Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà.
142 Èmi kígbe sókè sí Olúwa;
Èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú.
2 Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.
3 Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi,
ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi.
Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn
ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀
4 Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i
kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi
èmi kò ní ààbò;
kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi.
5 Èmi kígbe sí ọ, Olúwa:
èmi wí pé, “ìwọ ni ààbò mi,
ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”
6 Fi etí sí igbe mi,
nítorí tí èmi wà nínú àìnírètí
gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi,
nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ
7 Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú,
kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ.
Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkiri
nítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.
12 “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ kọ́ ìlú,
tí o sì fi àìṣedéédéé tẹ ìlú ńlá dó?
13 Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pé
làálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún iná
kí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún asán?
14 Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa,
bí omi ti bo Òkun.
15 “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀,
tí ó sì fi ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara,
kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòhò wọn”
16 Ìtìjú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lú
kí ìhòhò rẹ kí ó lè hàn,
ago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa, yóò yípadà sí ọ,
ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ.
17 Nítorí ìwà ipá tí ó tí hù sí Lebanoni yóò bò ọ́,
àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́ mọ́lẹ̀
Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀;
ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
18 “Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ,
ère dídá ti ń kọ ni èké?
Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnrarẹ̀ dá;
ó sì mọ ère tí kò le fọhùn.
19 Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, ‘di alààyè?’
Fún òkúta tí kò lè fọhùn pé, ‘Dìde’
Ǹjẹ́ òun lè tọ́ ni sí ọ̀nà?
Wúrà àti fàdákà ni a fi bò ó yíká;
kò sì sí èémí kan nínú rẹ.”
20 (A)Ṣùgbọ́n Olúwa wà nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;
Ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ.
9 (A)Nígbà tí mo kọ̀wé ṣáájú sí i yín, mo sọ fún yín pé, kí ẹ má ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ènìyàn. 10 (B)Nígbà tí mo sọ bẹ́ẹ̀ ń kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ayé yìí, tí wọ́n ń gbé ìgbé ayé wọn nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè, àti àwọn olójúkòkòrò tí ń rẹ́ ni jẹ, àwọn olè àti àwọn abọ̀rìṣà. Nítorí ó dájú pé ẹ̀yin gbọdọ̀ kúrò nínú ayé yìí láti yẹra fún wọn. 11 (C)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí mo kọ̀wé sí i yín pé, bí ẹnikẹ́ni tí a pe rẹ̀ ni arákùnrin bá jẹ́ àgbèrè, tàbí wọ̀bìà, tàbí abọ̀rìṣà, àti ẹlẹ́gàn, tàbí ọ̀mùtípara, tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà. Kí ẹ tilẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.
12 (D)Nítorí èwo ni tèmi láti máa ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń bẹ lóde? Kì í ha ṣe àwọn tí ó wà nínú ni ẹ̀yin ṣe ìdájọ́ wọn? 13 (E)Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ àwọn tí ó ń bẹ lóde. “Ẹ lé àwọn ènìyàn búburú náà kúrò láàrín yín.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.