Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 73:21-28

21 Nígbà tí inú mi bàjẹ́
    àti ọkàn mi ṣì korò,
22 Mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye;
    mo jẹ́ ẹranko ní iwájú rẹ.

23 Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo;
    ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.
24 Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi
    ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo
25 Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ?
    Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ.
26 Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà
    ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi
    àti ìpín mi títí láé.

27 Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé
    ìwọ ti pa gbogbo wọn run;
tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ rẹ
28 Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run
    Èmi ti fi Olúwa Olódùmarè ṣe ààbò mi;
    Kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.

Òwe 29

29 Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí
    yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.

Nígbà tí olódodo bá ń gbilẹ̀, àwọn ènìyàn a yọ̀
    nígbà tí ènìyàn búburú ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn ń kórìíra.

Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀
    ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá panṣágà kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́.

Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini,
    ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣe ojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládùúgbò rẹ̀
    ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀.

Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹ̀kùn rẹ̀
    ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀.

Olódodo ń máa ro ọ̀rọ̀ tálákà,
    ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kò sú sí i láti rò ó.

Àwọn ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè,
    ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò.

Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́n
    aláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà.

10 Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kò rí ẹni dídúró ṣinṣin
    wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo.

11 Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹnu rẹ̀ bínú
    ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu.

12 Bí olórí bá fetí sí irọ́,
    gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀.

13 Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí,
    Olúwa jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran.

14 Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ tálákà pẹ̀lú òtítọ́
    ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdímúlẹ̀ nígbà gbogbo.

15 Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n
    ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnrarẹ̀ a dójútì ìyá rẹ̀.

16 Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀
    ṣùgbọ́n olódodo yóò rí ìṣubú wọn.

17 Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíà
    yóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ.

18 Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà,
    ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfin mọ́.

19 A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́
    bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi ara sí i.

20 Ǹjẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀?
    Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ.

21 Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeré
    yóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn.

22 Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè,
    onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.

23 Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀
    ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì.

24 Ẹni tí ó ń kó ẹgbẹ́, olè kórìíra ọkàn ara rẹ̀,
    ó ń gbọ́ èpè olóhun kò sì le è fọhùn.

25 Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹ̀kùn
    ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu.

26 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóso,
    ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo.

27 Olódodo kórìíra àwọn aláìṣòótọ́:
    ènìyàn búburú kórìíra olódodo.

Johanu 7:25-36

Ṣé Jesu ni Kristi?

25 Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn ará Jerusalẹmu wí pé, “ẹni tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa kọ́ yìí? 26 Sì wò ó, ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kò sì wí nǹkan kan sí i. Àwọn olórí ha mọ̀ nítòótọ́ pé, èyí ni Kristi náà? 27 (A)Ṣùgbọ́n àwa mọ ibi tí ọkùnrin yí gbé ti wá: ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi bá dé, kò sí ẹni tí yóò mọ ibi tí ó gbé ti wá.”

28 (B)Nígbà náà ni Jesu kígbe ní tẹmpili bí ó ti ń kọ́ni, wí pé, “Ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá: èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀. 29 (C)Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó rán mi.”

30 (D)Nítorí náà wọ́n ń wá ọ̀nà à ti mú un: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e, nítorí tí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé. 31 (E)Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn sì gbà á gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Nígbà tí Kristi náà bá dé, yóò ha ṣe iṣẹ́ ààmì jù wọ̀nyí, tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ?”

32 Àwọn Farisi gbọ́ pé, ìjọ ènìyàn ń sọ nǹkan wọ̀nyí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀; àwọn Farisi àti àwọn olórí àlùfáà sì rán àwọn oníṣẹ́ lọ láti mú un.

33 (F)Nítorí náà Jesu wí fún wọn pé, “Níwọ́n ìgbà díẹ̀ ni èmi yóò wà pẹ̀lú yín, èmi yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó rán mi. 34 Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti ibi tí èmi bá wà, ẹ̀yin kì yóò le wà.”

35 (G)Nítorí náà ni àwọn Júù ń bá ara wọn sọ pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí yóò gbé lọ tí àwa kì yóò fi rí i? Yóò ha lọ sí àárín àwọn Helleni tí wọ́n fọ́n káàkiri, kí ó sì máa kọ́ àwọn Helleni bí. 36 Ọ̀rọ̀ kín ni èyí tí ó sọ yìí, ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi, àti ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà?”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.