New Testament in a Year
Ìpè sí ìforítì
19 Ará, ǹjẹ́ bí a ti ní ìgboyà láti wọ inú ibi mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jesu, 20 nípa ọ̀nà títún àti ààyè, tí o yà sí mímọ́ fún wa, àti láti kọjá aṣọ ìkélé èyí yìí ní, ara rẹ̀; 21 àti bí a ti ni àlùfáà gíga lórí ilé Ọlọ́run; 22 ẹ jẹ́ kí a fi òtítọ́ ọkàn súnmọ́ tòsí ni ẹ̀kún ìgbàgbọ́, kí a sì wẹ ọkàn wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí ọkàn búburú, kí a sì fi omi mímọ́ wẹ ara wa nù. 23 Ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mu ṣinṣin ni àìṣiyèméjì; (nítorí pé olóòtítọ́ ní ẹni tí o ṣe ìlérí). 24 Ẹ jẹ́ kí a yẹ ara wa wò láti ru ara wa sí ìfẹ́ àti sí iṣẹ́ rere: 25 kí a ma máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bi àṣà àwọn ẹlòmíràn; ṣùgbọ́n kí a máa gba ara ẹni níyànjú pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí i pé ọjọ́ náà ń súnmọ́ etílé.
26 Nítorí bí àwa ba mọ̀ ọ́n mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 27 (A)Bí kò ṣe ìrètí ìdájọ́ tí ó ba ni lẹ́rù, àti ti ìbínú ti o múná, tí yóò pa àwọn ọ̀tá run. 28 (B)Ẹnikẹ́ni tí ó ba gan òfin Mose, ó kú láìsí àánú nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta: 29 (C)Mélòó mélòó ni ẹ rò pé a o jẹ ẹni náà ní ìyà kíkan, ẹni tí o tẹ ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ tí ó sì ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ti a fi sọ ọ́ di mímọ́ si ohun àìmọ́, tí ó sì ti kẹ́gàn ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́. 30 (D)Nítorí àwa mọ ẹni tí o wí pé: Ẹ̀san ni ti èmi, Olúwa wí pé, “Èmi ó gbẹ̀san.” Àti pẹ̀lú, “Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.” 31 Ohun ẹ̀rù ni láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.
32 Ṣùgbọ́n ẹ rántí ọjọ́ ìṣáájú nínú èyí tí, nígbà tí a ti sí yin lójú, ẹ fi ara da wàhálà ńlá ti ìjìyà; 33 lápákan, nígbà tí a sọ yín di ìran wíwò nípa ẹ̀gàn àti ìpọ́njú; àti lápákan, nígbà tí ẹ̀yin di ẹgbẹ́ àwọn tí a ṣe bẹ́ẹ̀ si. 34 Nítorí ẹ̀yin bá àwọn tí ó wà nínú ìdè kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba ìkólọ ẹrù yin, nítorí ẹ̀yin mọ nínú ara yin pé, ẹ ni ọrọ̀ tí ó wà títí, tí ó sì dára jù bẹ́ẹ̀ lọ. 35 Nítorí náà ẹ má ṣe gbé ìgboyà yín sọnù, èyí ti o ni èrè ńlá.
36 Nítorí ẹ̀yin kò le ṣe aláìní sùúrù, nítorí ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tan kí ẹ̀yin le gba ìlérí náà. 37 (E)Nítorí,
“Ni ìwọ̀n ìgbà díẹ̀ sí i,
ẹni náà ti ń bọ̀ yóò dé,
kí yóò sì jáfara.
38 Ṣùgbọ́n,
“Olódodo ni yóò yè nípa ìgbàgbọ́.
Ṣùgbọ́n bí o ba fàsẹ́yìn,
ọkàn mi kò ní inú dídùn sí i.”
39 Ṣùgbọ́n àwa kò sí nínú àwọn tí ń fàsẹ́yìn sínú ègbé; bí kò ṣe nínú àwọn tí o gbàgbọ́ sí ìgbàlà ọkàn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.