sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì ni a ó mú ṣẹ.”

Ohùn náà tí mo gbọ́ láti ọ̀run tún ń ba mi sọ̀rọ̀, ó sì wí pé, “Lọ, gba ìwé tí o ṣí lọ́wọ́ angẹli tí o dúró lórí Òkun àti lórí ilẹ̀.”

(B)Mo sì tọ angẹli náà lọ, mo sì wí fún pé, “Fún mi ní ìwé kékeré náà.” Ó sì wí fún mi pé, “Gbà kí o sì jẹ ẹ́ tan: yóò dàbí oyin.” 10 Mo sì gba ìwé kékeré náà ni ọwọ́ angẹli náà mo sì jẹ ẹ́ tan; ó sì dùn lẹ́nu mi bí oyin; bí mo sì tí jẹ ẹ́ tan, inú mi korò. 11 (C)A sì wí fún mi pé, “Ìwọ ó sì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti orílẹ̀ àti èdè, àti àwọn ọba.”

Matiu 13:44-58

Òwe ìṣúra tí a fi pamọ́ sínú ilẹ̀ àti ohun ẹ̀ṣọ́ olówó iyebíye

44 “Ìjọba ọ̀run sì dàbí ìṣúra kan tí a fi pamọ́ sínú oko. Nígbà tí ọkùnrin kan rí i ó tún fi í pamọ́. Nítorí ayọ̀ rẹ̀, ó ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó ra oko náà.

45 “Bákan náà ni ìjọba ọ̀run dàbí oníṣòwò kan tí ó ń wá òkúta olówó iyebíye láti rà. 46 Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó ni iye lórí, ó lọ láti ta gbogbo ohun ìní rẹ̀ láti le rà á.

Òwe ti àwọ̀n ẹja

47 (A)“Bákan náà, a sì tún lè fi ìjọba ọ̀run wé àwọ̀n kan tí a jù sínú odò, ó sì kó onírúurú ẹja. 48 Nígbà tí àwọ̀n náà sì kún, àwọn apẹja fà á sókè sí etí bèbè Òkun, wọ́n jókòó, wọ́n sì ṣa àwọn èyí tí ó dára sínú apẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n da àwọn tí kò dára nù. 49 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn angẹli yóò wá láti ya àwọn ènìyàn búburú kúrò lára àwọn olódodo. 50 Wọn ó sì ju àwọn ènìyàn búburú sínú iná ìléru náà, ní ibi ti ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.”

51 Jesu bí wọn léèrè pé, “Ǹjẹ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí yé yín.”

Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó yé wa.”

52 Ó wí fún wọn pé, “Nítorí náà ni olúkúlùkù olùkọ́ òfin tí ó ti di ọmọ-ẹ̀yìn ní ìjọba ọ̀run ṣe dàbí ọkùnrin kan tí í ṣe baálé ilé, tí ó mú ìṣúra tuntun àti èyí tí ó ti gbó jáde láti inú yàrá ìṣúra rẹ̀.”

Wòlíì tí kò lọ́lá

53 (B)Lẹ́yìn ti Jesu ti parí òwe wọ̀nyí, ó ti ibẹ̀ kúrò. 54 (C)Ó wá sí ìlú òun tìkára rẹ̀, níbẹ̀ ni ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú Sinagọgu, ẹnu sì yà wọ́n. Wọ́n béèrè pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí ti mú ọgbọ́n yìí àti iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí wá? 55 Kì í ha ṣe ọmọ gbẹ́nàgbẹ́nà ni èyí bí? Ìyá rẹ̀ ha kọ́ ni à ń pè ní Maria bí? Arákùnrin rẹ̀ ha kọ́ ni Jakọbu, Josẹfu, Simoni àti Judasi bí? 56 Àwọn arábìnrin rẹ̀ gbogbo ha kọ́ ni ó ń bá wa gbé níhìn-ín yìí, nígbà náà níbo ni ọkùnrin yìí ti rí àwọn nǹkan wọ̀nyí?” 57 Inú bí wọn sí i.

Ṣùgbọ́n Jesu wí fún wọn pé, “Wòlíì a máa lọ́lá ní ibòmíràn, àfi ní ilé ara rẹ̀ àti ní ìlú ara rẹ̀ nìkan ni wòlíì kò ti lọ́lá.”

58 Nítorí náà kò ṣe iṣẹ́ ìyanu kankan níbẹ̀, nítorí àìnígbàgbọ́ wọn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.