New Testament in a Year
21 (A)A tí kọ ọ́ nínú òfin pé,
“Nípa àwọn aláhọ́n mìíràn
àti elétè àjèjì
ní èmi ó fi ba àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀;
síbẹ̀ wọn kì yóò gbọ́ tèmi,”
ni Olúwa wí.
22 Nítorí náà àwọn ahọ́n jásí ààmì kan, kì í ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n ìsọtẹ́lẹ̀ kì í ṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́ bí kò ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́. 23 Ǹjẹ́ bí gbogbo ìjọ bá péjọ sí ibi kan, tí gbogbo wọn sí ń fi èdè fọ̀, bí àwọn tí ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìgbàgbọ́ bá wọlé wá, wọn kí yóò ha wí pé ẹ̀yin ń ṣe òmùgọ̀? 24 Ṣùgbọ́n bí gbogbo yín bá ń sọtẹ́lẹ̀, ti ẹnìkan tí kò gbàgbọ́ tàbí tí ko ni ẹ̀kọ́ bá wọlé wá, gbogbo yin ní yóò fi òye ẹ̀ṣẹ̀ yé e, gbogbo yin ní yóò wádìí rẹ̀. 25 Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì fi àṣírí ọkàn rẹ̀ hàn; bẹ́ẹ̀ ni òun ó sì dojúbolẹ̀, yóò sí sin Ọlọ́run yóò sì sọ pé, “Nítòótọ́ Ọlọ́run ń bẹ láàrín yín!”
Ètò ìsìn lẹ́sẹẹsẹ
26 (B)Ǹjẹ́ èéha ti ṣe, kín ni àwa yóò sọ ẹ̀yin ará? Nígbà tí ẹ̀yin péjọpọ̀, tí olúkúlùkù yín ni Saamu kan tàbí ẹ̀kọ́ kan, èdè kan, ìfihàn kan àti ìtumọ̀ kan. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láti gbé ìjọ ró. 27 Bí ẹnìkan bá fi èdè fọ̀, kí ó jẹ ènìyàn méjì, tàbí bí ó pọ̀ tán, kí ó jẹ́ mẹ́ta, kí ó sọ̀rọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí ẹnìkan sì túmọ̀ rẹ̀, 28 Ṣùgbọ́n bí kò bá sí ògbufọ̀, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ nínú ìjọ; sì jẹ́ kí ó máa bá ara rẹ̀ àti Ọlọ́run sọ̀rọ̀.
29 Jẹ́ kí àwọn wòlíì méjì tàbí mẹ́ta sọ̀rọ̀, ki àwọn ìyókù sì wòye ìtumọ̀ ohun tí a sọ. 30 Bí a bá sì fi ohunkóhun hàn ẹni tí ó jókòó níbẹ̀, jẹ́ kí ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ ṣáájú dákẹ́. 31 Nítorí gbogbo yín lè sọtẹ́lẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo yín lè kọ́ ẹ̀kọ́, kí a lè tu gbogbo yín nínú. 32 Ẹ̀mí àwọn wòlíì a sí máa tẹríba fún àwọn wòlíì. 33 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu, ṣùgbọ́n ti àlàáfíà. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ nínú gbogbo ìjọ ènìyàn mímọ́.
34 (C)Jẹ́ ki àwọn obìnrin yín dákẹ́ nínú ìjọ: nítorí a kò fi fún wọn láti sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn wà lábẹ́ ìtẹríba, gẹ́gẹ́ bí òfin pẹ̀lú ti wí. 35 Bí wọ́n bá sì fẹ́ mọ̀ nípa ohunkóhun, kí wọn béèrè lọ́wọ́ ọkọ wọn ní ilé; nítorí ohun ìtìjú ni fún àwọn obìnrin láti máa sọ̀rọ̀ nínú ìjọ.
36 Kín ni? Ṣe lọ́dọ̀ yín ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jáde ni, tàbí ẹ̀yin nìkan ni o tọ̀ wá? 37 Bí ẹnikẹ́ni bá ró ará rẹ̀ pé òun jẹ́ wòlíì, tàbí òun jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, jẹ́ kí nǹkan wọ̀nyí ti mo kọ sí yin yé e dájú pé òfin Olúwa ni wọ́n. 38 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá fi ojú fo èyí dá, òun fúnrarẹ̀ ní a ó fi ojú fò dá.
39 Nítorí náà ará, ẹ máa fi ìtara ṣàfẹ́rí láti sọtẹ́lẹ̀, kí ẹ má sì ṣe dánilẹ́kun láti fi èdè fọ̀. 40 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo tẹ̀yẹtẹ̀yẹ àti lẹ́sẹẹsẹ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.