Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ti Solomoni
72 Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run,
ọmọ-aládé ni ìwọ fi òdodo rẹ fún
2 Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo,
yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà rẹ̀.
3 Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn
àti òkè kéékèèkéé nípa òdodo
4 Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn
yóò gba àwọn ọmọ aláìní;
yóò sì fa àwọn aninilára ya.
5 Àwọn òtòṣì àti aláìní
yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo,
níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn,
yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran.
6 Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀
Bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀
7 Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ rẹ̀
ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà;
títí tí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.
8 Yóò máa jẹ ọba láti Òkun dé Òkun
àti láti odò Eufurate títí dé òpin ayé.
9 Àwọn tí ó wà ní aginjù yóò tẹríba fún un
àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀.
10 Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù
wọn yóò mú ọrẹ wá fún un;
àwọn ọba Ṣeba àti Seba
wọn ó mú ẹ̀bùn wá fún un.
11 Gbogbo ọba yóò tẹríba fún un
àti gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sìn ín.
12 Nítorí yóò gba àwọn aláìní
nígbà tí ó bá ń ké,
tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
13 Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní
yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.
14 Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá
nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀.
15 Yóò sì pẹ́ ní ayé!
A ó sì fún un ní wúrà Ṣeba.
Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo
kí a sì bùkún fún un lójoojúmọ́.
16 Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀;
ní orí òkè ni kí ó máa dàgbà
kí èso rẹ̀ kí o gbilẹ̀ bí ti Lebanoni
yóò máa gbá yìn bí i koríko ilẹ̀.
17 Kí orúkọ rẹ̀ kí ó wà títí láé;
orúkọ rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ níwọ̀n bí oòrùn yóò ti pẹ́ tó.
Wọn ó sì máa bùkún fún ara wọn nípasẹ̀ rẹ.
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
18 Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli,
ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń ṣe ohun ìyanu.
19 Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó lógo títí láé;
kí gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.
Àmín àti Àmín.
20 Èyí ni ìparí àdúrà Dafidi ọmọ Jese.
Mose àti igbó tí ń jó
3 (A)Ní ọjọ́ kan nígbà tí Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jetro baba ìyàwó rẹ̀, àlùfáà Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ọ̀nà jíjìn nínú aginjù. Ó dé Horebu, òkè Ọlọ́run. 2 (B)Níbẹ̀ ni angẹli Olúwa ti yọ sí i nínú ọ̀wọ́-iná tí ń jó láàrín igbó. Mose rí i pé iná ń jó nínú igbó ṣùgbọ́n igbó kò run 3 Nígbà náà ni Mose sọ pé, “Èmi yóò lọ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná kò fi jó igbó run.”
4 Nígbà tí Olúwa rí i pe Mose ti lọ láti lọ wò ó, Ọlọ́run ké pè é láti àárín igbó náà, “Mose! Mose!”
Mose sì dáhùn ó wí pé, “Èmi nìyìí.”
5 (C)Olúwa sì wí fún Mose pé, “Má ṣe súnmọ́ ìhín yìí, bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni.”
23 (A)Nípa ìgbàgbọ́ ní àwọn òbí Mose pa a mọ́ fún oṣù mẹ́ta nígbà tí a bí i, nítorí tiwọn rí i ní arẹwà ọmọ; wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba.
24 (B)Nípa ìgbàgbọ́ ni Mose, nígbà tí o dàgbà, ó kọ̀ ki a máa pé òun ni ọmọ ọmọbìnrin Farao; 25 o kúkú yàn láti máa ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jìyà, ju jíjẹ fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. 26 Ó ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúra Ejibiti lọ: Nítorí tí ó ń wo èrè náà. 27 (C)Nípa ìgbàgbọ́ ni o kọ Ejibiti sílẹ̀ láìbẹ̀rù ìbínú ọba: nítorí tí o dúró ṣinṣin bí ẹni tí ó n ri ẹni àìrí. 28 (D)Nípa ìgbàgbọ́ ni ó da àsè ìrékọjá sílẹ̀, àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀, kí ẹni tí ń pa àwọn àkọ́bí ọmọ má bá a fi ọwọ́ kan wọn.
29 (E)Nípa ìgbàgbọ́ ni wọn la Òkun pupa kọjá bi ẹni pé ni ìyàngbẹ ilẹ̀: ti àwọn ara Ejibiti dánwò, tí wọ́n sì ri.
30 (F)Nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn odi Jeriko wo lulẹ̀, lẹ́yìn ìgbà tí a yí wọn ká ni ọjọ́ méje.
31 (G)Nípa ìgbàgbọ́ ni Rahabu panṣágà kò ṣègbé pẹ̀lú àwọn tí kò gbọ́rọ̀ nígbà tí o tẹ́wọ́gbà àwọn ààmì ní àlàáfíà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.