Revised Common Lectionary (Complementary)
169 Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, Olúwa;
fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
170 Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ;
gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
171 Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde,
nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
172 Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ,
nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.
173 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́,
nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ.
174 Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, Olúwa,
àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi.
175 Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́,
kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró.
176 Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó
sọnù, wá ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.
12 Nígbà tí Olúwa ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Sioni àti Jerusalẹmu, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Asiria nítorí gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojú rẹ̀. 13 Nítorí ó sọ pé:
“ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ mi ni mo fi ṣe èyí
àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye.
Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀-èdè kúrò,
Mo sì ti kó ìṣúra wọn.
Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.
14 Bí ènìyàn ti í tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ,
bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.
Bí ènìyàn ti í kó ẹyin tí a kọ̀sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀-èdè
kò sí èyí tí ó fi apá lu apá,
tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”
15 Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í,
tàbí kí ayùn fọ́nnu sí ẹni tí ó ń lò ó?
Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè,
tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.
16 Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
yóò rán ààrùn ìrẹ̀dànù sórí
àwọn akíkanjú jagunjagun,
lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ
gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.
17 Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóò di iná,
Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀wọ́-iná,
ní ọjọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run
àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n.
18 Gbogbo ẹwà igbó o rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràá
gbogbo rẹ̀ ni yóò run pátápátá,
gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ṣàìsàn ti í ṣòfò dànù.
19 Àwọn igi tí yóò kù nínú igbó o rẹ̀
yóò kéré níye,
tí ọ̀dọ́mọdé yóò fi le kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
Àwọn ìyókù Israẹli
20 Ní ọjọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli,
Àwọn tí ó yè ní ilé e Jakọbu,
kò ní gbẹ́kẹ̀lé ẹni náà
tí ó lù wọ́n bolẹ̀,
ṣùgbọ́n ní òtítọ́ yóò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa
Ẹni Mímọ́ Israẹli.
Ṣé Jesu ni Kristi?
25 Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn ará Jerusalẹmu wí pé, “ẹni tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa kọ́ yìí? 26 Sì wò ó, ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kò sì wí nǹkan kan sí i. Àwọn olórí ha mọ̀ nítòótọ́ pé, èyí ni Kristi náà? 27 (A)Ṣùgbọ́n àwa mọ ibi tí ọkùnrin yí gbé ti wá: ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi bá dé, kò sí ẹni tí yóò mọ ibi tí ó gbé ti wá.”
28 (B)Nígbà náà ni Jesu kígbe ní tẹmpili bí ó ti ń kọ́ni, wí pé, “Ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá: èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀. 29 (C)Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó rán mi.”
30 (D)Nítorí náà wọ́n ń wá ọ̀nà à ti mú un: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e, nítorí tí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé. 31 (E)Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn sì gbà á gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Nígbà tí Kristi náà bá dé, yóò ha ṣe iṣẹ́ ààmì jù wọ̀nyí, tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ?”
32 Àwọn Farisi gbọ́ pé, ìjọ ènìyàn ń sọ nǹkan wọ̀nyí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀; àwọn Farisi àti àwọn olórí àlùfáà sì rán àwọn oníṣẹ́ lọ láti mú un.
33 (F)Nítorí náà Jesu wí fún wọn pé, “Níwọ́n ìgbà díẹ̀ ni èmi yóò wà pẹ̀lú yín, èmi yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó rán mi. 34 Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti ibi tí èmi bá wà, ẹ̀yin kì yóò le wà.”
35 (G)Nítorí náà ni àwọn Júù ń bá ara wọn sọ pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí yóò gbé lọ tí àwa kì yóò fi rí i? Yóò ha lọ sí àárín àwọn Helleni tí wọ́n fọ́n káàkiri, kí ó sì máa kọ́ àwọn Helleni bí. 36 Ọ̀rọ̀ kín ni èyí tí ó sọ yìí, ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi, àti ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà?”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.