Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 40:1-8

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

40 Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa;
    ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.
Ó fà mí yọ gòkè
    láti inú ihò ìparun,
láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀,
    ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta,
ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà.
Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu,
    àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa.
Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù,
    wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì
    tí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn
tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga,
    tàbí àwọn tí ó yapa
lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.
Olúwa Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀
    ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.
Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;
    ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ
tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,
    wọ́n ju ohun tí
ènìyàn le è kà lọ.

(A)Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,
    ìwọ ti ṣí mi ní etí.
Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀
    ni ìwọ kò béèrè.
Nígbà náà ni mo wí pé,
    “Èmi nìyí;
nínú ìwé kíká ni
    a kọ ọ nípa tèmi wí pé.
Mo ní inú dídùn
    láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ,
ìwọ Ọlọ́run mi;
    Òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

Hosea 8:11-14

11 “Nítorí Efraimu ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀
    gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un
12 Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn.
    Ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì
13 Wọ́n ń rú ẹbọ tí wọ́n yàn fún mi,
    wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀
    Ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn.
Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọn
    yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
    Wọn yóò padà sí Ejibiti
14 (A)Nítorí Israẹli ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀
    Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀
    Juda ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀
ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kan
    sí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run.”

Hosea 10:1-2

10 Israẹli jẹ́ igi àjàrà tó gbilẹ̀
    ó ń so èso fún ara rẹ̀
Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀
    bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí i
bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rere
    o bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀.
Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹ
    báyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn.
Olúwa yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀
    yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run.

Heberu 13:1-16

Ìparí àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú náà

13 Kí ìfẹ́ ará kí o wà títí. (A)Ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣe àlejò; nítorí pé nípa bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn ṣe àwọn angẹli ní àlejò láìmọ̀. Ẹ máa rántí àwọn òǹdè bí ẹni tí a dè pẹ̀lú wọn, àti àwọn tí a ń pọn lójú bí ẹ̀yin tìkára yín pẹ̀lú tí ń bẹ nínú ara.

Kí ìgbéyàwó lọ́lá láàrín gbogbo ènìyàn, kí àkéte si jẹ́ aláìléèérí: Nítorí àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà ni Ọlọ́run yóò dá lẹ́jọ́. (B)Kí ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin; nítorí òun tìkára rẹ̀ ti wí pé,

“Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”

(C)Nítorí náà ni àwa ṣe ń fi ìgboyà wí pé,

“Olúwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, èmi kì yóò bẹ̀rù;
    kín ni ènìyàn lè ṣe sí mi?”

Ẹ máa rántí àwọn tiwọn jẹ́ aṣáájú yín, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín; kí ẹ máa ro òpin ìwà ayé wọn, kí ẹ sì máa ṣe àfarawé ìgbàgbọ́ wọn. Jesu Kristi ọ̀kan náà ni lánàá, àti lónìí, àti títí láé.

Ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbá yin kiri. Nítorí ó dára kí a mú yin lọ́kàn le nípa oore-ọ̀fẹ́, kì í ṣe nípa oúnjẹ nínú èyí tí àwọn tí ó ti rìn nínú wọn kò ní èrè. 10 Àwa ní pẹpẹ kan, níbi èyí tí àwọn ti ń sin àgọ́ kò ni agbára láti máa jẹ.

11 (D)Nítorí nígbà tí olórí àlùfáà bá mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹran wá si ibi mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀, òkú àwọn ẹran náà ni a o sun lẹ́yìn ibùdó. 12 Nítorí náà Jesu pẹ̀lú, kí ó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn ènìyàn di mímọ́, ó jìyà lẹ́yìn ibodè. 13 Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a jáde tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí a máa ru ẹ̀gàn rẹ̀. 14 Nítorí pé àwa kò ní ìlú tí o wa títí níhìn-ín, ṣùgbọ́n àwa ń wá èyí tí ń bọ.

15 (E)Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀. 16 Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín fun ni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.