Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
2 Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,
èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù.
Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,
òun ti di ìgbàlà mi.”
3 Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi
láti inú kànga ìgbàlà.
4 Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé:
“Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,
Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
ohun tí ó ti ṣe
kí o sì kéde pé a ti gbé
orúkọ rẹ̀ ga.
5 Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo,
jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.
6 Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni,
nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo
ti Israẹli láàrín yín.”
Ègbé ni fún àwọn tí ara rọ̀
6 Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Sioni
àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaria
àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè
tí ẹ̀yin ènìyàn Israẹli máa ń tọ̀ ọ́ wá
2 Ẹ lọ Kalne kí ẹ lọ wò ó
kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Hamati ìlú ńlá a nì.
Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gati ní ilẹ̀ Filistini
Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ?
Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju tiyín lọ bí?
3 Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú,
ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòsí
4 Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe
ẹ sì tẹ́ ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn
ẹyin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yín jẹ
ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrín agbo wọn jẹ
5 Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dafidi
ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ àwọn ohun èlò orin
6 Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan
àti ìkunra tí o dára jùlọ
ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé Josẹfu tí ó di ahoro
7 Nítorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn
pẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùn
àsè àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò.
Olúwa Kórìíra Ìgbéraga Ọmọ Israẹli
8 Olúwa Olódùmarè ti búra fúnrarẹ̀, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì ti wí pé:
“Mo kórìíra ìgbéraga Jakọbu
n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀
Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́
àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.”
Ọ̀rọ̀ ìyànjú lórí ìfifúnni
8 Pẹ̀lúpẹ̀lú, ará, àwa ń sọ fún yín ní ti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fífún àwọn ìjọ Makedonia; 2 Bí ó ti jẹ́ pé a dán wọn wò nípa ìpọ́njú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ àti àìlódiwọ̀n àìní wọn ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìlawọ́ wọn. 3 (A)Nítorí mo jẹ́rìí pé gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, àní ju agbára wọn, wọ́n ṣe é láti ìfẹ́ inú ara wọn. 4 (B)Wọ́n ń fi ẹ̀bẹ̀ púpọ̀ rọ̀ wá ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí, láti ba à lè ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́. 5 Àti èyí, kì í ṣe bí àwa tí rò rí, ṣùgbọ́n wọ́n tètè kọ́ fi àwọn fúnrawọn fún Olúwa, àti fún wá, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run. 6 (C)Tó bẹ́ẹ̀ tí àwa fi gba Titu níyànjú pé, bí ó tí bẹ̀rẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì parí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí nínú yín pẹ̀lú. 7 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti pọ̀ lóhùn gbogbo, ní ìgbàgbọ́, àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀, àti nínú iṣẹ́ ìhìnrere gbogbo, àti ní ìfẹ́ yín sí wa, ẹ rí i wí pé ẹ̀yin pọ̀ sí i nínú ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí pẹ̀lú.
8 Kì í ṣe nípa àṣẹ ni mo fi ń sọ ọ́, ṣùgbọ́n kí a lè rí ìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín pẹ̀lú, nípa iṣẹ́ ìhìnrere ẹlòmíràn. 9 (D)Nítorí ẹ̀yin mọ oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa Jesu Kristi, pé bí òun ti jẹ́ ọlọ́rọ̀ rí ṣùgbọ́n nítorí yín ó di tálákà kí a lè sọ yín di ọlọ́rọ̀ nípa àìní rẹ̀.
10 (E)Àti nínú èyí ni mo fi ìmọ̀ràn mi fún yín: nítorí èyí ṣe àǹfààní fún yín, ẹ̀yin tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ níwọ̀n ọdún tí ó kọjá, kì í ṣe láti ṣe nǹkan, ṣùgbọ́n láti fẹ́ pẹ̀lú. 11 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ parí ṣíṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú; kí ó ba à lè ṣe pé, bí ìpinnu fún ṣíṣe ti wà, bẹ́ẹ̀ ni kí ìparí sì wà láti inú agbára yín. 12 Nítorí bí ìpinnu bá wà ṣáájú, ó jásí ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ènìyàn bá ní, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ní.
13 Nítorí èmi kò fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn wà ní ìrọ̀rùn, kí ó sì jẹ́ ìpọ́njú fún yín, ṣùgbọ́n pé nípa mímú dọ́gba, 14 Ní àkókò yìí, pé kí àníṣẹ́kù yín lè ṣe déédé àìní wọn, kí àníṣẹ́kù tiwọn pẹ̀lú ba à lè ṣe déédé àìní yín: kí ìmúdọ́gba ba à lè wà. 15 (F)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.