Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Samuẹli 2:1-10

Àdúrà Hana

Hana sì gbàdúrà pé:

“Ọkàn mi yọ̀ sí Olúwa;
    Ìwo agbára mi ni a sì gbé sókè sí Olúwa.
Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀tá mi,
    nítorí ti èmi yọ̀ ni ìgbàlà rẹ̀.

“Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi Olúwa;
    kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ;
    kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa.

“Má ṣe halẹ̀;
    má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jáde
nítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni Olúwa,
    láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà.

“Ọ̀run àwọn alágbára ti ṣẹ́,
    àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè.
Àwọn tí ó yọ̀ fún oúnjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe,
    àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní.
Tó bẹ́ẹ̀ tí àgàn fi bí méje.
    Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára.

Olúwa pa ó sì sọ di ààyè;
    ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde.
Olúwa sọ di tálákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀;
    ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè.
Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá,
    ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá,
láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé,
    láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo:

“Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti Olúwa ni,
    ó sì ti gbé ayé ka orí wọn
Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́,
    àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn.

“Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí.
10     A ó fọ́ àwọn ọ̀tá Olúwa túútúú;
láti ọ̀run wá ni yóò sán àrá sí wọn;
    Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé.

“Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀,
    yóò si gbé ìwo ẹni ààmì òróró rẹ̀ sókè.”

Gẹnẹsisi 37:2-11

Èyí ni àwọn ìtàn Jakọbu.

Nígbà tí Josẹfu di ọmọ ọdún mẹ́tà-dínlógún (17), ó ń ṣọ́ agbo ẹran pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Biliha àti Silipa aya baba rẹ̀ Josẹfu sì ń ròyìn àwọn aburú tí wọ́n ń ṣe fún baba wọn.

Israẹli sì fẹ́ràn Josẹfu ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tókù lọ, nítorí ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ni ó bí i. O sì dá aṣọ aláràbarà tí ó kún fún onírúurú ọnà lára fún un. Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ rí i pé baba àwọn fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọ́n sì ń fi ẹ̀tanú bá a gbé, kò sì sí àlàáfíà láàrín wọn.

Josẹfu lá àlá kan, nígbà tí ó sì sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i. O wí fún wọn pé, “Ẹ fetí sí àlá tí mo lá: Sá à wò ó, àwa ń yí ìtí ọkà nínú oko, ó sì ṣe ìtí ọkà tèmi sì dìde dúró ṣánṣán, àwọn ìtí ọkà tiyín sì dúró yí ìtí tèmi ká, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún un.”

Àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ ń gbèrò àti jẹ ọba lé wa lórí bí? Tàbí ìwọ ó ṣe olórí wa nítòótọ́?” Wọn sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i, nítorí àlá rẹ̀ àti nítorí ohun tí ó wí.

O sì tún lá àlá mìíràn, ó sì tún sọ ọ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó wí pé, ẹ tẹ́tí sí mi, “Mo tún lá àlá mìíràn, wò ó, oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá ń foríbalẹ̀ fún mi.”

10 Nígbà tí ó sọ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú, baba rẹ̀ bá a wí pé, “irú àlá wo ni ìwọ lá yìí? Ṣé ìyá rẹ, pẹ̀lú èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ yóò wá foríbalẹ̀ níwájú rẹ ni?” 11 (A)Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ń ṣe ìlara rẹ̀ ṣùgbọ́n baba rẹ̀ pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ lọ́kàn rẹ̀.

Matiu 1:1-17

Àkọsílẹ̀ ìwé ìran Jesu Kristi

Ìwé ìran Jesu Kristi, ẹni tí í ṣe ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu:

Abrahamu ni baba Isaaki;

Isaaki ni baba Jakọbu;

Jakọbu ni baba Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀,

Juda ni baba Peresi àti Sera,

Tamari sì ni ìyá rẹ̀,

Peresi ni baba Hesroni:

Hesroni ni baba Ramu;

Ramu ni baba Amminadabu;

Amminadabu ni baba Nahiṣoni;

Nahiṣoni ni baba Salmoni;

Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀;

Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀;

Obedi sì ni baba Jese;

Jese ni baba Dafidi ọba.

Dafidi ni baba Solomoni, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Uriah tẹ́lẹ̀ rí.

Solomoni ni baba Rehoboamu,

Rehoboamu ni baba Abijah,

Abijah ni baba Asa,

Asa ni baba Jehoṣafati;

Jehoṣafati ni baba Jehoramu;

Jehoramu ni baba Ussiah;

Ussiah ni baba Jotamu;

Jotamu ni baba Ahaṣi;

Ahaṣi ni baba Hesekiah;

10 Hesekiah ni baba Manase;

Manase ni baba Amoni;

Amoni ni baba Josiah;

11 (A)Josiah sì ni baba Jekoniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkólọ sí Babeli.

12 Lẹ́yìn ìkólọ sí Babeli:

Jekoniah ni baba Ṣealitieli;

Ṣealitieli ni baba Serubbabeli;

13 Serubbabeli ni baba Abihudi;

Abihudi ni baba Eliakimu;

Eliakimu ni baba Asori;

14 Asori ni baba Sadoku;

Sadoku ni baba Akimu;

Akimu ni baba Elihudi;

15 Elihudi ni baba Eleasari;

Eleasari ni baba Mattani;

Mattani ni baba Jakọbu;

16 Jakọbu ni baba Josẹfu, ẹni tí ń ṣe ọkọ Maria, ìyá Jesu, ẹni tí í ṣe Kristi.

17 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọ́n jẹ́ ìran mẹ́rìnlá láti orí Abrahamu dé orí Dafidi, ìran mẹ́rìnlá á láti orí Dafidi títí dé ìkólọ sí Babeli, àti ìran mẹ́rìnlá láti ìkólọ títí dé orí Kristi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.