Read the New Testament in 24 Weeks
Ọ̀rọ̀ Ìyè
1 (A)Èyí tí ó wà láti àtètèkọ́ṣe, tí àwa ti gbọ́, tí àwa ti fi ojú wa rí, tí àwa sì ti tẹjúmọ́, tí ọwọ́ wa sì ti dì mú; èyí tí a kéde; ní ti ọ̀rọ̀ ìyè; 2 iyè náà sì ti farahàn, àwa sì ti rí i, àwa sì ń jẹ́rìí, àwa sì ń sọ ti ìyè àìnípẹ̀kun náà fún yín, tí ó ti ń bẹ lọ́dọ̀ Baba, tí ó sì farahàn fún wa. 3 Àwa ń sọ fún yín, èyí tí àwa ti rí, tí àwa sì ti gbọ́, kí ẹ̀yin pẹ̀lú kí ó lè ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítòótọ́ ìdàpọ̀ wa sì ń bẹ pẹ̀lú Baba àti pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. 4 (B)Àwa sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ayọ̀ yín kí ó lè di kíkún.
Rírìn nínú ìmọ́lẹ̀
5 (C)Èyí sì ni iṣẹ́ tí àwa ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, tí àwa sì ń jẹ́ fún yín: pé ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọ́run; ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì òkùnkùn rárá. 6 (D)Bí àwa bá wí pé àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí àwa sì ń rìn nínú òkùnkùn, àwa ń ṣèké, àwa kò sì gbé nínú òtítọ́. 7 (E)Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òun ti ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú ara wa, àti pé ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi, Ọmọ rẹ̀, wẹ̀ wá nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo.
8 Bí àwa bá wí pé àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀, àwa ń tan ara wa jẹ, òtítọ́ kan kò sì ṣí nínú wa. 9 Bí àwa bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòtítọ́ àti olódodo ni òun láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àti láti wẹ̀ wá nù kúrò nínú àìṣòdodo gbogbo. 10 (F)Bí àwa bá wí pé àwa kò dẹ́ṣẹ̀, àwa mú un ní èké, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ṣí nínú wa.
2 (G)Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, mo kọ ìwé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ẹ̀yin má bà á dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá sì dẹ́ṣẹ̀, àwa ni alágbàwí lọ́dọ̀ Baba: Jesu Kristi, olódodo nìkan. 2 (H)Òun sì ní ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, kì í tilẹ̀ ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo aráyé.
3 Àwa mọ̀ pé àwa ti wá mọ̀ ọ́n, bí àwa bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́. 4 (I)Ẹni tí ó bá wí pé, “Èmi mọ̀ ọ́n,” tí kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, èké ni, òtítọ́ kò sì ṣí nínú rẹ̀. 5 (J)Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́, lára rẹ̀ ni a gbé mú ìfẹ́ Ọlọ́run pé nítòótọ́. Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń wà nínú rẹ̀. 6 (K)Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú rẹ̀, òun náà pẹ̀lú sì yẹ láti máa rìn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti rìn.
7 (L)Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kì í ṣe òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín ṣùgbọ́n òfin àtijọ́, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe. Òfin àtijọ́ ni ọ̀rọ̀ náà tí ẹ̀yin tí gbọ́. 8 (M)Pẹ̀lúpẹ̀lú, òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín; èyí tí í ṣe òtítọ́ nínú rẹ̀ àti nínú yin, nítorí òkùnkùn ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ sì tí ń tàn.
9 Ẹni tí ó bá sì wí pé òun ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, tí ó sì kórìíra arákùnrin rẹ̀ sì ń bẹ nínú òkùnkùn. 10 (N)Ẹni tí ó ba fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀, ó ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, kò sì ṣí ohun ìkọ̀sẹ̀ kan nínú rẹ̀. 11 Ṣùgbọ́n ẹni tí o bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ ń gbé nínú òkùnkùn, ó sì ń rìn nínú òkùnkùn; kò sì mọ ibi tí òun ń lọ, nítorí tí òkùnkùn tí fọ́ ọ lójú.
12 Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n,
nítorí tí a darí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ rẹ̀.
13 (O)Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba,
nítorí tí ẹ̀yin tí mọ ẹni tí ó wà ní àtètèkọ́ṣe,
Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin,
nítorí tí ẹ̀yin ti ṣẹ́gun ẹni ibi náà.
14 Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọdé mi ọ̀wọ́n,
nítorí ẹ̀yin ti mọ Baba.
Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba,
nítorí ti ẹ̀yin tí mọ ẹni tí o wà ni àtètèkọ́ṣe.
Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin,
nítorí tí ẹ̀yin ni agbára,
tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ń gbé nínú yín,
tí ẹ sì ṣẹ́gun ẹni ibi náà.
Ẹ má ṣe fẹ́ràn ayé
15 Ẹ má ṣe fẹ́ràn ayé tàbí ohunkóhun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn ayé, ìfẹ́ tí Baba kò sí nínú rẹ̀. 16 Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ojú, àti ìgbéraga ti ohun ti ó ní àti ohun tí ó ṣe: kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bí kò ṣe láti ọwọ́ ayé. 17 Ayé sì ń kọjá lọ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò wà títí láéláé.
Ìkìlọ̀ nípa àwọn aṣòdì sí Kristi
18 (P)Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, ìgbà ìkẹyìn ni èyí; bí ẹ̀yin sì tí gbọ́ pé aṣòdì sí Kristi ń bọ̀ wá, àní nísinsin yìí, púpọ̀ aṣòdì sí Kristi ló ń bẹ. Nípa èyí ni àwa fi mọ́ pé ìgbà ìkẹyìn ni èyí. 19 Wọ́n ti ọ̀dọ̀ wá jáde, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe ara wa. Nítorí bí wọ́n bá jẹ́ ara wa, wọn ìbá bá wa dúró: ṣùgbọ́n jíjáde lọ wọn fihàn pé gbogbo wọn kì í ṣe ara wa.
20 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní ìfòróróyàn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ wá, gbogbo yín sì mọ òtítọ́. 21 Èmi kò kọ̀wé sí yín nítorí pé ẹ̀yin kò mọ òtítọ́, ṣùgbọ́n nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, àti pé kò sí èké nínú òtítọ́. 22 (Q)Ta ni èké? Ẹni tí ó sẹ́ pé Jesu kì í ṣe Kristi. Eléyìí ni Aṣòdì sí Kristi: ẹni tí ó sẹ́ Baba àti Ọmọ. 23 (R)Ẹnikẹ́ni tí o ba sẹ́ Ọmọ, kò gba Baba; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba jẹ́wọ́ Ọmọ, ó gba Baba pẹ̀lú.
24 Ẹ jẹ́ kí èyí tí ẹ tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe máa gbé inú yín. Bí èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe bá ń gbé inú yín, ẹ̀yin ó sì dúró nínú Ọmọ àti nínú Baba. 25 Èyí sì ni ìlérí náà tí ó tí ṣe fún wa, àní ìyè àìnípẹ̀kun.
26 Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé sí yín ní ti àwọn tí wọ́n fẹ́ ẹ mún un yín ṣìnà. 27 (S)Ṣùgbọ́n ní ti ìfóróróyàn tí ẹ̀yín gba lọ́wọ́ rẹ̀ ṣì ń gbé inú yín, ẹ̀yin kò tún nílò pé kí ẹnìkan kọ yín. Ṣùgbọ́n bí ìfòróróyàn náà ti ń kọ́ yín ní ohun gbogbo tí ó jẹ́ òtítọ́, tí kì í sì í ṣe èké, àní gẹ́gẹ́ bí ó sì ti kọ́ yín, ẹ máa gbé inú rẹ̀.
Àwọn ọmọ Ọlọ́run
28 (T)Àti nísinsin yìí, ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, ẹ máa gbé inú rẹ̀, pé nígbà tí òun ó bá farahàn, kí a lè ni ìgboyà níwájú rẹ̀, kí ojú má sì tì wá níwájú rẹ̀ ni ìgbà wíwá rẹ̀.
29 (U)Bí ẹ̀yin ba mọ̀ pé olódodo ni òun, ẹ mọ̀ pé a bí olúkúlùkù ẹni tí ń ṣe òdodo nípa rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.