New Testament in a Year
3 (A)Nígbà tí Jesu wá sí Sinagọgu. Sì kíyèsi i ọkùnrin kan wà níbẹ̀, tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. 2 (B)Àwọn kan nínú wọn sì ń wa ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jesu, Nítorí náà, wọ́n ń ṣọ́ Ọ bí yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi. 3 Jesu wí fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé, “Dìde dúró ní iwájú ìjọ ènìyàn.”
4 Nígbà náà ni Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ǹjẹ́ ó bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi bóyá láti ṣe rere, tàbí láti ṣe búburú! Láti gbà ẹ̀mí là, tàbí pa á run?” Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́ láìfèsì.
5 Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá. 6 (C)Lójúkan náà, àwọn Farisi jáde lọ, láti bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Herodu gbìmọ̀ pọ̀, bí wọn yóò ṣe pa Jesu.
Ọ̀pọ̀ ènìyàn tẹ̀lé Jesu
7 (D)Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra kúrò níbẹ̀ lọ sí etí Òkun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili àti Judea sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 8 (E)Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá láti Judea, Jerusalẹmu àti Idumea, àti láti apá kejì odò Jordani àti láti ìhà Tire àti Sidoni. 9 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣètò ọkọ̀ ojú omi kékeré kan sílẹ̀ fún un láti lọ, láti lé àwọn èrò sẹ́yìn. 10 (F)Nítorí tí ó mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláìsàn ló bí ara wọn lù ú láti fi ọwọ́ kàn án. 11 Ìgbàkúgbà tí àwọn tí ó ni ẹ̀mí àìmọ́ bá ti fojú ri, wọ́n á wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọn a sì kígbe lóhùn rara wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.” 12 (G)Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí wọn má ṣe fi òun hàn.
Jesu yan àwọn aposteli méjìlá
13 (H)Jesu gun orí òkè lọ, ó sì pe àwọn kan tí ó yàn láti wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá. 14 Ó yan àwọn méjìlá, kí wọn kí ó lè wà pẹ̀lú rẹ̀, àti kí ó lè rán wọn lọ láti wàásù 15 àti láti lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí Èṣù jáde.
16 (I)Wọ̀nyí ni àwọn méjìlá náà tí ó yàn:
Simoni (ẹni ti ó sọ àpèlé rẹ̀ ní Peteru)
17 Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jesu sọ àpèlé wọ́n ní Boanaji, èyí tí ó túmọ̀ sí àwọn ọmọ àrá).
18 Àti Anderu,
Filipi,
Bartolomeu,
Matiu,
Tomasi,
Jakọbu ọmọ Alfeu,
Taddeu,
Simoni tí ń jẹ́ Sealoti (ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ tí o ń ja fun òmìnira àwọn Júù).
19 (J)Àti Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi í hàn níkẹyìn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.