New Testament in a Year
Ní Ateni
16 Nígbà tí Paulu dúró dè wọ́n ni Ateni, ẹ̀mí rẹ̀ ru nínú rẹ̀, nígbà tí ó rí pé ìlú náà kún fún òrìṣà. 17 Nítorí náà ó ń bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú Sinagọgu, àti àwọn olùfọkànsìn, àti àwọn tí ó ń bá pàdé lọ́jà lójoojúmọ́. 18 Nínú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Epikure ni àti tí àwọn Stoiki kó tì í. Àwọn kan si ń wí pé, “Kín ni aláhesọ yìí yóò rí wí?” Àwọn mìíràn sì wí pé, “Ó dàbí oníwàásù àjèjì òrìṣà, Wọ́n sọ èyí nítorí Paulu ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu àti àjíǹde fún wọn.” 19 Wọ́n sì mú un, wọ́n sì fà á lọ sí Areopagu, wọ́n wí pé, “A ha lè mọ̀ kín ni ẹ̀kọ́ tuntun tí ìwọ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́? 20 Nítorí tí ìwọ mú ohun àjèjì wá sí etí wa: àwa sì ń fẹ́ mọ̀ kín ni ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí.” 21 Nítorí gbogbo àwọn ará Ateni, àti àwọn àjèjì tí ń ṣe àtìpó níbẹ̀ kì í ṣe ohun mìíràn jù kí a máa sọ tàbí kí a máa gbọ́ ohun tuntun lọ.
22 Paulu si dìde dúró láàrín Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Ateni, mo wòye pé ní ohun gbogbo ẹ kún fún ẹ̀sìn lọ́pọ̀lọpọ̀. 23 Nítorí bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo wo àwọn ohun tí ẹ̀yin ń sìn, mo sì rí pẹpẹ kan tí a kọ àkọlé yìí sí:
fún ọlọ́run àìmọ̀.
Ǹjẹ́ ẹni tí ẹ̀yin ń sìn ni àìmọ̀ òun náà ni èmi ń sọ fún yin.
24 (A)“Ọlọ́run náà tí ó dá ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òun náà tí í ṣe Olúwa ọ̀run àti ayé, kì í gbé tẹmpili tí a fi ọwọ́ kọ́; 25 Bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ènìyàn sìn ín, bí ẹni pé ó ń fẹ́ nǹkan, òun ni ó fi ìyè àti èémí àti ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn. 26 Ó sì tí tipasẹ̀ ẹnìkan dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé, ó sì ti pinnu àkókò tí a yàn tẹ́lẹ̀, àti ààlà ibùgbé wọn; 27 Ọlọ́run ṣe eléyìí kí wọn bá le máa wa, bóyá wọn yóò lè ṣàfẹ́rí rẹ̀, kí wọn sì rí í. Bí ó tilẹ̀ jẹ pé kò jìnnà sí olúkúlùkù wa: 28 Nítorí nínú rẹ̀ ni àwa wà láààyè, tí a ń rìn kiri, tí a sì ní ẹ̀mí wa: bí àwọn kan nínú àwọn akéwì tí ẹ̀yin tìkára yín tí wí pé, ‘Àwa pẹ̀lú sì jẹ́ ọmọ rẹ̀.’
29 “Ǹjẹ́ bí àwa bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, kò yẹ fún wa láti rò pé, ẹni tí a wa n sìn dàbí wúrà, tàbí fàdákà, tàbí òkúta, tí a fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ ènìyàn ya ère àwòrán rẹ̀. 30 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìgbà àìmọ̀ yìí ni Ọlọ́run tí fojú fò dá; ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ronúpìwàdà; 31 Níwọ́n bí ó ti dá ọjọ́ kan, nínú èyí tí yóò ṣe ìdájọ́ ayé lódodo nípasẹ̀ ọkùnrin náà tí ó ti yàn, nígbà tí ó ti fi ohun ìdánilójú fún gbogbo ènìyàn, ní ti pé ó jí dìde kúrò nínú òkú.”
32 Nígbà tí wọ́n ti gbọ́ ti àjíǹde òkú, àwọn mìíràn ń ṣẹ̀fẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn mìíràn wí pé, “Àwa o tún nǹkan yìí gbọ́ lẹ́nu rẹ̀.” 33 Bẹ́ẹ̀ ni Paulu sì jáde kúrò láàrín wọn. 34 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin kan fi ara mọ́ ọn, wọ́n sì gbàgbọ́: nínú àwọn ẹni tí Dionisiu ara Areopagu wà, àti obìnrin kan tí a ń pè ni Damari àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.