Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 24

Ti Dafidi. Saamu.

24 (A)Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀,
    ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;
Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí Òkun
    ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.

Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ?
    Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?
(B)Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,
    ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán
    tí kò sì búra èké.

Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,
    àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.
Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀,
    tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.

Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà;
    Kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé!
    Kí ọba ògo le è wọlé.
Ta ni ọba ògo náà?
    Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le,
    Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.
Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà;
    kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,
    kí Ọba ògo le è wọlé wá.
10 Ta ni Ọba ògo náà?
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    Òun ni Ọba ògo náà. Sela.

Isaiah 33:17-22

17 Ojú rẹ yóò rí ọba nínú ẹwà rẹ̀
    yóò sì rí ilẹ̀ kan tí ó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ.
18 Nínú èrò rẹ ìwọ yóò rántí ẹ̀rù rẹ àtẹ̀yìnwá:
    “Níbo ni ọ̀gá àgbà náà wà?
Níbo ni ẹni tí ń gba owó òde wà?
    Níbo ni òṣìṣẹ́ ti ó ń mójútó ilé ìṣọ́ wà?”
19 Ìwọ kì yóò rí àwọn agbéraga ènìyàn mọ́,
    àwọn ènìyàn tí èdè wọn fi ara sin,
    pẹ̀lú ahọ́n tí ó ṣàjèjì tí kò sì yé ni.

20 Gbójú sókè sí Sioni, ìlú àjọ̀dún wa,
    ojú rẹ yóò rí Jerusalẹmu,
ibùgbé àlàáfíà n nì, àgọ́ tí a kò ní yí padà;
    àwọn òpó rẹ̀ ni a kì yóò fàtu
    tàbí èyíkéyìí nínú okùn rẹ̀ kí já.
21 Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti jẹ́ Alágbára kan fún wa.
    Yóò sì dàbí ibi àwọn odò ńláńlá àti odò kéékèèkéé.
Kì yóò sí ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú tí yóò kọjá lórí i wọn,
    ọkọ̀ ojú omi ńlá ni a kì yóò tù lórí wọn.
22 Nítorí Olúwa ni onídàájọ́ wa,
    Olúwa ni onídàájọ́ wa,
Olúwa òun ni ọba wa;
    òun ni ẹni tí yóò gbà wá là.

Ìfihàn 22:8-21

Èmi, Johanu, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ angẹli náà, tí o fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi, Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Wó ò, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ wòlíì, àti ti àwọn tí ń pa ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí mọ́: foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run!”

10 Ó sì wí fún mi pé, “má ṣe fi èdìdì di ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí inú ìwé yìí: nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀. 11 (A)Ẹni tí ń ṣe aláìṣòótọ́, kí ó máa ṣe aláìṣòótọ́ nì só: àti ẹni tí ń ṣe ẹlẹ́gbin, kí ó máa ṣe ẹ̀gbin nì só: àti ẹni tí ń ṣe olódodo, kí ó máa ṣe òdodo nì só: Àti ẹni tí ń ṣe mímọ́, kí ó máa ṣe mímọ́ nì só.”

12 (B)“Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán; èrè mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi, láti sán fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ yóò tí rí. 13 (C)Èmi ni Alfa àti Omega, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin.

14 “Ìbùkún ni fún àwọn ti ń fọ aṣọ wọn, kí wọ́n lè ni ẹ̀tọ́ láti wá sí ibi igi ìyè náà, àti kí wọ́n lè gbà àwọn ẹnu ibodè wọ inú ìlú náà. 15 Nítorí ni òde ni àwọn ajá gbé wà, àti àwọn oṣó, àti àwọn àgbèrè, àti àwọn apànìyàn, àti àwọn abọ̀rìṣà, àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn èké tí ó sì ń hùwà èké.

16 “Èmi, Jesu, ni ó rán angẹli mi láti jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí fún yin ní tí àwọn ìjọ. Èmi ni gbòǹgbò àti irú-ọmọ Dafidi, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tí ń tàn.”

17 (D)Ẹ̀mí àti ìyàwó wí pé, “Máa bọ!” Àti ẹni tí ó ń gbọ́ kí ó wí pé, “Máa bọ̀!” Àti ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ kí ó wá, àti ẹni tí o bá sì fẹ́, kí ó gba omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́.

18 Èmi kìlọ̀ fún olúkúlùkù ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí pé, bí ẹnikẹ́ni ba fi kún wọn, Ọlọ́run yóò fi kún àwọn ìyọnu tí a kọ sínú ìwé yìí fún un. 19 Bí ẹnikẹ́ni bá sì mú kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìwé ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ́run yóò sì mú ipa tirẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, àti kúrò nínú ìlú mímọ́ náà, àti kúrò nínú àwọn ohun tí a kọ sínú ìwé yìí.

20 Ẹni tí ó jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí wí pé, “Nítòótọ́ èmi ń bọ̀ kánkán.”

Àmín, Máa bọ̀, Jesu Olúwa!

21 (E)Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. Àmín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.