Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
ÌWÉ KẸRIN
Saamu 90–106
Àdúrà Mose ènìyàn Ọlọ́run
90 Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.
2 Kí a tó bí àwọn òkè ńlá
àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé,
láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.
3 Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀,
wí pé “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.”
4 (A)Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú rẹ,
bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
5 Ìwọ gbá ènìyàn dànù nínú oorun ikú;
wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
6 Lóòtítọ́, ní òwúrọ̀, ó yọ tuntun
ní àṣálẹ́ ni yóò gbẹ, tí yóò sì rẹ̀ dànù.
7 A pa wá run nípa ìbínú rẹ
nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá.
8 Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú rẹ,
àti ohun ìkọ̀kọ̀ wa nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ,
9 Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú rẹ;
àwa ń lo ọjọ́ wa lọ bí àlá tí à ń rọ́.
10 Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá,
bi ó sì ṣe pé nípa agbára
tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún,
agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni,
nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò,
àwa a sì fò lọ.
11 Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ?
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ.
12 Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára,
kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.
13 Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ tó?
Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ.
14 Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ,
kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀
kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.
15 Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú,
fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.
16 Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀,
ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.
17 Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa;
fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa
bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.
Ọ̀pá Aaroni rúwé
17 Olúwa sì sọ fún Mose pé, 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí o sì gba ọ̀pá méjìlá lọ́wọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ olórí ìdílé ẹ̀yà ìran wọn, kọ orúkọ ènìyàn kọ̀ọ̀kan sí ara ọ̀pá rẹ̀. 3 Lórí ọ̀pá Lefi kọ orúkọ Aaroni, nítorí ọ̀pá kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà fún olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan tí yóò jẹ́ orí fún ẹ̀yà ìran kọ̀ọ̀kan. 4 Kó wọn sí àgọ́ ìpàdé níwájú ẹ̀rí níbi tí èmi ti ń pàdé yín. 5 Ọ̀pá tí ó bá yí jẹ́ ti ẹni tí èmi bá yàn yóò rúwé, èmi yóò sì dá kíkùn gbogbo ìgbà àwọn ọmọ Israẹli sí yín dúró.”
6 Nígbà náà Mose bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, àwọn olórí wọn sì fún un ní ọ̀pá méjìlá, ọ̀pá kan fún olórí kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà ìran wọn, ọ̀pá Aaroni sì wà lára àwọn ọ̀pá náà. 7 Mose sì fi ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú Olúwa nínú àgọ́ ẹ̀rí.
8 (A)Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì Mose wọ inú àgọ́ ẹ̀rí lọ, ó sì rí ọ̀pá Aaroni, tí ó dúró fún ẹ̀yà Lefi, kì í ṣe wí pé ó hù nìkan Ṣùgbọ́n ó rúwé, ó yọ ìtànná, ó sì so èso almondi. 9 Nígbà náà ni Mose kó gbogbo àwọn ọ̀pá jáde láti iwájú Olúwa wá fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n wò wọ́n, ẹnìkọ̀ọ̀kan sì mú ọ̀pá tirẹ̀.
10 Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú ọ̀pá Aaroni padà wá síwájú ẹ̀rí, láti fi pamọ́ gẹ́gẹ́ bí ààmì fún àwọn ọlọ̀tẹ̀. Èyí ó sì mú òpin bá kíkùn sínú wọn sí mi, kí wọn kí ó má ba à kú.” 11 Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti páláṣẹ fún un.
Ọjọ́ Olúwa
3 Olùfẹ́, èyí ni ìwé kejì tí mo ń kọ sí yín, nínú méjèèjì náà ni èmi ń ru èrò inú yín sókè nípa rírán yín létí; 2 kí ẹ̀yin lè máa rántí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì mímọ́ sọ ṣáájú, àti òfin Olúwa àti Olùgbàlà wa láti ọ̀dọ̀ àwọn aposteli yín.
3 Kí ẹ kọ́ mọ èyí pé, nígbà ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ẹlẹ́gàn yóò dé pẹ̀lú ẹ̀gàn wọn. Wọn ó máa rìn nípa ìfẹ́ ara wọn. 4 Wọn ó sì máa wí pé, “Níbo ni ìlérí wíwà rẹ̀ gbé wà? Láti ìgbà tí àwọn baba ti sùn, ohun gbogbo ń lọ bí wọ́n ti wà rí láti ìgbà ọjọ́ yìí wá.” 5 (A)Nítorí èyí ni wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ ṣe àìfẹ́ ẹ́ mọ̀ pé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àwọn ọ̀run ti wà láti ìgbà àtijọ́ àti tí ilẹ̀ yọrí jáde nínú omi, tí ó sì dúró nínú omi. 6 Nípa èyí tí omi bo ayé tí ó wà nígbà náà tí ó sì ṣègbé. 7 Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀run àti ayé, tí ó ń bẹ nísinsin yìí, nípa ọ̀rọ̀ kan náà ni ó ti tò jọ bí ìṣúra fún iná, a pa wọ́n mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run.
8 (B)Ṣùgbọ́n, olùfẹ́, ẹ má ṣe gbàgbé ohun kan yìí, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa bí ẹgbẹ̀rún ọdún ni ó rí, àti ẹgbẹ̀rún ọdún bí ọjọ́ kan. 9 Olúwa kò fi ìlérí rẹ̀ jáfara, bí àwọn ẹlòmíràn ti ka ìjáfara sí; ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, bí kò ṣe kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.
10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá bí olè ní òru; nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo ńlá, àti àwọn ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́, ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ó wà nínú rẹ̀ yóò sì jóná túútúú.
11 Ǹjẹ́ bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti yọ́ bẹ́ẹ̀, irú ènìyàn wo ni ẹ̀yin ìbá jẹ́ nínú ìwà mímọ́ gbogbo àti ìwà-bí-Ọlọ́run. 12 (C)Kí ẹ máa retí, kí ẹ sì máa múra gírí de dídé ọjọ́ Ọlọ́run, nítorí èyí tí àwọn ọ̀run yóò gbiná, tí wọn yóò di yíyọ́, tí àwọn ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́. 13 (D)Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, àwa ń retí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé títún nínú èyí tí òdodo ń gbé.
14 Nítorí náà, olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti ń retí irú nǹkan wọ̀nyí, ẹ múra gírí, kí a lè bá yín ní àlàáfíà ní àìlábàwọ́n, àti ní àìlábùkù lójú rẹ̀. 15 Kí ẹ sì máa kà á sí pé, sùúrù Olúwa wa ìgbàlà ni; bí Paulu pẹ̀lú arákùnrin wa olùfẹ́, ti kọ̀wé sí yín gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí a fi fún un. 16 Bí ó tí ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú nínú ìwé rẹ̀ gbogbo nínú èyí ti ohun mìíràn sọ̀rọ̀ láti yé ni gbé wà, èyí ti àwọn òpè àti àwọn aláìdúró níbìkan ń lo, bí wọ́n ti ń lo ìwé mímọ́ ìyókù, sí ìparun ara wọn.
17 Nítorí náà ẹ̀yin olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti mọ nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀, ẹ máa kíyèsára, kí a má ba à fi ìṣìnà àwọn ènìyàn búburú fà yín lọ, kí ẹ sì ṣubú kúrò ní ìdúró ṣinṣin yín. 18 Ṣùgbọ́n ẹ máa dàgbà nínú oore-ọ̀fẹ́ àti nínú ìmọ̀ Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.
Ẹni tí ògo wà fún nísinsin yìí àti títí láé! Àmín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.