Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Saamu ti Dafidi
15 Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ?
Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?
2 Ẹni tí ń rìn déédé
tí ó sì ń sọ òtítọ́,
láti inú ọkàn rẹ̀;
3 tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,
tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀
tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀,
4 ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígàn
ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
Ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀
àní tí kò sì yípadà,
5 tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé
tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí
ni a kì yóò mì láéláé.
Àwọn adájọ́
18 Ẹ yan àwọn adájọ́ àti àwọn olóyè fún ẹ̀yà a yín kọ̀ọ̀kan, ní gbogbo ìlú tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò fún un yín, wọ́n sì gbọdọ̀ máa fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn. 19 (A)Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú ènìyàn. Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọ́gbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ olódodo jẹ́. 20 Ẹ tẹ̀lé ìdájọ́ òtítọ́ àní ìdájọ́ òtítọ́ nìkan, kí ẹ bá à lè gbé kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń fún un yín.
Jíjìyà fún ṣíṣe iṣẹ́ rere
8 Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ 9 Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún. 10 (A)Nítorí,
“Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè,
ti yóò sì rí ọjọ́ rere,
kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi,
àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn:
11 Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere;
kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.
12 Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo,
etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn:
ṣùgbọ́n ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.