Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Numeri 5-6

Wíwà ní mímọ́ ibùdó

Olúwa sọ fún Mose pé: (A)“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn ó lé ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀tẹ̀, ìtújáde ara ní oríṣìíríṣìí tàbí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífọwọ́ kan òkú. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó kí wọn má ba à ba ibùdó wọn jẹ́ níbi tí èmi ń gbé láàrín wọn” Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀; wọ́n lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó. Wọn ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mose.

Ìjẹ́wọ́ àti àtúnṣe

(B)Olúwa sọ fún Mose pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: ‘Nígbà tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan bá ṣẹ̀ ara wọn lọ́nà kan tàbí òmíràn, tí wọ́n sì ṣe àìṣòótọ́ sí Olúwa, ẹni náà jẹ̀bi. Ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. Ó gbọdọ̀ san ẹ̀san rẹ̀ ní ojú owó, kí ó sì fi ìdámárùn-ún rẹ̀ lé e, kí ó sì fi fún ẹni tí Òun jẹ̀bi rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ìbátan tí ó súnmọ́ ọn tí ó lè ṣe àtúnṣe àṣìṣe rẹ̀ náà fún, àtúnṣe náà jẹ́ ti Olúwa, ẹ sì gbọdọ̀ ko fún àlùfáà pẹ̀lú àgbò tí a fi ṣe ètùtù fún ẹni náà Gbogbo ọrẹ ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún àlùfáà jẹ́ tirẹ̀. 10 Ọrẹ ohun mímọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ ti òun nìkan Ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá fún àlùfáà yóò jẹ́ ti àlùfáà.’ ”

Àyẹ̀wò fún aláìṣòótọ́ ìyàwó

11 Olúwa sọ fún Mose wí pé, 12 “Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀ kí o sọ fún wọn pé: ‘Bí ìyàwó ọkùnrin kan bá yapa tó sì ṣe àìṣòótọ́ sí i, 13 Nípa mímú kí ọkùnrin mìíràn bá a lòpọ̀ tí ó sì fi èyí pamọ́ fún ọkọ rẹ̀, tí a kò si gbá a mú nínú ìwà àìmọ́ rẹ̀ (nítorí pé kò sí ẹlẹ́rìí àti pé wọn kò ká a mọ́ nígbà tí ó ń dẹ́ṣẹ̀ náà). 14 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkọ rẹ̀ dé bi pé ó ń funra sí ìyàwó rẹ̀ yìí tí ìyàwó rẹ̀ sì wà ní àìmọ́ nítòótọ́, tàbí tí ẹ̀mí owú bá bà lé ọkùnrin kan tó sì ń jowú ìyàwó rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà ní mímọ́, 15 nígbà náà ni ọkùnrin yìí yóò mú ìyàwó rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àlùfáà. Ọkùnrin náà yóò sì mú ọrẹ tí a yàn fún obìnrin náà, ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n efa ìyẹ̀fun barle. Kò gbọdọ̀ da òróró sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fi tùràrí dídùn sí i nítorí pé ẹbọ ohun jíjẹ fún owú ni, èyí ti n mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí.

16 “ ‘Àlùfáà yóò sì mú un wá síwájú Olúwa. 17 Àlùfáà yóò sì bu erùpẹ̀ ilẹ̀ àgọ́ sínú omi mímọ́ tó bù láti ìkòkò amọ̀, 18 Lẹ́yìn èyí, àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì tú irun orí obìnrin náà lé e lọ́wọ́, èyí ni ẹbọ ohun jíjẹ ti owú, àlùfáà fúnrarẹ̀ yóò sì gbé omi kíkorò tí ń mú ègún lọ́wọ́. 19 Àlùfáà yóò sì mú obìnrin náà búra, yóò wí pé, “Bí ọkùnrin mìíràn kò bá bá ọ lòpọ̀, tí ó kò sì yapa, tí o kò sì di aláìmọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ọkọ rẹ̀, a jẹ́ pé omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí kò ní ṣe ọ́ níbi. 20 Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá ti yapa kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ, tí o bá ti ba ara rẹ jẹ́ nípa jíjẹ́ kí ọkùnrin tí kì í ṣe ọkọ rẹ bá ọ lòpọ̀,” 21 nígbà náà ni àlùfáà yóò mú obìnrin náà búra, yóò sọ fún obìnrin náà pé: “Kí Olúwa sọ ọ́ di ẹni ègún àti ẹni ìbáwí láàrín àwọn ènìyàn rẹ nípa mímú kí itan rẹ jẹrà, kí ikùn rẹ̀ sì wú. 22 Ǹjẹ́ kí omi yìí tí ń mú ègún wá wọ inú ara rẹ, kí ó mú ikùn rẹ̀ wú, kí ó sì mú itan rẹ̀ jẹrà dànù.”

“ ‘Obìnrin náà yóò sì wí pé, “Àmín. Bẹ́ẹ̀ ni kó rí.”

23 “ ‘Nígbà náà ni àlùfáà yóò kọ ègún yìí sínú ìwé kíká, yóò sì sìn ín sínú omi kíkorò náà. 24 Àlùfáà yóò sì mú kí obìnrin náà mu omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí, omi náà yóò wọ inú rẹ̀ yóò sì fa ìrora kíkorò fún obìnrin náà bí ó bá jẹ̀bi. 25 Àlùfáà yóò gba ọrẹ ohun jíjẹ owú náà lọ́wọ́ rẹ̀, yóò fì í síwájú Olúwa, yóò sì mú iná sórí pẹpẹ. 26 Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ọrẹ ohun jíjẹ nàà, yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lẹ́yìn tí ó ti mú kí obìnrin náà mu omi. 27 Bí ó bá ti mú obìnrin yìí mu omi náà, bí ó bá sì jẹ́ pé obìnrin náà ti ba ara rẹ̀ jẹ́, tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí ọkọ rẹ̀, omi tí ń mú ègún wá, yóò wọ ara rẹ̀, yóò fa ìrora kíkorò fún un, ikùn rẹ̀ yóò wú, itan rẹ̀ yóò sì jẹrà dànù, yóò sì di ẹni ègún láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 28 Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé obìnrin náà kò ba ara rẹ̀ jẹ́, tó sì jẹ́ mímọ́, yóò bọ́ nínú ẹ̀bi, yóò sì le bímọ.

29 “ ‘Èyí ni òfin owú jíjẹ nígbà tí obìnrin tó wà lábẹ́ ọkọ bá ṣe a ṣe má ṣe, tí ó bá ba ara rẹ̀ jẹ́ 30 Tàbí nígbà tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkùnrin kan nítorí pé ó funra sí ìyàwó rẹ̀. Àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí fún un. 31 Ara ọkọ rẹ̀ mọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ṣùgbọ́n obìnrin náà yóò ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.’ ”

Òfin fún àwọn Nasiri

Olúwa sọ fún Mose pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì, ẹ̀jẹ́ ìyara-ẹni-sọ́tọ̀ sí Olúwa nípa àìgé irun orí (Nasiri): (C)Irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ yàgò fún wáìnì tàbí ọtí líle, ọtí wáìnì kíkan àti àwọn ohun mímu mìíràn tó bá kan. Kò gbọdọ̀ mu èso àjàrà tàbí kí ó jẹ èso àjàrà tútù tàbí gbígbẹ. Níwọ́n ìgbà tí ó sì jẹ́ Nasiri, ní kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi èso àjàrà ṣe, ìbá à ṣe kóró tàbí èèpo rẹ̀.

“ ‘Ní gbogbo ìgbà ẹ̀jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, kí abẹ kankan má ṣe kàn án ní orí. Ó gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ títí tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Olúwa yóò fi pé; ó gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí rẹ̀ gùn.

“ ‘Ní gbogbo àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Olúwa kò gbọdọ̀ súnmọ́ òkú ènìyàn. Ìbá à ṣe òkú baba, àti ìyá rẹ̀, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin tàbí àbúrò rẹ̀, kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí wọn, nítorí pé ààmì ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run wà ní orí rẹ̀. Ní gbogbo àsìkò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.

“ ‘Bí ẹnìkan bá kú ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òjijì, tí ó sì ba irun rẹ̀ tó yà sọ́tọ̀ jẹ́; ó gbọdọ̀ gé irun rẹ̀ ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe ọjọ́ keje. 10 Ní ọjọ́ kẹjọ, yóò mú àdàbà méjì àti ọmọ ẹyẹlé méjì wá sọ́dọ̀ àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 11 Àlùfáà yóò fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun láti fi ṣe ètùtù fún un nítorí pé ó ti ṣẹ̀ nípa wíwà níbi tí òkú ènìyàn wà. Yóò sì ya orí rẹ̀ sí mímọ́ ní ọjọ́ náà gan an. 12 Ó gbọdọ̀ ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ sí Olúwa fún àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ mú akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀bi. Kò sì ní í ka àwọn ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó tí ba ara rẹ̀ jẹ́ ní àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀.

13 (D)“ ‘Èyí ni òfin fún Nasiri nígbà tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ bá pé. Wọn ó mu wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 14 Níbẹ̀ ni yóò ti mú ọrẹ wá fún Olúwa, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun àti ẹgbọrọ-àgùntàn ọlọ́dún kan, tí kò ní àbùkù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò kan tí kò ní àbùkù fún ọrẹ àlàáfíà, 15 pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu, apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí a kò fi ìwúkàrà ṣe, àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun dáradára pò mọ́ òróró àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a fi òróró sọjọ̀ lé lórí.

16 “ ‘Àlùfáà yóò gbé gbogbo rẹ̀ wá síwájú Olúwa, yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun. 17 Àlùfáà yóò fi àgbò náà rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa, pẹ̀lú apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà; yóò rú ẹbọ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu.

18 “ ‘Nígbà náà ni Nasiri náà yóò fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Yóò fi irun náà sínú iná tó wà lábẹ́ ẹbọ àlàáfíà.

19 “ ‘Lẹ́yìn tí Nasiri bá ti fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ tan, àlùfáà yóò mú apá àgbò bíbọ̀, àkàrà aláìwú kan àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà láti inú apẹ̀rẹ̀ yóò sì kó gbogbo rẹ̀ lé e lọ́wọ́. 20 Àlùfáà yóò fi gbogbo rẹ̀ níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, wọ́n jẹ́ mímọ́, wọ́n sì jẹ́ ti àlùfáà pẹ̀lú igẹ̀ tí a fì àti itan tí wọ́n mú wá. Lẹ́yìn èyí, Nasiri náà lè mu wáìnì.

21 “ ‘Èyí ni òfin Nasiri tó jẹ́ ẹ̀jẹ́, ọrẹ rẹ̀ sí Olúwa, yóò wà ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Nasiri, ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn tó lágbára láti mú wá. Ó gbọdọ̀ mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin Nasiri.’ ”

Ìbùkún àlùfáà

22 Olúwa sọ fún Mose pé, 23 “Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Báyìí ni kí ẹ ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli. Ẹ sọ fún wọn pé:

24 “ ‘ “Kí Olúwa bùkún un yín
    Kí ó sì pa yín mọ́.
25 Olúwa kí o mú ojú rẹ̀ kí ó mọ́lẹ̀ sí i yín lára.
    Kí ó sì ṣàánú fún un yín.
26 Olúwa bojú wò yín;
    Kí ó sì fún un yín ní àlàáfíà.” ’

27 “Báyìí ni wọn ó ṣe fi orúkọ mi sára àwọn ọmọ Israẹli, Èmi ó sì bùkún wọn.”

Marku 4:1-20

Òwe afúnrúgbìn

(A)Jesu sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ́ni létí Òkun Àwọn ìjọ ènìyàn tí ó yí i ká pọ̀ jọjọ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, tí ó sì jókòó nínú rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun, nígbà tí àwọn ènìyàn sì wà ní ilẹ̀ létí Òkun. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé: “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀. Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ. Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀. Láìpẹ́ ọjọ́, ó hu jáde. Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jóná, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ. Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrín ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbàsókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúgbìn náà kò le so èso. Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, o sì so èso lọ́pọ̀lọpọ̀-òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.”

Jesu sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”

10 (B)Nígbà tí ó ku òun nìkan pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá àti àwọn mìíràn, wọ́n bi í léèrè wí pé, “Kí ni ìtumọ̀ òwe rẹ̀?” 11 (C)Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láààyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà. 12 (D)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé,

“ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn,
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run.
Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”

13 (E)Ṣùgbọ́n Jesu wí fún wọn pé, “Bí òwe tí ó rọrùn yìí kò bá yé e yín? Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe mọ ìtumọ̀ àwọn mìíràn tí mo ń sọ fún un yín? 14 Afúnrúgbìn ń fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà. 15 Àwọn èso tó bọ́ sí ojú ọ̀nà, ni àwọn ọlọ́kàn líle tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, lójúkan náà èṣù wá ó sì mú kí wọn gbàgbé ohun tí wọ́n ti gbọ́. 16 Bákan náà, àwọn tí ó bọ́ sórí àpáta, ni àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 17 Ṣùgbọ́n kò ni gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n á wà fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà nígbà ti wàhálà tàbí inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà, lójúkan náà, wọ́n á kọsẹ̀. 18 Àwọn tí ó bọ́ sáàrín ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọn sì gbà á. 19 Ṣùgbọ́n láìpẹ́ jọjọ, àwọn adùn ayé àti inú dídùn, ọrọ̀ àti ìjàkadì fún àṣeyọrí àti ìfẹ́ àwọn ohun mèremère ayé, gba ọkàn wọn, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa ní ọkàn wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ aláìléso. 20 Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì gbà á lóòtítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.