Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jeremiah 1-2

Èyí ni ọ̀rọ̀ Jeremiah ọmọ Hilkiah ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà ní Anatoti ní agbègbè ilẹ̀ Benjamini. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá ní ọdún kẹtàlá ní àkókò ìjọba Josiah ọmọ Amoni ọba Juda, Àti títí dé àsìkò Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, títí dé oṣù karùn-ún ọdún kọkànlá Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, nígbà tí àwọn ará Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn.

Ìpè Jeremiah

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé,

(A)Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́n,
    kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀.
    Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè.

Mo sọ pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè, ọmọdé ni mí, èmi kò mọ bí a ṣe é sọ̀rọ̀.”

Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe sọ pé, ‘Ọmọdé lásán ni mí.’ O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.” (B)Olúwa sì wí pé má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ èmi ó sì gbà ọ́.

Olúwa sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsin yìí mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ 10 (C)Wò ó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, láti wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti máa kọ́, àti láti máa gbìn.

11 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ mí wá wí pé:

“Kí ni o rí Jeremiah?”

Mo sì dáhùn wí pé “Mo rí ẹ̀ka igi almondi.”

12 Olúwa sì wí fún mi pé, “Ó ti rí i bí ó ṣe yẹ, nítorí pé mo ti ń ṣọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúṣẹ.”

13 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ mi wá ní ẹ̀ẹ̀kejì pé, “Kí ni o rí?” Mo sì dáhùn pé mo rí ìkòkò gbígbóná, tí ó ń ru láti apá àríwá.

14 Olúwa, sì wí fún mi pé, “Láti apá àríwá ni a ó ti mu ìdààmú wá sórí gbogbo àwọn tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà. 15 Mo sì ti ṣetán láti pe gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè àríwá níjà,” ni Olúwa wí.

Àwọn ọba wọn yóò wá
    gbé ìtẹ́ wọn ró ní ojú ọ̀nà àbáwọlé
Jerusalẹmu. Wọn ó sì dìde sí gbogbo
    àyíká wọn àti sí gbogbo àwọn
    ìlú Juda.
16 Èmi yóò sì kéde ìdájọ́ mi lórí àwọn ènìyàn mi
    nítorí ìwà búburú wọn nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀,
nípa rírúbọ sí ọlọ́run mìíràn
    àti sínsin àwọn ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe.

17 “Wà ní ìmúrasílẹ̀! Dìde dúró kí o sì sọ fún wọn ohunkóhun tí mo bá pàṣẹ fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n dẹ́rùbà ọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀rù níwájú wọn. 18 Ní òní èmi ti sọ ọ́ di ìlú alágbára, òpó irin àti odi idẹ sí àwọn ọba Juda, àwọn ìjòyè rẹ̀, sí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. 19 Wọn yóò dojú ìjà kọ ọ́, wọn kì yóò borí rẹ, nítorí wí pé èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì gbà ọ́,” ni Olúwa wí.

Israẹli kọ Ọlọ́run sílẹ̀

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé: “Lọ kí o sì kéde sí etí Jerusalẹmu pé:

“Báyìí ni Olúwa wí,

“ ‘Èmi rántí ìṣeun ìgbà èwe rẹ,
    ìfẹ́ ìgbéyàwó rẹ
àti nígbà tí ìwọ tẹ̀lé mi nínú ijù,
    nínú ìyàngbẹ ilẹ̀.
Israẹli jẹ́ mímọ́ sí Olúwa,
    àkọ́kọ́ èso ìkórè rẹ̀,
gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó jẹ run ni a ó dá lẹ́bi,
    ibi yóò sì wá sí orí wọn,’ ”
    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.

Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ìdílé Jakọbu
    àti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Israẹli.

Báyìí ni Olúwa wí:

“Irú àìṣedéédéé wo ni baba yín rí lọ́wọ́ mi?
Tí wọ́n fi jìnnà sí mi?
    Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán,
    àwọn fúnrawọn sì di asán.
Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni Olúwa wà,
    tí ó mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
tí ó mú wa la aginjù já,
    tí ó mú wa la àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ihò,
ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn biribiri,
    ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kò sì tẹ̀dó sí?’
Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá
    láti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀,
ṣùgbọ́n ẹ̀yin wọ inú rẹ̀, ẹ sì bà á jẹ́,
    ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra.
Àwọn àlùfáà kò béèrè wí pé,
    ‘Níbo ni Olúwa wà?’
Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí,
    àwọn olùṣọ́ sì ṣẹ̀ sí mi.
Àwọn wòlíì sì ń sọtẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà Baali,
    wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán.

“Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ̀kan sí i,”
    ni Olúwa wí.
    “Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ
10 Rékọjá lọ sí erékùṣù àwọn ara Kittimu, kí ẹ sì wò ó,
    ránṣẹ́ lọ sí Kedari, kí ẹ sì kíyèsi gidigidi
kí ẹ wò bí irú nǹkan báyìí bá ń bẹ níbẹ̀?
11 Orílẹ̀-èdè kan ha á pa Ọlọ́run rẹ̀ dà?
    (Síbẹ̀, wọ́n kì í ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run)
àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀
    ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì.
12 Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì
    kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,”
    ni Olúwa wí.
13 “Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì
    Wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, Èmi
orísun omi ìyè, wọ́n sì ti
    ṣe àmù, àmù fífọ́ tí kò lè
    gba omi dúró.
14 Israẹli ha á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀
    ẹrú nípa ìbí? Kí ló ha a
    dé tí ó fi di ìkógun?
15 Àwọn kìnnìún ké ramúramù
    wọ́n sì ń bú mọ́ wọn
wọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfò
    Ìlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sì
    ti di ìkọ̀sílẹ̀.
16 Bákan náà, àwọn ọkùnrin
    Memfisi àti Tafanesi
    wọ́n ti fa adé orí rẹ yọ.
17 Ẹ̀yin kò ha a ti fa èyí sórí
    ara yín nípa kíkọ Ọlọ́run sílẹ̀
    nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà?
18 Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Ejibiti
    láti lọ mu omi ní Ṣihori?
Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Asiria
    láti lọ mú omi ni odò Eufurate náà?
19 Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yín
    ìpadàsẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wí
mọ̀ kí o sì rí i wí pé ibi àti
    ohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹ
nígbà tí o ti kọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀,
    ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,”
    ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

20 “Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgà
    rẹ sọnù, ìwọ sì já ìdè rẹ
ìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’
    Lóòtítọ́, lórí gbogbo òkè gíga ni
àti lábẹ́ igi tí ó tànkálẹ̀
    ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà.
21 Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bí
    àjàrà ọ̀tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá,
Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí mi
    di àjàrà búburú àti aláìmọ́?
22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódà
    tí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹ
síbẹ̀síbẹ̀ èérí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ níwájú,”
    ni Olúwa Olódùmarè wí.
23 “Báwo ni ìwọ ṣe wí pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́;
    Èmi kò sá à tẹ̀lé àwọn Baali’?
Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì;
    wo ohun tí o ṣe.
Ìwọ jẹ́ abo ìbákasẹ
    tí ń sá síhìn-ín sọ́hùn-ún.
24 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń gbé aginjù
    tí ń fa ẹ̀fúùfù ìfẹ́ sí i mu rẹ,
ta ni ó le è mú dúró ní àkókò rẹ̀?
    Kí gbogbo àwọn akọ ẹran tí o wá a kiri kì ó má ṣe dá ara wọn lágara,
    nítorí wọn yóò rí ní àkókò oṣù rẹ̀.
25 Dá ẹsẹ̀ dúró láìwọ bàtà,
    àti ọ̀fun rẹ nínú òǹgbẹ.
Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Asán ni!
    Èmi fẹ́ràn àwọn ọlọ́run àjèjì,
    àwọn ni èmi yóò tọ̀ lẹ́yìn.’

26 “Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń dójútì olè nígbà tí a bá mú u,
bẹ́ẹ̀ náà ni ojú yóò ti ilé Israẹli—
    àwọn ọba àti àwọn ìjòyè wọn,
    àwọn àlùfáà àti wòlíì wọn pẹ̀lú.
27 Wọ́n sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni baba mi,’
    àti sí òkúta wí pé, ‘Ìwọ ni ó bí mi,’
wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí mi,
    wọn kò kọ ojú sí mi
síbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro,
    wọn yóò wí pé, ‘Wá kí o sì gbà wá!’
28 Níbo wá ni àwọn ọlọ́run tí
    ẹ ṣe fúnrayín ha a wà?
Jẹ́ kí wọ́n wá kí wọ́n sì
    gbà yín nígbà tí ẹ bá
wà nínú ìṣòro! Nítorí pé
    ẹ̀yin ní àwọn ọlọ́run púpọ̀, gẹ́gẹ́
    bí ẹ ti ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Juda.

29 “Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí?
    Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,”
    ni Olúwa wí.
30 “Nínú asán mo fìyà jẹ àwọn ènìyàn yín,
    wọn kò sì gba ìbáwí.
Idà yín ti pa àwọn wòlíì yín run,
    gẹ́gẹ́ bí kìnnìún tí ń bú ramúramù.

31 “Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ kíyèsi ọ̀rọ̀ Olúwa:

“Mo ha ti di aginjù sí Israẹli
    tàbí mo jẹ ilẹ̀ olókùnkùn biribiri?
Èéṣe tí àwọn ènìyàn mi ṣe wí pé,
    ‘A ní àǹfààní láti máa rìn kiri;
àwa kì yóò tọ̀ ọ́ wá mọ́?’
32 Wúńdíá ha le gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀,
    tàbí ìyàwó ohun ọ̀ṣọ́ ìgbéyàwó rẹ̀?
Síbẹ̀, àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé mi ní ọjọ́ àìníye.
33 Ìwọ ti jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́!
    Àwọn obìnrin búburú yóò kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà rẹ
34 Lórí aṣọ rẹ ni wọ́n bá ẹ̀jẹ̀
    àwọn tálákà aláìṣẹ̀
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò ká wọn mọ́
    níbi tí wọ́n ti ń rùn wọlé
35 Síbẹ̀ nínú gbogbo èyí
    ìwọ sọ wí pé, ‘Èmi jẹ́ aláìṣẹ̀
kò sì bínú sí mi.’
    Èmi yóò mú ìdájọ́ mi wá sórí rẹ
    nítorí pé ìwọ wí pé, ‘Èmi kò dẹ́ṣẹ̀.’
36 Èéṣe tí ìwọ fi ń lọ káàkiri
    láti yí ọ̀nà rẹ padà?
Ejibiti yóò dójútì ọ́
    gẹ́gẹ́ bí i ti Asiria
37 Ìwọ yóò sì fi ibẹ̀ sílẹ̀
    pẹ̀lú kíkáwọ́ rẹ lé orí rẹ,
nítorí pé Olúwa ti kọ̀ àwọn
    tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé sílẹ̀,
kì yóò sí ìrànlọ́wọ́ kankan
    fún ọ láti ọ̀dọ̀ wọn.

1 Timotiu 3

Alábojútó àti Díákónì

Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, bí ẹnìkan bá fẹ́ ipò alábojútó, iṣẹ́ rere ni ó ń fẹ́, Ǹjẹ́ alábojútó yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùṣọ̀ràn, aláìrékọjá, oníwà rere, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́. Kí ó má jẹ́ ọ̀mùtí, tàbí oníjàgídíjàgan, tàbí olójúkòkòrò, bí kò ṣe onísùúrù, kí ó má jẹ́ oníjà, tàbí olùfẹ́ owó. Ẹni tí ó káwọ́ ilé ara rẹ̀ gírígírí, tí ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ tẹríba pẹ̀lú ìwà àgbà gbogbo; Ṣùgbọ́n bí ènìyàn kò bá mọ̀ bí a ti ń ṣe ìkáwọ́ ilé ara rẹ̀, òun ó ha ti ṣe lè tọ́jú ìjọ Ọlọ́run? Kí ó má jẹ́ ẹni tuntun ti ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàgbọ́, kí ó má ba à gbéraga, a sì ṣubú sínú ẹ̀bi èṣù. Ó sì yẹ kí ó ni ẹ̀rí rere pẹ̀lú lọ́dọ̀ àwọn tí ń bẹ lóde; kí ó má ba à bọ́ sínú ẹ̀gàn àti sínú ìdẹ̀kùn èṣù.

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn Díákónì láti ní ìwà àgbà, kí wọ́n máa jẹ́ ẹlẹ́nu méjì, kí wọ́n máa fi ara wọn fún wáìnì púpọ̀, kí wọ́n má jẹ́ olójúkòkòrò. Kí wọn máa di ohun ìjìnlẹ̀ ìgbàgbọ́ mú pẹ̀lú ọkàn funfun. 10 Kí a kọ́kọ́ wádìí àwọn wọ̀nyí dájú pẹ̀lú; nígbà náà ni kí a jẹ́ kí wọn ó ṣiṣẹ́ díákónì, bí wọn bá jẹ́ aláìlẹ́gàn.

11 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn obìnrin láti ni ìwà àgbà, kí wọn má jẹ́ asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn bí kò ṣe aláìrékọjá, olóòtítọ́ ní ohun gbogbo.

12 Kí àwọn díákónì jẹ́ ọkọ obìnrin kan, kí wọn káwọ́ àwọn ọmọ àti ilé ara wọn dáradára. 13 Nítorí àwọn tí ó lo ipò díákónì dáradára ra ipò rere fún ara wọn, àti ìgboyà púpọ̀ nínú ìgbàgbọ́ tí ń bẹ nínú Kristi Jesu.

14 Ìwé nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ sí ọ, mo sì ń retí àti tọ̀ ọ́ wá ní lọ́ọ́lọ́ọ́. 15 Ṣùgbọ́n bí mo bá pẹ́, kí ìwọ lè mọ̀ bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn láti máa hùwà nínú ilé Ọlọ́run, tì í ṣe ìjọ Ọlọ́run alààyè, ọ̀wọ́n àti ìpìlẹ̀ òtítọ́. 16 Láìṣiyèméjì, títóbi ní ohun ìjìnlẹ̀ ìwà-bí-Ọlọ́run:

ẹni tí a fihàn nínú ara,
    tí a dá láre nínú Ẹ̀mí,
ti àwọn angẹli rí,
    tí a wàásù rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
tí a gbàgbọ́ nínú ayé,
    tí a sì gbà sókè sínú ògo.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.