Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 40:1-11

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

40 Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa;
    ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.
Ó fà mí yọ gòkè
    láti inú ihò ìparun,
láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀,
    ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta,
ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà.
Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu,
    àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa.
Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù,
    wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì
    tí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn
tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga,
    tàbí àwọn tí ó yapa
lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.
Olúwa Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀
    ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.
Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;
    ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ
tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,
    wọ́n ju ohun tí
ènìyàn le è kà lọ.

(A)Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,
    ìwọ ti ṣí mi ní etí.
Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀
    ni ìwọ kò béèrè.
Nígbà náà ni mo wí pé,
    “Èmi nìyí;
nínú ìwé kíká ni
    a kọ ọ nípa tèmi wí pé.
Mo ní inú dídùn
    láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ,
ìwọ Ọlọ́run mi;
    Òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà
    láàrín àwùjọ ńlá;
wò ó,
    èmi kò pa ètè mi mọ́,
gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀,
    ìwọ Olúwa.
10 Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà sin ní àyà mi;
    èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti ìgbàlà rẹ.
Èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ mọ́
    kúrò láàrín àwọn ìjọ ńlá.

11 Ìwọ má ṣe,
    fa àánú rẹ tí ó rọ́nú
sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; Olúwa
    jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ
àti òtítọ́ rẹ
    kí ó máa pa mi mọ́
títí ayérayé.

Isaiah 22:15-25

15 Èyí ni ohun tí Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé,
    fún Ṣebna, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ rẹ̀:
16 Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín-yìí àti pé
    ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ
láti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín-yìí,
    tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gíga
    tí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta?

17 “Kíyèsára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígírí
    kí ó sì jù ọ́ nù, Ìwọ ọkùnrin alágbára.
18 Òun yóò ká ọ rúgúdù bí i òkìtì
    yóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀-èdè ńlá kan.
Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí
    àti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogun
àràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà—
    ìwọ di ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ!
19 Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ,
    a ó sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ.

20 “Ní ọjọ́ náà. Èmi yóò ké sí ọmọ ọ̀dọ̀ mi, Eliakimu ọmọ Hilkiah. 21 Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́. Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jerusalẹmu àti fún ilé e Juda. 22 (A)Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé e Dafidi lé e ní èjìká; ohunkóhun tí ó bá ṣí, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ti, ohunkóhun tí ó bá sì tì, ẹnikẹ́ni kì yóò le è ṣí. 23 Èmi yóò sì kàn mọ́lẹ̀ bí èèkàn tí ó dúró gírígírí ní ààyè e rẹ̀; òun yóò sì jẹ́ ibùjókòó ọlá fún ilé baba rẹ̀. 24 Gbogbo ògo ìdílé rẹ̀ ni wọn yóò sì fi kọ ní ọrùn: ìran rẹ̀ àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀, gbogbo ohun èlò ife, títí dé orí ago ọtí.

25 “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gírígírí ní ààyè e rẹ̀ yóò yẹrí, yóò dẹ̀gbẹ́ yóò sì fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ àti ẹrù tí ó létéńté lórí i rẹ̀ ni a ó gé lulẹ̀.” Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

Galatia 1:6-12

Kò sí ìhìnrere mìíràn

Ó yà mi lẹ́nu pé ẹ tètè yapa kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín sínú oore-ọ̀fẹ́ Kristi, sí ìhìnrere mìíràn: Nítòótọ́, kò sí ìhìnrere mìíràn: bí ó tilẹ̀ ṣe pé àwọn kan wà, tí ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n sì ń fẹ́ yí ìhìnrere Kristi padà. (A)Ṣùgbọ́n bí ó ṣe àwa ni tàbí angẹli kan láti ọ̀run wá, ni ó bá wàásù ìhìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí a tí wàásù rẹ̀ fún yín lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé! Bí àwa ti wí ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni mo sì tún wí nísinsin yìí pé: Bí ẹnìkan bá wàásù ìhìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí ẹ̀yin tí gbà lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé!

10 (B)Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ènìyàn ni èmi ń wá ojúrere rẹ̀ ní tàbí Ọlọ́run? Tàbí ènìyàn ni èmi ń fẹ́ láti wù bí? Bí èmi bá ń fẹ́ láti wu ènìyàn, èmi kò lè jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi.

Paulu ẹni tí Ọlọ́run pè

11 (C)Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ará, pé ìhìnrere tí mo tí wàásù kì í ṣe láti ipa ènìyàn. 12 N kò gbà á lọ́wọ́ ènìyàn kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi kọ́ mi, ṣùgbọ́n mo gbà á nípa ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.