); Genesis 22:15-18 (God’s blessing promised again); 1 Thessalonians 4:9-12 (How to love one another) (Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn)
Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
47 Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn
ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀.
2 Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó
ọba ńlá lórí gbogbo ayé.
3 Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa
àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa
4 Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa
ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa.
5 Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀,
Olúwa ti òun ti ariwo ìpè.
6 Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn.
Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn!
7 Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé,
ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu!
8 Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí;
Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀.
9 Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ
gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamu
nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni,
òun ni ó ga jùlọ.
15 Angẹli Olúwa sì tún pe Abrahamu láti ọ̀run wá lẹ́ẹ̀kejì. 16 (A)Ó sì wí pé, Olúwa wí pé, “Mo fi ara mi búra, níwọ̀n bí ìwọ ti ṣe èyí, tí ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí, 17 (B)Nítòótọ́, ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí iyanrìn etí Òkun. Irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀tá wọn, 18 (C)àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu.”
9 Ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ará, a kò ní láti tún kọ̀wé sí i yín, ìdí ni pé, Ọlọ́run pàápàá ń kọ́ yín láti fẹ́ràn ara yín. 10 Nítòótọ́, ẹ ní ìfẹ́ fún àwọn arákùnrin tí ó wà káàkiri Makedonia. Síbẹ̀síbẹ̀ àwa ń bẹ̀ yín, ará, pé kí ẹ̀yin kí ó máa tẹ̀síwájú nínú rẹ̀. 11 (A)Ẹ jẹ́ kí èyí jẹ́ ìfẹ́ ọkàn yín láti gbé jẹ́ẹ́ àti láti mọ ti ara yín àti kí olúkúlùkù kọjú sí iṣẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti wí fún yín. 12 Èyí yóò mú kí àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ gbẹ́kẹ̀lé yín àti láti bu ọlá fún yín pẹ̀lú. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ kò ní máa wo ojú ẹnikẹ́ni láti fún yín ni owó tí ẹ ó fi san gbèsè.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.