Revised Common Lectionary (Complementary)
19 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi;
Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi!
20 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà,
àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.
21 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún;
Kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.
22 Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi;
nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́.
23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ yìn ín!
Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un!
Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli!
24 Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra
ìpọ́njú àwọn tí a ni lára;
kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi
ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.
25 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá;
ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀
26 tálákà yóò jẹ yóò sì yó;
àwọn tí n wá Olúwa yóò yin
jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!
27 Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí
wọn yóò sì yípadà sí Olúwa,
àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè
ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀,
28 Nítorí ìjọba ni ti Olúwa.
Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.
57 Olódodo ṣègbé
kò sí ẹnìkan tí ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀;
a mú àwọn ẹni mímọ́ lọ,
kò sì ṣí ẹni tó yé
pé a ti mú àwọn olódodo lọ
láti yọ wọ́n kúrò nínú ibi.
2 Gbogbo àwọn tí ń rìn déédé
ń wọ inú àlàáfíà;
wọ́n rí ìsinmi bí wọ́n ti ń sùn nínú ikú.
3 “Ṣùgbọ́n ẹ súnmọ́ ìhìn-ín, ẹ̀yin ọmọ aláfọ̀ṣẹ,
ẹ̀yin irú-ọmọ panṣágà àti àgbèrè!
4 Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà?
Ta ni o ń yọ ṣùtì sí
tí o sì yọ ahọ́n síta?
Ẹ̀yin kì í ha ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí,
àti ìran àwọn òpùrọ́?
5 Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrín igi óákù
àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀;
ẹ fi àwọn ọmọ yín rú ẹbọ nínú kòtò jíjìn
àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta.
6 Àwọn ère tí ó wà ní àárín òkúta dídán
wọ́n n nì, nínú kòtò jíjìn ni ìpín in yín;
àwọ̀n ni ìpín in yín.
Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀
àti láti ta ọrẹ ìyẹ̀fun.
Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ
kí n dáwọ́ dúró?
7 Ìwọ ti ṣe ibùsùn rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà;
níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.
8 Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yín
níbẹ̀ ni ẹ fi àwọn ààmì òrìṣà yín sí.
Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ ṣí ibùsùn yín sílẹ̀,
ẹ gun orí rẹ̀ lọ, ẹ sì ṣí i sílẹ̀ gbagada;
ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn ibùsùn wọn,
ẹ̀yin sì ń wo ìhòhò wọn.
9 Ẹ̀yin lọ sí Moleki pẹ̀lú òróró olifi
ẹ sì fi kún òórùn dídùn yín.
Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré;
ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!
10 Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ ba á yín,
ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘kò sí ìrètí mọ́?’
Ẹ rí okun kún agbára yín,
nípa bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ ọ yín.
11 “Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rù
tí ẹ fi ń ṣèké sí mi,
àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mi
tàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín?
Ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí dídákẹ́ jẹ́ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́
tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?
12 Èmi yóò ṣí òdodo yín páyà àti iṣẹ́ yín,
wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.
13 Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́
ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín!
Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ,
èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ.
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀
ni yóò jogún ilẹ̀ náà
yóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”
Òfin àti ìlérí
15 Ará, èmi ń sọ̀rọ̀ bí ènìyàn, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ènìyàn ti a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò sí ẹni tí ó lè sọ ọ́ di asán, tàbí tí ó lè fi kún un mọ́. 16 (A)Ǹjẹ́ fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀ ni a ti ṣe àwọn ìlérí náà. Ìwé Mímọ́ kò ṣe wí pé, Fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀, bí ẹni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀; ṣùgbọ́n bí ẹni pé ọ̀kan ṣoṣo, àti fún irú-ọmọ rẹ̀, èyí tí í ṣe Kristi. 17 (B)Èyí tí mò ń wí ni pé: májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níṣàájú, òfin ti ó dé lẹ́yìn ọgbọ̀n-lé-nírinwó ọdún kò lè sọ ọ́ di asán, kí ó sì mú ìlérí náà di aláìlágbára. 18 (C)Nítorí bí ogún náà bá dúró lórí ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí í òfin kì í ṣe ti ìlérí mọ́: ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í fún Abrahamu nípa ìlérí.
19 (D)Ǹjẹ́ kí ha ni òfin? A fi kún un nítorí ìrékọjá títí irú-ọmọ tí a ti ṣe ìlérí fún yóò fi dé; a sì tipasẹ̀ àwọn angẹli ṣe ìlànà rẹ̀ láti ọwọ́ alárinà kan wá. 20 Ǹjẹ́ onílàjà kì í ṣe alárinà ti ẹnìkan, ṣùgbọ́n ọ̀kan ni Ọlọ́run.
21 (E)Nítorí náà òfin ha lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run bí? Kí a má rí i; Nítorí ìbá ṣe pé a ti fi òfin kan fún ni tí ó lágbára láti sọ ni di ààyè nítòótọ́ òdodo ìbá ti tipasẹ̀ òfin wà. 22 (F)Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ ti fi yé wa pé gbogbo ènìyàn ni ń bẹ lábẹ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀, kí a lè fi ìlérí nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi fún àwọn tí ó gbàgbọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.