Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

New Testament in a Year

Read the New Testament from start to finish, from Matthew to Revelation.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Luku 22:31-46

31 (A)Olúwa sì wí pé, “Simoni, Simoni, wò ó, Satani fẹ́ láti gbà ọ́, kí ó lè kù ọ́ bí alikama: 32 (B)Ṣùgbọ́n mo ti gbàdúrà fún ọ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀; àti ìwọ nígbà tí ìwọ bá sì padà bọ̀ sípò, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le.”

33 (C)Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sínú túbú, àti sí ikú.”

34 Ó sì wí pé, “Mo wí fún ọ, Peteru, àkùkọ kì yóò kọ lónìí tí ìwọ ó fi sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, ìwọ kò mọ̀ mí.”

35 (D)Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí mo rán yín lọ láìní àpò-owó, àti àpò, àti bàtà, ọ̀dá ohun kan dá yín bí?”

Wọ́n sì wí pé, “Rárá!”

36 (E)Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹni tí ó bá ní àpò-owó kí ó mú un, àti àpò pẹ̀lú; ẹni tí kò bá sì ní idà, kí ó ta aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi ra ọ̀kan. 37 (F)Nítorí mo wí fún yín pé, ‘Èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ lára mi, A sì kà á mọ́ àwọn arúfin.’ Nítorí àwọn ohun wọ̀nyí nípa ti èmi yóò ní ìmúṣẹ.”

38 Wọ́n sì wí pé, “Olúwa, sá wò ó, idà méjì ń bẹ níhìn-ín yìí!”

Ó sì wí fún wọn pé, “Ó tó.”

Jesu gbàdúrà lórí òkè olifi

39 (G)Ó sì jáde, ó sì lọ bí ìṣe rẹ̀ sí òkè olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 40 (H)(I)Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.” 41 Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níwọ̀n ìsọ-òkò kan, ó sì kúnlẹ̀ ó sì ń gbàdúrà. 42 (J)Wí pé, “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mu ago yìí kúrò lọ́dọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmi kọ́, bí kò ṣe tìrẹ ni kí à ṣe.” 43 Angẹli kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú. 44 Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀.

45 Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó bá wọn, wọ́n ń sùn nítorí ìbànújẹ́ ti mu kí ó rẹ̀ wọ́n. 46 Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ yin ń sùn sí? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.