Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

New Testament in a Year

Read the New Testament from start to finish, from Matthew to Revelation.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Kọrinti 7:20-40

20 Ó yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa ṣe iṣẹ́ tí ó ń ṣe tẹ́lẹ̀, kí Ọlọ́run tó pé é sínú ìgbàgbọ́ nínú Kristi.

21 Ǹjẹ́ ẹrú ni ọ́ bí nígbà ti a pè ọ́? Má ṣe kà á sí. Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá le di òmìnira, kúkú ṣe èyí nì. 22 (A)Tí ó bá jẹ́ ẹrú, ti Olúwa sì pé ọ, rántí pé Kristi ti sọ ọ́ di òmìnira kúrò lọ́wọ́ agbára búburú ti ẹ̀ṣẹ̀. Tí ó bá sì ti pé ọ̀ nítòótọ́ tí ó sì ti di òmìnira, ó ti di ẹrú Kristi. 23 (B)A sì ti rà yín ní iye kan, nítorí náà ẹ má ṣe di ẹrú ènìyàn. 24 Ará, jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn, nínú èyí tí a pè é, kí ó dúró nínú ọ̀kan náà pẹ̀lú Ọlọ́run.

Ọ̀rọ̀ nípa àwọn àpọ́n

25 Ṣùgbọ́n nípa ti àwọn wúńdíá: èmi kò ní àṣẹ kankan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n mo wí fún yín ní ìdájọ́ bí ẹni tí ó rí àánú Olúwa gbà láti jẹ́ olódodo. 26 Nítorí náà mo rò pé èyí dára nítorí wàhálà ìsinsin yìí, èyí nì ni pé o dára fún ènìyàn kí ó wà bí o ṣe wà. 27 Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹlẹ́rìí láti fẹ́ ìyàwó. Ẹ má ṣe kọ ara yín sílẹ̀, nítorí èyí tí mo wí yìí. Ṣùgbọ́n tí o kò bá sì tí ìgbéyàwó, tàbí fẹ́ ọkọ, má ṣe sáré láti ṣe bẹ́ẹ̀ lákokò yìí. 28 Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá gbé ìyàwó ìwọ kò dẹ́ṣẹ̀, bí a bá gbé wúńdíá ní ìyàwó òun kò dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó bá gbé ìyàwó yóò dojúkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà nípa ti ara: ṣùgbọ́n èmi fẹ́ dá a yín sí.

29 (C)Òun ti mo ń wí ará, ni pé kúkúrú ni àkókò, láti ìsinsin yìí lọ, ẹni tí ó ni aya kí ó dàbí ẹni tí kò ní rí; 30 àwọn tí ń sọkún, bí ẹni pé wọn kò sọkún rí, àti àwọn tí ń yọ̀ bí ẹni pé wọn kò yọ̀ rí, àti àwọn tí ń rà bí ẹni pé wọn kò ní rí, 31 àti àwọn tó ń lo ohun ayé yìí, bí ẹni tí kò ṣe àṣejù nínú wọn: nítorí ìgbà ayé yìí ń kọjá lọ.

32 (D)Nínú gbogbo nǹkan tí ẹ bá ń ṣe ni mo tí fẹ́ kí ẹ sọ ara yín di òmìnira lọ́wọ́ àníyàn. Ọkùnrin tí kò ní ìyàwó le lo àkókò rẹ̀ láti fi ṣiṣẹ́ fún Olúwa, yóò sì má ronú bí ó ti ṣe le tẹ́ Olúwa lọ́rùn. 33 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn nǹkan rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn, 34 dájúdájú, ìfẹ́ rẹ̀ pín sí ọ̀nà méjì. Bákan náà ló rí fún obìnrin tí a gbé ní ìyàwó àti wúńdíá. Obìnrin tí kò bá tí ì délé ọkọ a máa tọ́jú ohun tí ṣe ti Olúwa, kí òun lè jẹ́ mímọ́ ní ara àti ní ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin tí a bá ti gbé níyàwó, a máa ṣe ìtọ́jú ohun tí ṣe ti ayé, bí yóò ti ṣe le tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn. 35 Mo ń sọ èyí fún àǹfààní ara yín kì í ṣe láti dá yín lẹ́kun ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè gbé ní ọ̀nà tí ó tọ́ kí ẹ sì lè máa sin Olúwa láìsí ìyapa ọkàn.

36 Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun kò ṣe ohun tí ó yẹ sí wúńdíá rẹ̀ ti ìpòùngbẹ rẹ si pọ si, bí ó bá sí tọ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ó ṣe bí ó tí fẹ́, òun kò dẹ́ṣẹ̀, jẹ́ kí wọn gbé ìyàwó. 37 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni ọkàn rẹ̀, tí kò ní àìgbọdọ̀ má ṣe, ṣùgbọ́n tí ó ní agbára lórí ìfẹ́ ara rẹ̀, tí ó sì ti pinnu ní ọkàn rẹ̀ pé, òun ó pa wúńdíá ọmọbìnrin òun mọ́, yóò ṣe rere. 38 Bẹ́ẹ̀ sì ní ẹni tí ó fi wúńdíá ọmọbìnrin fún ni ní ìgbéyàwó, ó ṣe rere; ṣùgbọ́n ẹni tí kò fi fún ni ní ìgbéyàwó ṣe rere jùlọ.

39 (E)A fi òfin dé obìnrin níwọ̀n ìgbà tí òun pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ wà láààyè, bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní òmìnira láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn, tí ó bá wù ú ó sì gbọdọ̀ jẹ́ ti Olúwa. 40 (F)Ṣùgbọ́n nínú èrò tèmi obìnrin náà yóò ní ayọ̀ púpọ̀, tí kò bá ṣe ìgbéyàwó mìíràn mọ́. Mo sì rò pé mo ń fún un yín ní ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run nígbà tí mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.