Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:105-112

Òfin Olúwa ni fìtílà mi

105 Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi
    àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi
106 Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn
    wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ.
107 A pọ́n mi lójú gidigidi;
    Olúwa, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ
108 Olúwa, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi,
    kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀.
109 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi
    nígbà gbogbo,
    èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
110 Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi,
    ṣùgbọ́n èmi kò ṣìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
111 Òfin rẹ ni ogún mi láéláé;
    àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.
112 Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́
    láé dé òpin.

2 Ọba 23:1-8

Josiah sọ májẹ̀mú dọ̀tun

23 Nígbà náà ọba pe gbogbo àwọn àgbàgbà Juda àti Jerusalẹmu jọ. Ó gòkè lọ sí ilé Olúwa pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu, àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì—gbogbo àwọn ènìyàn láti ibi kéékèèkéé sí ńlá. Ó kà á sí etí ìgbọ́ ọ wọn, gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé májẹ̀mú, tí a ti rí nínú ilé Olúwa. Ọba sì dúró lẹ́bàá òpó, ó sì sọ májẹ̀mú di tuntun níwájú Olúwa láti tẹ̀lé Olúwa àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, ìlànà àti òfin pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo ẹ̀mí rẹ̀, àti láti ṣe ìwádìí àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sínú ìwé yìí. Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn sì ṣèlérí fúnrawọn sí májẹ̀mú náà.

(A)Ọba sì pàṣẹ fún Hilkiah olórí àlùfáà àti àwọn, àlùfáà tí ó tẹ̀lé e ní ipò àti àwọn olùṣọ́nà láti yọ kúrò nínú ilé Olúwa gbogbo ohun èlò tí a ṣe fún Baali àti Aṣerah àti gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run. Ó sì sun wọ́n ní ìta Jerusalẹmu ní pápá Àfonífojì Kidironi. Ó sì kó eérú wọn jọ sí Beteli. Ó sì kúrò pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà tí a yàn láti ọwọ́ ọba Juda láti sun tùràrí ní ibi gíga ti ìlú Juda àti àwọn tí ó yí Jerusalẹmu ká. Àwọn tí ó ń sun tùràrí sí Baali, sí oòrùn àti òṣùpá, sí àwọn ààmì ìràwọ̀ àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run. Ó mú ère òrìṣà Aṣerah láti ilé Olúwa sí Àfonífojì Kidironi ní ìta Jerusalẹmu, ó sì sun wọ́n níbẹ̀. Ó lọ̀ ọ́ bí àtíkè ó sì fọ́n eruku náà sórí isà òkú àwọn ènìyàn tí ó wọ́pọ̀. Ó sì wó ibùgbé àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà lulẹ̀. Tí ó wà nínú ilé Olúwa àti ibi tí àwọn obìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ aṣọ híhun fún òrìṣà Aṣerah.

Josiah kó gbogbo àwọn àlùfáà láti àwọn ìlú Juda ó sì ba ibi mímọ́ wọ̀n-ọn-nì jẹ́ láti Geba sí Beerṣeba, níbi tí àwọn àlùfáà ti sun tùràrí. Ó wó àwọn ojúbọ lulẹ̀ ní ẹnu ìlẹ̀kùn—ní ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ti Joṣua, baálẹ̀ ìlú ńlá tí ó wà ní apá òsì ẹnu ìlẹ̀kùn ìlú ńlá.

2 Ọba 23:21-25

21 (A)Ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé: “Ẹ ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá sí Olúwa Ọlọ́run yín, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sí inú ìwé májẹ̀mú yìí.” 22 Kì í ṣe láti ọjọ́ àwọn Juda tí ó tọ́ Israẹli, ní gbogbo àwọn ọjọ́ àwọn ọba Israẹli àti àwọn ọba Juda. Ṣé wọ́n ti ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá rí. 23 Ṣùgbọ́n ní ọdún kejì-dínlógún tí ọba Josiah, àjọ ìrékọjá yìí ni a ṣe ìrántí sí Olúwa ní Jerusalẹmu.

24 Síwájú sí, Josiah sì lé àwọn oṣó àti àwọn ẹ̀mí ní àwọn ìdílé, àti àwọn òrìṣà àti gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí a rí ní Juda àti ní Jerusalẹmu. Èyí ni ó ṣe kí ó le è mú ọ̀rọ̀ òfin náà ṣe ní ti òfin tí a kọ sínú ìwé tí Hilkiah àlùfáà ti rí nínú ilé Olúwa. 25 Kò sì sí ọba kankan níwájú tàbí lẹ́yìn Josiah tí ó dàbí rẹ̀, tí ó yí padà sí olúwa tinútinú àti gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tọkàntọkàn pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí i rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin Mose.

2 Kọrinti 4:1-12

Ìṣúra nínú ohun-èlò amọ̀

Nítorí náà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé nípa àánú Ọlọ́run ni a rí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí gba, àárẹ̀ kò mú ọkàn wa rara; Ṣùgbọ́n àwa tí kọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ tí ó ní ìtìjú sílẹ̀, àwa kò rìn ní ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò fi ọwọ́ ẹ̀tàn mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n nípa fífi òtítọ́ hàn, àwa ń fi ara wa le ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù ènìyàn lọ́wọ́ níwájú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n báyìí, bí Ìhìnrere wa bá sí fi ara sin, ó fi ara sin fún àwọn tí ó ń ṣègbé. (A)Nínú àwọn ẹni tí ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àwòrán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn. Nítorí àwa kò wàásù àwa tìkára wa, bí kò ṣe Kristi Jesu Olúwa; àwa tìkára wa sì jẹ́ ẹrú yín nítorí Jesu. (B)Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ ó tan láti inú òkùnkùn jáde,” òun ní ó ti ń tan mọ́lẹ̀ lọ́kàn wa, láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run ní ojú Jesu Kristi.

Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò amọ̀, kí ọláńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá. A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dààmú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù. A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run. 10 Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jesu Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jesu hàn pẹ̀lú lára wa. 11 Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fi àwa tí ó wà láààyè fún ikú nítorí Jesu, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú. 12 Bẹ́ẹ̀ ni ikú ń ṣiṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè ṣiṣẹ́ nínú yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.