Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 6

Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin olókùn. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.

Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ
    kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ
Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń kú lọ;
    Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.
Ọkàn mi wà nínú ìrora.
    Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó?

Yípadà, Olúwa, kí o sì gbà mí;
    gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í.
Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú.
    Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú?

Agara ìkérora mi dá mi tán.

Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún,
    mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.
Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́;
    wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.

(A)Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,
    nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.
Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú;
    Olúwa ti gba àdúrà mi.
10 Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú;
    wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.

Jobu 30:16-31

16 “Àti nísinsin yìí, ayé mi n yòrò lọ díẹ̀díẹ̀;
    ọjọ́ ìpọ́njú mi dì mímú.
17 Òru gún mi nínú egungun mi,
    èyí tí ó bù mí jẹ kò sì sinmi.
18 Nípa agbára ńlá rẹ̀ Ọlọ́run wà bí aṣọ ìbora fún mi,
    ó sì lẹ̀ mọ́ mi ní ara yíká bí aṣọ ìlekè mi.
19 Ọlọ́run ti mú mi lọ sínú ẹrẹ̀,
    èmi sì dàbí eruku àti eérú.

20 “Èmi ké pè ọ́ ìwọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi lóhùn;
    èmi dìde dúró ìwọ sì wò mí lásán.
21 Ìwọ padà di ẹni ìkà sí mi; ọwọ́
    agbára rẹ ni ìwọ fi dè mí ní ọ̀nà.
22 Ìwọ gbé mi sókè sí inú ẹ̀fúùfù, ìwọ mú mi fò lọ,
    bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì sọ mí di asán pátápátá.
23 Èmi sá à mọ̀ pé ìwọ yóò mú mi lọ sínú ikú,
    sí ilé ìpéjọ tí a yàn fún gbogbo alààyè.

24 “Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan kí yóò ha nawọ́ rẹ̀ nígbà ìṣubú rẹ̀,
    tàbí kì yóò ké nínú ìparun rẹ̀.
25 Èmi kò ha sọkún bí fún ẹni tí ó wà nínú ìṣòro?
    Ọkàn mi kò ha bàjẹ́ fún tálákà bí?
26 Nígbà tí mo fojú ṣọ́nà fún àlàáfíà, ibi sì dé;
    nígbà tí mo dúró de ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn sì dé.
27 Ikùn mí n ru kò sì sinmi;
    Ọjọ́ ìpọ́njú ti dé bá mi.
28 Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú oòrùn;
    èmi dìde dúró ní àwùjọ mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́.
29 Èmi ti di arákùnrin ìkookò,
    èmi di ẹgbẹ́ àwọn ògòǹgò.
30 Àwọ̀ mi di dúdú ní ara mi;
    egungun mi sì jórun fún ooru.
31 Ohun èlò orin mi pẹ̀lú sì di ti ọ̀fọ̀,
    àti ìpè orin mi sì di ohùn àwọn tí ń sọkún.

Johanu 4:46-54

46 (A)Bẹ́ẹ̀ ni Jesu tún wá sí Kana ti Galili, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì. Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kapernaumu. 47 Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti Judea wá sí Galili, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá: nítorí tí ó wà ní ojú ikú.

48 (B)Nígbà náà ni Jesu wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá rí ààmì àti iṣẹ́ ìyanu, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́ láé.”

49 Ọkùnrin ọlọ́lá náà wí fún un pé, “Olúwa, sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ mi tó kú.”

50 Jesu wí fún un pé, “Máa bá ọ̀nà rẹ lọ; ọmọ rẹ yóò yè.”

Ọkùnrin náà sì gba ọ̀rọ̀ Jesu gbọ́, ó sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 51 Bí ó sì ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pàdé rẹ̀, wọ́n sì wí fún un pé, ọmọ rẹ ti yè. 52 Nígbà náà ni ó béèrè wákàtí tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ní àná, ní wákàtí keje ni ibà náà fi í sílẹ̀.”

53 (C)Bẹ́ẹ̀ ni baba náà mọ̀ pé ní wákàtí kan náà ni, nínú èyí tí Jesu wí fún un pé “Ọmọ rẹ̀ yè.” Òun tìkára rẹ̀ sì gbàgbọ́, àti gbogbo ilé rẹ̀.

54 (D)Èyí ni iṣẹ́ ààmì kejì tí Jesu ṣe nígbà tí ó ti Judea jáde wá sí Galili.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.