Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 40:6-17

(A)Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,
    ìwọ ti ṣí mi ní etí.
Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀
    ni ìwọ kò béèrè.
Nígbà náà ni mo wí pé,
    “Èmi nìyí;
nínú ìwé kíká ni
    a kọ ọ nípa tèmi wí pé.
Mo ní inú dídùn
    láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ,
ìwọ Ọlọ́run mi;
    Òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà
    láàrín àwùjọ ńlá;
wò ó,
    èmi kò pa ètè mi mọ́,
gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀,
    ìwọ Olúwa.
10 Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà sin ní àyà mi;
    èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti ìgbàlà rẹ.
Èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ mọ́
    kúrò láàrín àwọn ìjọ ńlá.

11 Ìwọ má ṣe,
    fa àánú rẹ tí ó rọ́nú
sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; Olúwa
    jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ
àti òtítọ́ rẹ
    kí ó máa pa mi mọ́
títí ayérayé.
12 Nítorí pé àìníye ibi
    ni ó yí mi káàkiri,
ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi,
    títí tí èmi kò fi ríran mọ́;
wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,
    àti wí pé àyà mí ti kùnà.

13 (B)Jẹ́ kí ó wù ọ́,
    ìwọ Olúwa,
láti gbà mí là;
    Olúwa,
yára láti ràn mí lọ́wọ́.

14 Gbogbo àwọn wọ̀n-ọn-nì
    ni kí ojú kí ó tì
kí wọn kí ó sì dààmú
    àwọn tí ń wá ọkàn mi
láti parun:
    jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn
kí a sì dójútì wọ́n,
    àwọn tí ń wá ìpalára mi.
15 Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Háà! Háà!”
    ó di ẹni à fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtìjú wọn.
16 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ
    kí ó máa yọ̀
kí inú wọn sì máa dùn sí ọ;
    kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà rẹ
kí o máa wí nígbà gbogbo pé,
    “Gbígbéga ni Olúwa!”

17 Bí ó ṣe ti èmi ni,
    tálákà àti aláìní ni èmi,
ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi.
    Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi
àti ìgbàlà mi;
    Má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́,
    ìwọ Ọlọ́run mi.

Isaiah 53

53 (A)Ta ni ó ti gba ìròyìn in wa gbọ́
    àti ta ni a ti fi apá Olúwa hàn fún?
Òun dàgbàsókè níwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ irúgbìn,
    àti gẹ́gẹ́ bí i gbòǹgbò tí ó jáde láti inú ìyàngbẹ ilẹ̀.
Òun kò ní ẹwà tàbí ògo láti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀,
    kò sí ohun kankan nínú àbùdá rẹ̀
    tí ó fi yẹ kí a ṣàfẹ́rí i rẹ̀.
A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
    ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí.
Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fún
    a kẹ́gàn rẹ, a kò sì bu ọlá fún un rárá.

(B)Lóòtítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ
    ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú,
síbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù,
    tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.
(C)Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa
    a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa;
ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀,
    àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.
Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ,
    ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀;
Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀
    gbogbo àìṣedéédéé wa.

(D)A jẹ ẹ́ ní yà, a sì pọ́n ọn lójú,
    síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀;
a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà,
    àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,
    síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.
Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ,
    ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀?
Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè;
    nítorí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú.
(E)A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà,
    àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan,
    tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀.

10 Síbẹ̀, ó wu Olúwa láti pa á lára
    àti láti mú kí ó jìyà,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fi ayé rẹ̀
    fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,
Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé
    rẹ̀ yóò pẹ́ títí,
    àti ète Olúwa ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀.
11 Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀,
    òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn;
nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre,
    Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.
12 (F)Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá
    òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára,
nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ fún ikú,
    tí a sì kà á mọ́ àwọn alárékọjá.
Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀,
    ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárékọjá.

Heberu 10:1-4

Ìrúbọ Kristi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo fún gbogbo ènìyàn

10 Nítorí tí òfin jẹ́ òjìji àwọn ohun rere ti ń bọ̀ tí kì í ṣe àwòrán tòótọ́ fún àwọn òtítọ́ náà, wọn kò lè fi ẹbọ kan náà tí wọn ń rú nígbà gbogbo lọ́dọọdún mu àwọn tí ń wá jọ́sìn di pípé. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, a kì ìbá tí dẹ́kun àti máa rú wọn, nítorí àwọn ti ń sìn ki ìbá tí ní ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Ṣùgbọ́n nínú ẹbọ wọ̀nyí ni a ń ṣe ìrántí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọọdún. Nítorí ko ṣe é ṣe fún ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti ti ewúrẹ́ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.