Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
22 Paulu si dìde dúró láàrín Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Ateni, mo wòye pé ní ohun gbogbo ẹ kún fún ẹ̀sìn lọ́pọ̀lọpọ̀. 23 Nítorí bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo wo àwọn ohun tí ẹ̀yin ń sìn, mo sì rí pẹpẹ kan tí a kọ àkọlé yìí sí:
fún ọlọ́run àìmọ̀.
Ǹjẹ́ ẹni tí ẹ̀yin ń sìn ni àìmọ̀ òun náà ni èmi ń sọ fún yin.
24 (A)“Ọlọ́run náà tí ó dá ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òun náà tí í ṣe Olúwa ọ̀run àti ayé, kì í gbé tẹmpili tí a fi ọwọ́ kọ́; 25 Bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ènìyàn sìn ín, bí ẹni pé ó ń fẹ́ nǹkan, òun ni ó fi ìyè àti èémí àti ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn. 26 Ó sì tí tipasẹ̀ ẹnìkan dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé, ó sì ti pinnu àkókò tí a yàn tẹ́lẹ̀, àti ààlà ibùgbé wọn; 27 Ọlọ́run ṣe eléyìí kí wọn bá le máa wa, bóyá wọn yóò lè ṣàfẹ́rí rẹ̀, kí wọn sì rí í. Bí ó tilẹ̀ jẹ pé kò jìnnà sí olúkúlùkù wa: 28 Nítorí nínú rẹ̀ ni àwa wà láààyè, tí a ń rìn kiri, tí a sì ní ẹ̀mí wa: bí àwọn kan nínú àwọn akéwì tí ẹ̀yin tìkára yín tí wí pé, ‘Àwa pẹ̀lú sì jẹ́ ọmọ rẹ̀.’
29 “Ǹjẹ́ bí àwa bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, kò yẹ fún wa láti rò pé, ẹni tí a wa n sìn dàbí wúrà, tàbí fàdákà, tàbí òkúta, tí a fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ ènìyàn ya ère àwòrán rẹ̀. 30 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìgbà àìmọ̀ yìí ni Ọlọ́run tí fojú fò dá; ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ronúpìwàdà; 31 Níwọ́n bí ó ti dá ọjọ́ kan, nínú èyí tí yóò ṣe ìdájọ́ ayé lódodo nípasẹ̀ ọkùnrin náà tí ó ti yàn, nígbà tí ó ti fi ohun ìdánilójú fún gbogbo ènìyàn, ní ti pé ó jí dìde kúrò nínú òkú.”
8 Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn,
jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀;
9 Ó ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa,
kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí ó yẹ̀
10 Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò;
ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò.
11 Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n
o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa
12 Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí
àwa la iná àti omi kọjá
ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.
13 Èmi ó wá sí tẹmpili rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun,
kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ
14 Ẹ̀jẹ́ tí ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọ
nígbà tí mo wà nínú ìṣòro.
15 Èmi ó rú ẹbọ sísun ọlọ́ràá sí ọ,
àti ẹbọ ọ̀rá àgbò;
èmi ó rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. Sela.
16 Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run;
ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi.
17 Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i:
Ìyìn rẹ̀ wà ní ẹnu mi.
18 Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi,
Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi;
19 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́
ó ti gbọ́ ohùn mi nínú àdúrà.
20 Ìyìn ni fún Ọlọ́run
ẹni tí kò kọ àdúrà mi
tàbí mú ìfẹ́ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!
13 Tá nì yóò sì ṣe yín ní ibi, bí ẹ̀yin bá jẹ́ onítara sí ohun rere? 14 (A)Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, a ti bùkún yín. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù ìhàlẹ̀ wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú.” 15 Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kristi bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń béèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù. 16 Kí ẹ máa ni ẹ̀rí ọkàn rere bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kristi. 17 Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣíṣe búburú lọ. 18 Nítorí tí Kristi pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ fún àwọn aláìṣòótọ́, kí a lè mú wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí: 19 Nínú èyí tí ó lọ pẹ̀lú tí ó sì wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú túbú: 20 (B)àwọn tí ó ṣe aláìgbọ́ràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run dúró pẹ́ ní sá à kan ní ọjọ́ Noa, nígbà tí wọ́n fi kan ọkọ̀ nínú èyí tí a gba ọkàn díẹ̀ là nípa omi, èyí ni ẹni mẹ́jọ. 21 Àpẹẹrẹ èyí ti ń gbà yín là nísinsin yìí pẹ̀lú, àní ìtẹ̀bọmi, kì í ṣe wíwẹ́ èérí ti ara nù, bí kò ṣe ìdáhùn ẹ̀rí ọkàn rere si Ọlọ́run, nípa àjíǹde Jesu Kristi. 22 Ẹni tí ó lọ sí ọ̀run, tí ó sì ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run: pẹ̀lú àwọn angẹli, àwọn aláṣẹ, àti àwọn alágbára sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.
Jesu ṣe ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́
15 (A)“Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́. 16 (B)Nígbà náà èmi yóò wá béèrè lọ́wọ́ Baba. Òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn. Olùtùnú náà yóò máa bá yín gbé títí láé 17 Òun ni Ẹ̀mí òtítọ́. Ayé kò le gbà á. Nítorí ayé kò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò rí i rí. Ẹ̀yin mọ̀ ọn nítorí láti ìgbà tí ẹ ti wà pẹ̀lú mí. Òun náà ti wà pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan yóò wọ inú yín láti máa gbé ibẹ̀. 18 Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìní Olùtùnú, kí ẹ ma dàbí ọmọ tí kò ní òbí. Rárá o! Mo tún ń tọ̀ yín bọ̀. 19 (C)Nígbà díẹ̀ sí i, ayé kì yóò rí mi mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò rí mi: nítorí tí èmi wà láààyè, ẹ̀yin yóò wà láààyè pẹ̀lú. 20 Ní ọjọ́ náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi wà nínú Baba mi, àti ẹ̀yin nínú mi, àti èmi nínú yín. 21 Ẹni tí ó bá ní òfin mi, tí ó bá sì ń pa wọ́n mọ́, òun ni ẹni tí ó fẹ́ràn mi: ẹni tí ó bá sì fẹ́ràn mi, a ó fẹ́ràn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba mi, èmi ó sì fẹ́ràn rẹ̀, èmi ó sì fi ara mi hàn fún un.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.