Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 148

148 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,
    Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    oòrùn àti òṣùpá
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga
    àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé
    ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá
    ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi
    àti ẹ̀yin ibú Òkun
Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín
    ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,
    ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé,
    igi eléso àti gbogbo igi kedari,
10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn
    gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:
11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo
    àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
    àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá
    ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,
    ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,
    àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Isaiah 49:13-23

13 (A)Ẹ hó fún ayọ̀, ẹyin ọ̀run;
    yọ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé;
bú sórin, ẹ̀yin òkè ńlá!
    Nítorí Olúwa tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú
yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni
    tí a ń pọ́n lójú.

14 Ṣùgbọ́n Sioni sọ pé, “Olúwa ti kọ̀ mí sílẹ̀,
    Olúwa ti gbàgbé è mi.”

15 “Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀
    kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé
    Èmi kì yóò gbàgbé rẹ!
16 Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi
    ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.
17 Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà,
    àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ.
18 Gbójú rẹ sókè kí o sì wò yíká;
    gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọ
wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
    Níwọ́n ìgbà tí mo bá wà láààyè,” ni Olúwa wí,
“Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́;
    ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó.

19 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí run ọ́, a sì sọ ọ́ di ahoro
    tí gbogbo ilẹ̀ rẹ sì di ìparun,
ní ìsinsin yìí, ìwọ yóò kéré jù fún àwọn ènìyàn rẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó jẹ ọ́ run ni yóò
    wà láti ọ̀nà jíjìn réré.
20 Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹ
    yóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ,
‘Ibi yìí ti kéré jù fún wa;
    ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.’
21 Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé,
    ‘ta ló bí àwọn yìí fún mi?
Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn;
    A sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀.
Ta ló wo àwọn yìí dàgbà?
    A fi èmi nìkan sílẹ̀,
    ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá?’ ”

22 Ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nìyìí:

    “Kíyèsi i, Èmi yóò ké sí àwọn aláìkọlà
Èmi yóò gbé àsíá mi sókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn;
    Wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọn
wọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin
    ní èjìká wọn.
23 Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́ baba fún ọ,
    àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́.
Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀;
    wọn yóò máa lá erùpẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ.
Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa;
    gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mi
    ni a kì yóò jákulẹ̀.”

Matiu 18:1-14

Ẹni tí ó tóbi jù ní ìjọba Ọ̀run

18 (A)Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í léèrè pé, “Ta ni ẹni ti ó pọ̀jù ní ìjọba ọ̀run?”

Jesu sì pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Ó sì mú un dúró láàrín wọn. (B)Ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àfi bí ẹ̀yin bá yí padà kí ẹ sì dàbí àwọn ọmọdé, ẹ̀yin kì yóò lè wọ ìjọba ọ̀run. Nítorí náà, ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọdé yìí, ni yóò pọ̀ jùlọ ní ìjọba ọ̀run. (C)Àti pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọ kékeré bí èyí nítorí orúkọ mi, gbà mí.

“Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ ṣìnà, yóò sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì rì í sí ìsàlẹ̀ ibú omi Òkun. Ègbé ni fún ayé nítorí gbogbo ohun ìkọ̀sẹ̀ rẹ̀! Ohun ìkọ̀sẹ̀ kò le ṣe kó má wà, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípasẹ̀ ẹni tí ìkọ̀sẹ̀ náà ti wá! Nítorí náà, bí ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀ rẹ yóò bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀, gé e kúrò, kí o sì jù ú nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run ní akéwọ́ tàbí akésẹ̀ ju pé kí o ni ọwọ́ méjì àti ẹsẹ̀ méjì ki a sì sọ ọ́ sínú iná ayérayé. Bí ojú rẹ yóò bá sì mú kí o dẹ́ṣẹ̀, yọ ọ́ kúrò kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti lọ sínú ìyè pẹ̀lú ojú kan, ju pé kí o ní ojú méjì, kí a sì jù ọ́ sí iná ọ̀run àpáàdì.

Òwe àgùntàn tó sọnù

10 (D)“Ẹ rí i pé ẹ kò fi ojú tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn kéékèèkéé wọ̀nyí. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, nígbà gbogbo ni ọ̀run ni àwọn angẹli ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run. 11 Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn wá láti gba àwọn tí ó nù là.

12 (E)“Kí ni ẹ̀yin rò? Bí ọkùnrin kan bá ni ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ẹyọ kan nínú wọn sì sọnù, ṣé òun kì yóò fi mọ́kàn-dínlọ́gọ́rùn-ún (99) ìyókù sílẹ̀ sórí òkè láti lọ wá ẹyọ kan tó nù náà bí? 13 Ǹjẹ́ bí òun bá sì wá á rí i, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé inú rẹ̀ yóò dùn nítorí rẹ̀ ju àwọn mọ́kàn-dínlọ́gọ́rùn-ún tí kò nù lọ? 14 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ni kì í ṣe ìfẹ́ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, pé ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kí ó ṣègbé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.