Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
147 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa,
ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!
2 Olúwa kọ́ Jerusalẹmu;
Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.
3 Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn
ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.
4 Ó ka iye àwọn ìràwọ̀
ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ
5 Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára
òye rẹ̀ kò sì ní òpin.
6 Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.
7 Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa
fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.
8 Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀
ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé
ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè
9 Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko
àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.
10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin
bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin
11 Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.
20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, Bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀
wọn ko mọ òfin rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
36 Elihu sì tún sọ̀rọ̀ wí pé:
2 “Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fihàn ọ́,
nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run.
3 Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jíjìn wá,
èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi.
4 Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèké
nítòótọ́; ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.
5 “Kíyèsi i, Ọlọ́run ni alágbára, òun kò i sì
gàn ènìyàn; ó ní agbára ní ipá àti òye.
6 Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí,
ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà.
7 Òun kì í mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo,
ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́;
àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.
8 Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà, tí a
sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,
9 Nígbà náà ni ó ń sọ àwọn ohun tí wọn ti ṣe fún wọn,
wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga wọn.
10 Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́,
ó sì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedédé.
11 Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín,
wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀rùn,
àti ọdún wọn nínú afẹ́.
12 Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́,
wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé,
wọ́n á sì kú láìní òye.
13 “Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní ayé kó ìbínú jọ;
wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá wọ́n wí.
14 Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe,
ní àárín àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà.
15 Òun gba òtòṣì nínú ìpọ́njú wọn,
a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínú ìnira wọn.
16 “Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó fa wọn yọ láti inú ìhágágá sí ibi gbòòrò,
sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀,
ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́.
17 Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú;
ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú.
18 Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹ máa bá a tàn ọ;
láti jẹ́ kí títóbi rẹ mú ọ ṣìnà.
19 Ọrọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí?
Tàbí ipa agbára rẹ?
20 Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń ké
àwọn orílẹ̀-èdè kúrò ní ipò wọn.
21 Máa ṣọ́ra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀ padà sí búburú;
Nítorí èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ.
22 “Kíyèsi i, Ọlọ́run ni gbéga nípa agbára rẹ̀;
ta ni jẹ́ olùkọ́ni bí rẹ̀?
23 Ta ni ó là ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún un,
tàbí ta ni ó lè wí pé ìwọ ti ń ṣe àìṣedéédéé?
Àwọn ẹ̀tọ́ aposteli
9 (A)Èmi kò ha ni òmìnira bí? Èmi kò ha ń ṣe aposteli bí? Èmi kò ha ti rí Jesu Olúwa bí? Ẹ̀yìn ha kọ́ ní èrè iṣẹ́ mi nínú Olúwa bí? 2 Ní ìrònú àwọn ẹlòmíràn, èmi kì í ṣe aposteli. Dájúdájú aposteli ni mo jẹ́ fún un yín, tí n kì bá ṣe fún àwọn ẹlòmíràn. Nítorí èdìdì iṣẹ́ aposteli mi ni ẹ̀yin jẹ́ nínú Olúwa.
3 Èyí ni ìdáhùn mi sí àwọn tí ń béèrè ẹ̀tọ́ aposteli mi. 4 (B)Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹ àti láti máa mu bí? 5 (C)Ṣé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú ìyàwó tí í ṣe onígbàgbọ́ káàkiri gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli mìíràn? Àti bí arákùnrin Olúwa, àti Kefa. 6 (D)Ṣé èmi nìkan àti Barnaba, àwa kò ha ní agbára láti máa ṣiṣẹ́ bọ́ ara wa ni?
7 Ta ni ó ṣíṣẹ́ ológun tí ó sanwó ara rẹ̀? Ta ní gbin ọgbà àjàrà tí kì í jẹ nínú èso rẹ̀? Tàbí ta ní ń bọ ọ̀wọ́ ẹran tí kì í sí ì jẹ nínú wàrà ọ̀wọ́ ẹran? 8 Èmi ha sọ nǹkan wọ̀nyí bí ènìyàn? Tàbí òfin kò wí bákan náà bì? 9 (E)Nítorí nínú òfin tí Ọlọ́run fún Mose, ni a tí kọ ọ́ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu.” Ǹjẹ́ màlúù ni Ọlọ́run n ṣe ìtọ́jú rẹ̀ bi? 10 (F)Dájúdájú ó sọ eléyìí fún wa pé, nítorí wa ni a ṣe kọ̀wé yìí kí ẹni tí ń tulẹ̀ lè máa tulẹ̀ ní ìrètí àti ẹni tí ń pakà lè ni ìrètí láti ní ìpín nínú ìkórè. 11 (G)Bí àwa ti fún irúgbìn ohun ti ẹ̀mí sínú ọkàn yín, ohun ńlá ha ni bí àwa ó ba ká ohun ti yín tí ṣe ti ara? 12 (H)Bí àwọn ẹlòmíràn bá ní ẹ̀tọ́ tí ìrànlọ́wọ́ sì wá láti ọ̀dọ̀ yín, àwa ha kọ́ ni ó tọ́ sí jù?
Ṣùgbọ́n àwa kò lo agbára yìí ṣùgbọ́n àwa faradà ohun gbogbo, kí àwa má ba à ṣe ìdènà fún ìhìnrere Kristi.
13 (I)Ǹjẹ́ ó yé e yín pé Ọlọ́run sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹmpili pé kí wọ́n mú oúnjẹ tàbí àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú wá fún òun, láti fi ṣe ìtọ́jú ara wọn? Àti àwọn tí ń dúró tí pẹpẹ wọn a máa ṣe àjọpín pẹ̀lú pẹpẹ. 14 (J)Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ti fi àṣẹ lélẹ̀ pé, àwọn tí ń wàásù ìhìnrere kí wọn sì máa jẹ́ nípa ìhìnrere.
15 (K)Síbẹ̀síbẹ̀ n kò ì tí ì lo irú àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí rí. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì kọ ìwé yìí láti fi sọ fún un yín pé, mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà irú nǹkan bẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ yín. Kí a sọ òtítọ́, ó sàn fún mi láti kú sínú ebi ju pé kí n sọ ògo tí mo ní láti wàásù nù. 16 Nítorí pé bí mo ti ń wàásù ìhìnrere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa ṣògo lè. Èmi kò tilẹ̀ le è ṣe é ní, kí a tilẹ̀ sọ pé mo fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ègbé ni fún mi tí mo bá kọ̀ láti wàásù ìhìnrere.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.