New Testament in a Year
22 A sì kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ara Ejibiti, ó sì pọ̀ ni ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe.
23 (A)“Nígbà tí Mose di ọmọ ogójì ọdún, ó sọ sí i lọ́kàn láti lọ bẹ àwọn ọmọ Israẹli ará rẹ̀ wò. 24 Nígbà tí ó sì rí ọ̀kan nínú wọ́n tí ará Ejibiti kan ń jẹ́ ní ìyà, ó gbèjà rẹ̀, ó gbẹ̀san ẹni tí wọ́n jẹ ní ìyà nípa lílu ará Ejibiti náà pa: 25 Mose rò bí àwọn ará òun mọ̀ pé Ọlọ́run yóò ti ọwọ́ òun gbà wọn; ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀. 26 Ní ọjọ́ kejì Mose yọ sí àwọn ọmọ Israẹli méjì bí wọ́n ti ń jà. Òun si fẹ́ parí ìjà fún wọn. Ó wí pé, ‘Ènìyàn mi, ará ni ẹ̀yin; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ sí ara yín?’
27 “Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fínràn sí ẹnìkejì rẹ̀ ti Mose sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó wí pé, ‘Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídàájọ́ lórí wa? 28 Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ejibiti lánàá?’ 29 (B)Mose sì sá nítorí ọ̀rọ̀ yìí, ó sì wa ṣe àtìpó ni ilẹ̀ Midiani, níbi tí ó gbé bí ọmọ méjì.
30 (C)“Nígbà tí ogójì ọdún sì pé, angẹli Olúwa fi ara han Mose ní ijù, ní òkè Sinai, nínú ọ̀wọ́-iná nínú igbó. 31 Nígbà tí Mose sì rí i, ẹnu yà á sí ìran náà; nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti wò ó fín, ohùn Olúwa kọ sí i, 32 Wí pé ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu,’ Mose sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù, kò sì dáṣà láti wò ó mọ́.
33 “Olúwa sì wí fún un pé, ‘bọ́ bàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni. 34 Ní rí rí mo ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ni Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ìkérora wọn, Mo sì sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n. Wá nísinsin yìí, Èmi ó sì rán ọ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.’
35 (D)“Mose náà yìí tí wọ́n kọ̀, wí pé, ‘Ta ni ó fi jẹ olórí àti onídàájọ́?’ Òun náà ni Ọlọ́run rán lọ láti ọwọ́ angẹli, tí ó farahàn án ní pápá, láti ṣe olórí àti olùdáǹdè. 36 (E)Òun ni ó mú wọn jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ ààmì ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ni Òkun pupa, àti ni aginjù ní ogójì ọdún.
37 (F)“Èyí ni Mose náà ti ó wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde nínú àwọn ènìyàn yín.’ 38 (G)Èyí náà ni ẹni tí ó wà nínú ìjọ ní ijù pẹ̀lú angẹli náà tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sinai, àti pẹ̀lú àwọn baba wa; ẹni ti ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti fi fún wa.
39 (H)“Ṣùgbọ́n àwọn baba wa kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, àti pé nínú ọkàn wọn, wọn fẹ́ yípadà lọ sí ilẹ̀ Ejibiti; 40 (I)Wọ́n wí fún Aaroni pé, ‘Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ́nà ṣáájú wa; nítorí bí ó ṣe ti Mose yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é.’ 41 (J)Wọ́n sì yá ère ẹgbọrọ màlúù ni ọjọ́ wọ̀nyí. Wọ́n sì rú ẹbọ sí ère náà, wọ́n sì ń yọ̀ nínú ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. 42 Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run: òòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé:
“ ‘Ẹ̀yin ha mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún mi
ní ogójì ọdún ní ijù bí, ìwọ ilé Israẹli?
43 Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gbà àgọ́ Moleki,
àti ìràwọ̀ Refani òrìṣà yín,
àwòrán tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ wọ́n.
Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Babeli.’
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.