Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
40 Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa;
ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.
2 Ó fà mí yọ gòkè
láti inú ihò ìparun,
láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀,
ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta,
ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà.
3 Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu,
àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa.
Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù,
wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
4 Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì
tí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn
tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga,
tàbí àwọn tí ó yapa
lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.
5 Olúwa Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀
ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.
Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;
ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ
tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,
wọ́n ju ohun tí
ènìyàn le è kà lọ.
6 (A)Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,
ìwọ ti ṣí mi ní etí.
Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀
ni ìwọ kò béèrè.
7 Nígbà náà ni mo wí pé,
“Èmi nìyí;
nínú ìwé kíká ni
a kọ ọ nípa tèmi wí pé.
8 Mo ní inú dídùn
láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ,
ìwọ Ọlọ́run mi;
Òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”
Ìwòsàn ń bẹ fún àwọn tó ronúpìwàdà
14 Yípadà ìwọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ló fa ìparun rẹ!
2 (A)Ẹ gba ọ̀rọ̀ Olúwa gbọ́,
kí ẹ sì yípadà sí Olúwa.
Ẹ sọ fún un pé:
“Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá
kí o sì fi oore-ọ̀fẹ́ gbà wá,
kí àwa kí ó lè fi ètè wa sán an fún ọ
3 Asiria kò le gbà wá là;
A kò ní í gorí ẹṣin ogun
A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé
‘Àwọn ni òrìṣà wa
sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe;
nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn
aláìní baba tí ń rí àánú.’
4 “Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn,
Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́,
nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.
5 Èmi o dàbí ìrì sí Israẹli
wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì
Bi kedari ti Lebanoni yóò si ta gbòǹgbò
6 Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà,
Dídán ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi olifi
Òórùn rẹ yóò sì dàbí igi kedari ti Lebanoni.
7 Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀.
Yóò rúwé bi ọkà.
Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà,
òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lebanoni.
8 Ìwọ Efraimu; Kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà?
Èmi ó dá a lóhùn, èmi ó sì ṣe ìtọ́jú rẹ.
Mo dàbí igi junifa tó ń fi gbogbo ìgbà tutù,
èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.”
9 (B)Ta ni ọlọ́gbọ́n? Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyí
Ta a ní ó mọ̀? Òun yóò ní ìmọ̀ wọn.
Títọ́ ni ọ̀nà Olúwa
àwọn olódodo si ń rìn nínú wọn
Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ni yóò kọsẹ̀ nínú wọn.
Olúwa ọjọ́ ìsinmi
12 (A)(B) Ní àkókò náà ni Jesu ń la àárín oko ọkà kan lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ebi sì ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i ya orí ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́. 2 Nígbà tí àwọn Farisi rí èyí. Wọ́n wí fún pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi.”
3 (C)Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò ha ka ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa á àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. 4 Ó wọ inú ilé Ọlọ́run, òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àkàrà tí a yà sọ́tọ̀, èyí tí kò yẹ fún wọn láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan. 5 Tàbí ẹ̀yin kò ti kà á nínú òfin pé ní ọjọ́ ìsinmi, àwọn àlùfáà tí ó wà ní tẹmpili ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ tí wọ́n sì wà láìjẹ̀bi. 6 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, ẹni tí ó pọ̀ ju tẹmpili lọ wà níhìn-ín. 7 Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí, ‘Àánú ni èmi ń fẹ́ kì í ṣe ẹbọ,’ ẹ̀yin kì bá tí dá aláìlẹ́ṣẹ̀ lẹ́bi. 8 Nítorí pé Ọmọ Ènìyàn jẹ́ Olúwa ọjọ́ ìsinmi.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.