Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 124

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

124 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa”
    ni kí Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;
“Ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,”
    Nígbà tí àwọn ènìyàn dúró sí wa:
Nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè
    nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa
Nígbà náà ni omi
    wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀
Nígbà náà ni agbéraga
omi ìbá borí ọkàn wa.

Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n
    bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.
Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;
    okùn já àwa sì yọ.
Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa,
    tí ó dá ọ̀run òun ayé.

Isaiah 54:1-10

Ògo ọjọ́ iwájú ti Sioni

54 (A)“Kọrin, ìwọ obìnrin àgàn,
    ìwọ tí kò tí ì bímọ rí;
bú sí orin, ẹ hó fún ayọ̀,
    ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí;
nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro
    ju ti ẹni tí ó ní ọkọ,”
    ni Olúwa wí.
Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i,
    fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i,
má ṣe dá a dúró;
    sọ okùn rẹ di gígùn,
    mú òpó rẹ lágbára sí i.
Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn àti sí òsì;
    ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀-èdè,
    wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.

“Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́.
    Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù.
Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ
    Ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́.
Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀
Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ;
    a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
Olúwa yóò pè ọ́ padà
    àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀
tí a sì bà lọ́kàn jẹ́
    obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́,
    tí a sì wá jákulẹ̀” ni Olúwa wí.
“Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
    ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò
    mú ọ padà wá.
Ní ríru ìbínú.
    Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan,
ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun
    Èmi yóò ṣíjú àánú wò ọ́,”
    ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí.

“Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Noa,
    nígbà tí mo búra pé àwọn omi
Noa kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́.
    Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́.
10 Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá
    tí a sì ṣí àwọn òkè kékeré nídìí,
Síbẹ̀síbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé
    tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,”
    ni Olúwa, ẹni tí ó ṣíjú àánú wò ọ́ wí.

Matiu 24:23-35

23 Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wo Kristi náà,’ tàbí pé ó ti farahàn níhìn-ín tàbí lọ́hùn ún, ẹ má ṣe gbà á gbọ́. 24 Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde. Wọn yóò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ààmì àti ìyanu. Bí ó bá lè ṣe é ṣe wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá jẹ. 25 Wò ó, mo ti kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀.

26 (A)“Nítorí náà, bí ẹnìkan bá sọ fún yín pé, ‘Olùgbàlà ti dé,’ àti pé, ‘Ó wà ní aginjù,’ ẹ má ṣe wàhálà láti lọ wò ó, tàbí tí wọ́n bá ní ó ń fi ara pamọ́ sí iyàrá, ẹ má ṣe gbà wọn gbọ́. 27 Nítorí bí mọ̀nàmọ́ná ti ń tàn láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́. 28 Nítorí ibikíbi tí òkú bá gbé wà, ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ igún ń kójọpọ̀ sí.

29 (B)“Lójúkan náà, lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,

“ ‘ni oòrùn yóò ṣókùnkùn,
    òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn;
àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò já sílẹ̀,
    agbára ojú ọ̀run ni a ó mì tìtì.’

30 (C)“Nígbà náà ni ààmì Ọmọ Ènìyàn yóò sì fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá. 31 Yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ jáde pẹ̀lú ohùn ìpè ńlá, wọn yóò sì kó gbogbo àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé àti ọ̀run jọ.

32 “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́: Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ti ń yọ tuntun tí ó bá sì ń ru ewé, ẹ̀yin mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí. 33 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí i tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìpadàbọ̀ mi dé tán lẹ́yìn ìlẹ̀kùn. 34 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ìran yìí kì yóò kọjá títí tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ. 35 Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.