Readings for Celebrating Advent
2 Ọlọ́run sì bá Israẹli sọ̀rọ̀ ní ojú ìran ní òru pé, “Jakọbu! Jakọbu!”
Ó sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
3 Ọlọ́run sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run, Ọlọ́run baba rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti nítorí, èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀. 4 Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Ejibiti, èmi yóò sì tún mú ọ padà wá. Ọwọ́ Josẹfu fúnrarẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí.”
5 Nígbà náà ni Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, àwọn ọmọ Israẹli sì mú Jakọbu baba wọn àti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì kó wọn sí inú kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Farao fi ránṣẹ́ fún ìrìnàjò rẹ̀:
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.