Old/New Testament
Ìkìlọ̀ láti ṣọ́ra fún ìwà òmùgọ̀
6 Ọmọ mi, bí ìwọ bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ,
bí ìwọ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì ènìyàn,
2 bí a bá ti fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ dẹkùn mú ọ,
tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ti kó ọ sí pàkúté,
3 Nígbà náà, ṣe èyí, ìwọ ọmọ mi, láti gba ara rẹ
níwọ̀n bí o ti kó ṣọ́wọ́ aládùúgbò rẹ:
lọ kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀;
bẹ aládùúgbò rẹ dáradára
4 Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́,
tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá.
5 Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo èsúró kúrò lọ́wọ́ ọdẹ,
bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ.
6 Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ
kíyèsi ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n!
7 Kò ní olùdarí,
kò sí alábojútó tàbí ọba,
8 síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjò
yóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè.
9 Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ?
Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ?
10 Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,
ìkáwọ́gbera láti sinmi díẹ̀
11 Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣà
àti àìní bí adigunjalè.
12 Ènìyànkénìyàn àti ènìyàn búburú,
tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri,
13 tí ó ń ṣẹ́jú pàkòpàkò,
ó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀
ó sì ń fi ìka ọwọ́ rẹ̀ júwe,
14 tí ó ń pète búburú pẹ̀lú ẹ̀tàn nínú ọkàn rẹ̀
ìgbà gbogbo ni ó máa ń dá ìjà sílẹ̀.
15 Nítorí náà ìdààmú yóò dé bá a ní ìṣẹ́jú akàn;
yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.
16 Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra,
ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i:
17 Ojú ìgbéraga,
Ahọ́n tó ń parọ́
ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,
18 ọkàn tí ń pète ohun búburú,
ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà,
19 Ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu
àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan.
Ìkìlọ̀ nítorí àgbèrè
20 Ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́
má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.
21 Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláé
so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ
22 Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ;
nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùṣọ́ rẹ;
nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀.
23 Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà,
ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀,
àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwí
ni ọ̀nà sí ìyè.
24 Yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin búburú,
kúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn obìnrin àjèjì.
25 Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹ
tàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra.
26 Nítorí pé nípasẹ̀ àgbèrè obìnrin ni ènìyàn fi ń di oníṣù-àkàrà kan,
ṣùgbọ́n àyà ènìyàn a máa wá ìyè rẹ̀ dáradára.
27 Ǹjẹ́ ọkùnrin ha le è gbé iná lé orí itan
kí aṣọ rẹ̀ má sì jóná?
28 Ǹjẹ́ ènìyàn le è máa rìn lórí iná?
Kí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì má jóná?
29 Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sùn pẹ̀lú aya aláya;
kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí yóò lọ láìjìyà.
30 Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalè
nítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á.
31 Síbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méje
bí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà.
32 Ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbèrè kò nírònú;
ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ó ń pa ara rẹ̀ run ni
33 Ìfarapa àti ìtìjú ni tirẹ̀,
ẹ̀gàn rẹ̀ kì yóò sì kúrò láéláé.
34 Nítorí owú yóò ru ìbínú ọkọ sókè,
kì yóò sì ṣàánú nígbà tí ó bá ń gbẹ̀san.
35 Kò nígbà nǹkan kan bí ohun ìtánràn;
yóò kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó.
Ìkìlọ̀ nítorí àwọn aṣẹ́wó
7 Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́,
sì fi àwọn òfin mi pamọ́ sínú ọkàn rẹ.
2 Pa òfin mi mọ́, ìwọ yóò sì yè
tọ́jú ẹ̀kọ́ mi bí ẹyinlójú rẹ
3 Kọ wọ́n sí ọwọ́ òsì rẹ, má ṣe fi jẹun
kọ wọ́n sí inú wàláà àyà rẹ.
4 Wí fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arábìnrin mi,”
sì pe òye ní ìbátan rẹ;
5 Wọn yóò pa ó mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin alágbèrè,
kúrò lọ́wọ́ àjèjì obìnrin àti ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀.
6 Ní ojú fèrèsé ilé è mi
mo wo ìta láti ojú fèrèsé.
7 Mo rí i láàrín àwọn aláìmọ̀kan
mo sì kíyèsi láàrín àwọn ọ̀dọ́kùnrin,
ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n.
8 Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbèrè obìnrin náà,
ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀
9 Ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀,
bí òkùnkùn ṣe ń bo ni lára.
10 Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀,
ó múra bí panṣágà pẹ̀lú ètè búburú.
11 (Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí,
ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé;
12 bí ó ti ń já níhìn-ín ní ó ń já lọ́hùn ún
gbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.)
13 Ó dìímú, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu
pẹ̀lú ojú díndín ó wí pé:
14 “Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé;
lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi.
15 Nítorí náà ni n o ṣe jáde wá pàdé è rẹ;
mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ!
16 Mo ti tẹ́ ibùsùn mi
pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Ejibiti.
17 Mo ti fi nǹkan olóòórùn dídùn sí ibùsùn mi
bí i òjìá, aloe àti kinamoni.
18 Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀;
jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!
19 Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé;
ó ti lọ sí ìrìnàjò jíjìn.
20 Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́
kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”
21 Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà;
ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.
22 Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà,
bí i màlúù tí ń lọ sí ibùpa,
tàbí bí (aṣiwèrè) àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi ọgbọ́n ìfabà kọ́.
23 Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀,
bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn,
láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.
24 Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi
fọkàn sí nǹkan tí mo sọ.
25 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀,
tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀.
26 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀
Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.
27 Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààrà sí isà òkú,
tí ó lọ tààrà sí àgbàlá ikú.
2 1 Nítorí náà mo tí pinnu nínú ara mí pé, èmi kì yóò tún fi ìbànújẹ́ tọ̀ yin wá. 2 Nítorí pé bí èmi bá mú inú yín bàjẹ́, ǹjẹ́ ta ni ẹni ti ìbá mú inú mí dùn ní àkókò tí inú mi bá bàjẹ́ bí kò ṣe ẹni tí mo ti ba nínú jẹ́? 3 Èmi sì kọ̀wé bí mo tí kọ sí yín pé, nígbà tí mo bá sì de, kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ti ìbá mú mi ní ayọ̀: nítorí tí mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú gbogbo yín, wí pé ẹ̀yin yóò jẹ́ alábápín ayọ̀ mi. 4 Nítorí pé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà àti ìrora ọkàn mí ni mo ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ omijé kọ̀wé sí yín; kì í ṣe nítorí kí a lè bà yín nínú jẹ́, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin bá a lè mọ bí ìfẹ́ tí mo ní sí yín ṣe jinlẹ̀ tó.
Ìdáríjì fún ẹlẹ́ṣẹ̀
5 Bí ẹnikẹ́ni bá fa ohun ìbànújẹ́ kì í ṣe èmi ni ó bà nínú jẹ́, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnrayín, níwọ̀n ìyówù kí ó jẹ́; n kò fẹ́ sọ ọ́ lọ́nà líle jù. 6 Ìyà náà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fi jẹ́ irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ tó fún un. 7 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ìbá kúkú dáríjì í, kí ẹ sí tù ú nínú ní gbogbo ọ̀nà, kí ìbànújẹ́ má bà á bo irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀. 8 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìdánilójú ìfẹ́ yín hàn sí irú ẹni náà. 9 Ìdí tí mo ṣe kọ̀wé ni kí èmi ba à lè rí ẹ̀rí dìímú nípa ìgbọ́ràn yín nínú ohun gbogbo. 10 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá dáríjì ẹnikẹ́ni, èmi pẹ̀lú dáríjì í. Ohun tí èmi pẹ̀lú bá fi jì, nítorí tiyín ní mo fi jì níwájú Kristi. 11 Kí Satani má ba à rẹ́ wa jẹ. Nítorí àwa kò ṣe aláìmọ́ àrékérekè rẹ̀.
Ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun
12 (A)Ṣùgbọ́n nígbà ti mo dé Troasi láti wàásù ìhìnrere Kristi, tí mo sì rí i wí pé Olúwa ti ṣí ìlẹ̀kùn fún mi, 13 síbẹ̀ èmi kò ní àlàáfíà lọ́kàn mi, nítorí tí èmi kò rí Titu arákùnrin mi níbẹ̀. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe dágbére fún wọn, mo si rékọjá lọ sí Makedonia.
14 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí wá nígbà gbogbo nínú Kristi, tí a sì ń fi òórùn dídùn ìmọ̀ rẹ̀ hàn nípa wa níbi gbogbo. 15 Nítorí òórùn dídùn Kristi ni àwa jẹ́ fún Ọlọ́run, nínú àwọn tí a ń gbàlà àti nínú àwọn tí ó ń ṣègbé: 16 Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè. Ta ni ó ha si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí? 17 Nítorí àwa kò dàbí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣòwò jẹun; ṣùgbọ́n nínú òtítọ́ inú àwa ń sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọ́run nínú Kristi gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.