Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 65:1-9

Ìdájọ́ àti ìgbàlà

65 (A)“Èmi fi ara mi hàn fún àwọn tí kò béèrè fún mi;
    Àwọn tí kò wá mi ni wọ́n rí mi.
Sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò pe orúkọ mi,
    Ni èmi wí pé, ‘Èmi nìyìí, Èmi nìyìí.’
Gbogbo ọjọ́ ni mo ti nawọ́ mi síta
    sí àwọn ènìyàn ọlọ́rùn líle,
tí wọn ń rìn lọ́nà tí kò dára,
    tí wọ́n sì gbára lé èrò ara wọn
àwọn ènìyàn tí wọ́n bí mi nínú nígbà gbogbo
    lójú ara mi gan an,
wọ́n ń rú ẹbọ nínú ọgbà
    wọ́n sì ń sun tùràrí lórí i pẹpẹ bíríkì;
wọ́n ń jókòó láàrín ibojì
    wọ́n sì ń lo òru wọn nínú ìṣọ́ ìkọ̀kọ̀;
tí wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,
    tí ìkòkò ọbẹ̀ wọn kún fún ẹran àìmọ́;
tí ó wí pé, ‘Ẹ sún mẹ́yìn; ẹ má wá sọ́dọ̀ mi,
    nítorí mo ti jẹ́ mímọ́ jù fún un yín!’
Àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èéfín nínú ihò imú mi
    iná tí ń fi gbogbo ọjọ́ jó.

“Kíyèsi i, a ti kọ ọ́ síwájú mi:
    Èmi kì yóò dákẹ́,
ṣùgbọ́n èmi yóò san án padà lẹ́kùnrẹ́rẹ́;
    Èmi yóò san án padà sí àyà wọn
àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín àti tàwọn baba yín,”
    ni Olúwa wí.
“Nítorí pé wọ́n sun ẹbọ ní orí òkè ńlá
    wọ́n sì ṣe ẹ̀gbin sí mi ní òkè kékeré,
Èmi yóò wọ́n ọ́n sí itan wọn
    ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀san ohun gbogbo tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀.”

Báyìí ni Olúwa wí:

“Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí oje sì tún wà nínú àpólà àjàrà
    tí àwọn ènìyàn sì wí pé, ‘má ṣe bà á jẹ́,
nítorí ìbùkún ń bẹ nínú rẹ̀,’
    bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe nítorí ìránṣẹ́ mi;
    Èmi kì yóò pa gbogbo wọn run.
Èmi yóò mú ìrandíran wá láti ìdílé Jakọbu,
    àti láti Juda àwọn tí yóò jogún òkè ńlá mi wọ̀n-ọn-nì;
àwọn àyànfẹ́ ènìyàn mi yóò jogún wọn,
    ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ mi yóò sì gbé.

Saamu 22:19-28

19 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi;
    Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi!
20 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà,
    àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.
21 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún;
    Kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.

22 Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi;
    nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́.
23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ yìn ín!
    Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un!
    Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli!
24 Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra
    ìpọ́njú àwọn tí a ni lára;
kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi
    ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.

25 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá;
    ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀
26 tálákà yóò jẹ yóò sì yó;
    àwọn tí n wá Olúwa yóò yin
    jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!

27 Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí
    wọn yóò sì yípadà sí Olúwa,
àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè
    ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀,
28 Nítorí ìjọba ni ti Olúwa.
    Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.

Galatia 3:23-29

23 Ṣùgbọ́n kí ìgbàgbọ́ tó dé, a ti pa wá mọ́ lábẹ́ òfin, a sì sé wa mọ́ de ìgbàgbọ́ tí a ń bọ̀ wá fihàn. 24 Nítorí náà òfin ti jẹ́ olùtọ́jú láti mú ènìyàn wá sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́. 25 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí ìgbàgbọ́ ti dé, àwa kò sí lábẹ́ olùtọ́jú mọ́.

Ọmọ Ọlọ́run

26 Nítorí pé ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín, nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. 27 Nítorí pé iye ẹ̀yin tí a ti bamitiisi sínú Kristi ti gbé Kristi wọ̀. 28 (A)Kò le sí Júù tàbí Giriki, ẹrú tàbí òmìnira, ọkùnrin tàbí obìnrin nítorí pé ọ̀kan ni nínú Kristi Jesu. 29 Bí ẹ̀yin bá sì jẹ́ ti Kristi, ǹjẹ́ ẹ̀yin ní irú-ọmọ Abrahamu, àti àrólé gẹ́gẹ́ bí ìlérí.

Luku 8:26-39

Jesu wo ọkùnrin ẹlẹ́mìí èṣù sàn

26 (A)Wọ́n sì gúnlẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Gadara, tí ó kọjú sí Galili. 27 Nígbà tí ó sì sọ̀kalẹ̀, ọkùnrin kan pàdé rẹ̀ lẹ́yìn ìlú náà, tí ó ti ní àwọn ẹ̀mí èṣù fún ìgbà pípẹ́, tí kì í wọ aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í jókòó ní ilé kan, bí kò ṣe ní ibojì. 28 (B)Nígbà tí ó rí Jesu, ó ké, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí lóhùn rara, pé, “Kí ni mo ní í ṣe pẹ̀lú rẹ, Jesu, ìwọ ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Èmi bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.” 29 (Nítorí tí ó ti wí fún ẹ̀mí àìmọ́ náà pé, kí ó jáde kúrò lára ọkùnrin náà. Nígbàkúgbà ni ó ń mú un: wọn a sì fi ẹ̀wọ̀n àti ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é; a sì ja gbogbo ìdè náà, ẹ̀mí èṣù náà a sì darí rẹ̀ sí ijù).

30 Jesu sì bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?”

Ó sì dáhùn pé, “Légíónì,” nítorí ẹ̀mí èṣù púpọ̀ ni ó wa nínú rẹ. 31 Wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe rán wọn lọ sínú ọ̀gbun.

32 Agbo ẹlẹ́dẹ̀ púpọ̀ sì ń bẹ níbẹ̀ tí ń jẹ lórí òkè: wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí àwọn wọ inú wọn lọ. Ó sì gba fún wọn. 33 Nígbà tí àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ sì tú ka, wọ́n sí súré rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ sì bèbè odò bọ́ sínú adágún náà, wọ́n sì rì sínú rẹ̀.

34 Nígbà tí àwọn tí n bọ́ wọn rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sá, wọ́n sì lọ, wọ́n sì ròyìn ní ìlú àti ní ilẹ̀ náà. 35 Nígbà náà ni wọ́n jáde lọ wo ohun náà tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sì tọ Jesu wá, wọ́n sì rí ọkùnrin náà, lára ẹni tí àwọn ẹ̀mí èṣù ti jáde lọ, ó jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó wọ aṣọ, iyè rẹ̀ sì bọ́ sí ipò: ẹ̀rù sì bà wọ́n. 36 Àwọn tí ó rí i ròyìn fún wọn bí ó ti ṣe mú ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù náà láradá. 37 Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn láti ilẹ̀ Gadara yíká bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn; nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Ó sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, ó si kúrò.

38 Ǹjẹ́ ọkùnrin náà tí ẹ̀mí èṣù jáde kúrò lára rẹ̀, bẹ̀ ẹ́ kí òun lè máa bá a gbé: ṣùgbọ́n Jesu rán an lọ, wí pé, 39 “Padà lọ sí ilé rẹ, kí o sì sọ ohun tí Ọlọ́run ṣe fún ọ bí ó ti pọ̀ tó.” Ó sì lọ, o sì ń ròyìn ka gbogbo ìlú náà bí Jesu ti ṣe ohun ńlá fún òun tó.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.