Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu.
81 Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa
Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!
2 Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá,
tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.
3 Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun
àní nígbà tí a yàn;
ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.
4 Èyí ni àṣẹ fún Israẹli,
àti òfin Ọlọ́run Jakọbu.
5 Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu
nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já.
Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.
6 Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín,
a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.
7 Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,
mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá,
mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela.
8 “Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,
bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli.
9 Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín;
ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.
10 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.
Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.
Ọdún àwọn ọmọ Israẹli
23 (A)Olúwa sọ fún Mose wí pé, 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn àjọ̀dún tí a yàn, àwọn àjọ̀dún ti Olúwa èyí tí ẹ gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí àjọ̀dún tí a yàn.
Ọjọ́ ìsinmi
3 “ ‘Ọjọ́ mẹ́fà ni ẹ le fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi. Ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. Ọjọ́ ìsinmi Olúwa ni.
Ọdún ìrékọjá àti àkàrà aláìwú
4 “ ‘Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọdún tí Olúwa yàn, àjọ̀dún tí a yàn tí ẹ gbọdọ̀ kéde lákokò wọn. 5 Àjọ ìrékọjá Olúwa bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní (Epiri). 6 Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kìn-ín-ní, ni àjọ̀dún àkàrà àìwú (àkàrà tí kò ní ìwúkàrà) tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ fún ọjọ́ méje ni ẹ gbọdọ̀ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. 7 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; ẹ́yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan nínú rẹ̀. 8 Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa. Ní ọjọ́ keje, ẹ pe ìpàdé àjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.’ ”
Jíju aṣẹ́gun lọ
31 (A)Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa? 32 (B)Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti fi Ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le ṣòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí? 33 (C)Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀. Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dáríjì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀. 34 (D)Ta ni ẹni náà tí yóò dá wa lẹ́bi? Kò sí. Kristi Jesu tí ó kú, kí a sá à kúkú wí pé tí a ti jí dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí ó sì wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, tó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa? 35 Ta ni yóò ha yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni, tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ìyàn, tàbí ìhòhò, tàbí ewu tàbí idà? 36 (E)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Nítorí rẹ̀ ni a ṣe ń pa wá kú ní gbogbo ọjọ́;
À ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.”
37 (F)Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ju ẹni tí ó ṣẹ́gun lọ nípasẹ̀ Kristi ẹni tí ó fẹ́ wa. 38 Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kì í ṣe ikú tàbí ìyè, kì í ṣe àwọn angẹli tàbí ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe ohun ìgbà ìsinsin yìí tàbí ohun tí ó ń bọ̀, tàbí àwọn agbára, 39 tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.