Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Ti Safu. Saamu.
80 Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli;
ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran;
ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù, tàn jáde
2 Níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase.
Ru agbára rẹ̀ sókè;
wá fún ìgbàlà wa.
3 Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run;
jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
kí a bá à lè gbà wá là.
4 Olúwa Ọlọ́run alágbára,
ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó
sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?
5 Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn
ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
6 Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa,
àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.
7 Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára;
jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa,
kí a ba à lè gbà wá là.
8 Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti;
ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín.
9 Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un,
ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀
ó sì kún ilẹ̀ náà.
10 A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀,
ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run.
11 O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun,
ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì.
12 Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀
tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀?
13 Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́
àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.
14 Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára!
Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó!
Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,
15 Gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn,
àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ.
16 A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún;
ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé.
17 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,
ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ.
18 Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ;
mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.
19 Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára;
kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
kí á ba à lè gbà wá là.
Àwọn ọrun tuntun àti ayé tuntun
17 “Kíyèsi i, Èmi yóò dá
àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun
A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́,
tàbí kí wọn wá sí ọkàn.
18 Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láé
nínú ohun tí èmi yóò dá,
nítorí èmi yóò dá Jerusalẹmu láti jẹ́ ohun ìdùnnú
àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀.
19 Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmu
n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi;
ariwo ẹkún àti igbe
ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́.
20 “Títí láé a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀
ọmọ ọwọ́ tí yóò gbé fún ọjọ́ díẹ̀,
tàbí àgbàlagbà tí kì yóò lo ọjọ́ ayé rẹ̀ tán;
ẹni tí ó bá kú ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún
ni a ó pè ní ọ̀dọ́mọdé;
ẹni tí kò ba le pé ọgọ́rùn-ún kan
ni a ó pè ní ẹni ìfibú.
21 Wọn yó ò kọ́ ilé, wọn yóò sì gbé nínú wọn
wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì jẹ èso wọn.
22 Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmíràn láti gbé,
tàbí kí wọn gbìn fún ẹlòmíràn láti jẹ,
Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí igi kan,
bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí;
àwọn àyànfẹ́ mi yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́
wọn fún ìgbà pípẹ́.
23 Wọn kì yóò ṣe iṣẹ́ lásán,
wọn kí yóò bímọ fún wàhálà;
nítorí wọn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn ti Olúwa bùkún fún,
àwọn àti àwọn ìrandíran wọn pẹ̀lú wọn.
24 Kí wọn tó pè, èmi yóò dáhùn;
nígbà tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi yóò gbọ́.
25 (A)Ìkookò àti ọ̀dọ́-àgùntàn yóò jẹun pọ̀,
kìnnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù,
ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò.
Wọn kì yóò pa ni lára tàbí pa ni run
ní gbogbo òkè mímọ́ mi,”
ni Olúwa wí.
18 Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìní Olùtùnú, kí ẹ ma dàbí ọmọ tí kò ní òbí. Rárá o! Mo tún ń tọ̀ yín bọ̀. 19 (A)Nígbà díẹ̀ sí i, ayé kì yóò rí mi mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò rí mi: nítorí tí èmi wà láààyè, ẹ̀yin yóò wà láààyè pẹ̀lú. 20 Ní ọjọ́ náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi wà nínú Baba mi, àti ẹ̀yin nínú mi, àti èmi nínú yín. 21 Ẹni tí ó bá ní òfin mi, tí ó bá sì ń pa wọ́n mọ́, òun ni ẹni tí ó fẹ́ràn mi: ẹni tí ó bá sì fẹ́ràn mi, a ó fẹ́ràn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba mi, èmi ó sì fẹ́ràn rẹ̀, èmi ó sì fi ara mi hàn fún un.”
22 Judasi (kì í ṣe Judasi Iskariotu) wí fún un pé, “Olúwa, èéha ti ṣe tí ìwọ ó fi ara rẹ hàn fún àwa, tí kì yóò sì ṣe fún aráyé?”
23 (B)Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Bí ẹnìkan bá fẹ́ràn mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́; Baba mi yóò sì fẹ́ràn rẹ̀, àwa ó sì tọ̀ ọ́ wá, a ó sì ṣe ibùgbé wa pẹ̀lú rẹ̀. 24 Ẹni tí kò fẹ́ràn mi ni kò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́; ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin ń gbọ́ kì í ṣe ti èmi, ṣùgbọ́n ti Baba tí ó rán mi.
25 “Nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti sọ fún yín, nígbà tí mo ń bá yín gbé. 26 Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, òun ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yóò sì rán yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín. 27 (C)Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín pé, àlàáfíà mi ni mo fi fún yin, kì í ṣe bí ayé ti fi fún ni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ó wárìrì.
28 “Ẹ̀yin sá ti gbọ́ bí mo ti wí fún yín pé, ‘Èmi ń lọ, èmi ó sì tọ̀ yín wá.’ Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fẹ́ràn mi, ẹ̀yin ìbá yọ̀ nítorí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba; nítorí Baba mi tóbi jù mí lọ. 29 (D)Èmi sì ti sọ fún yín nísinsin yìí kí ó tó ṣẹ, pé nígbà tí ó bá ṣẹ, kí ẹ lè gbàgbọ́. 30 (E)Èmi kì yóò bá yín sọ̀rọ̀ púpọ̀: nítorí ọmọ-aládé ayé yí wá, kò sì ní nǹkan kan lòdì sí mi. 31 (F)Ṣùgbọ́n nítorí kí ayé lè mọ̀ pé èmi fẹ́ràn Baba; gẹ́gẹ́ bí Baba sì ti fi àṣẹ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi ń ṣe.
“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a lọ kúrò níhìn-ín yìí.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.