New Testament in a Year
17 Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòye ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí. 18 Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurùdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. 19 (A)Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin Ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrin dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa. 20 Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní Baba, ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wá.
Àwọn aya àti ọkọ
21 Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
22 (B)Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa. 23 Nítorí pé ọkọ ni ó ń ṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí i ṣe orí ìjọ, tí òun si ń ṣe ara rẹ̀, Òun sì ni Olùgbàlà rẹ̀. 24 Nítorí náà gẹ́gẹ́ bí ìjọ tí i tẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ sì ní kì àwọn aya máa ṣe sí ọkọ wọn ní ohun gbogbo.
25 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un. 26 Kí òun lè sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó tí fi ọ̀rọ̀ wẹ̀ ẹ́ nínú agbada omí. 27 Kí òun lé mú un wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó ní ògo ní àìlábàwọ́n, tàbí àlébù kan, tàbí irú nǹkan bá-wọ̀n-ọn-nì: ṣùgbọ́n kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù. 28 Bẹ́ẹ̀ ní ó tọ́ kí àwọn ọkùnrin máa fẹ́ràn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnrawọn. 29 Nítorí kò sì ẹnìkan tí ó ti kórìíra ara rẹ̀; bí kò ṣe pé kí ó máa bọ́ ọ kí ó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi sì ti ń ṣe sí ìjọ. 30 Nítorí pé àwa ni ẹ̀yà ara rẹ̀, àti tí ẹran-ara rẹ̀, àti egungun ara rẹ̀. 31 (C)Nítorí èyí ní ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan. 32 Àṣírí ńlá ní èyí: ṣùgbọ́n èmí ń sọ nípá ti Kristi àti tí ìjọ. 33 Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yín fẹ́ràn aya rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun fúnrarẹ̀; kí aya kí ó sì bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.