Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Deuteronomi 33-34

Mose bùkún fún àwọn ẹ̀yà

33 Èyí ni ìbùkún tí Mose ènìyàn Ọlọ́run bùkún fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú. Ó sì wí pé:

Olúwa ti Sinai wá,
    ó sì yọ sí wọn láti Seiri wá
    ó sì tàn án jáde láti òkè Parani wá.
Ó ti ọ̀dọ̀ ẹgbẹgbàarùn-ún àwọn mímọ́ wá
    láti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni òfin kan a mú bí iná ti jáde fún wọn wá.
Nítòótọ́, ó fẹ́ràn àwọn ènìyàn an rẹ̀,
    gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ wà ní ọwọ́ rẹ̀.
Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti foríbalẹ̀,
    àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀,
òfin tí Mose fi fún wa,
    ìní ti ìjọ ènìyàn Jakọbu.
Òun ni ọba lórí Jeṣuruni
    ní ìgbà tí olórí àwọn ènìyàn péjọpọ̀,
    pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Israẹli.

“Jẹ́ kí Reubeni yè kí ó má ṣe kú,
    tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n.”

Èyí ni ohun tí ó sọ nípa Juda:

Olúwa gbọ́ ohùn Juda
    kí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá.
Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un,
    kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀!”

Ní ti Lefi ó wí pé:

“Jẹ́ kí Tumimu àti Urimu rẹ kí ó wà
    pẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ.
Ẹni tí ó dánwò ní Massa,
    ìwọ bá jà ní omi Meriba.
Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé,
    ‘Èmi kò buyì fún wọn.’
Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀,
    tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀,
ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀,
    ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.
10 Ó kọ́ Jakọbu ní ìdájọ́ rẹ̀
    àti Israẹli ní òfin rẹ̀.
Ó mú tùràrí wá síwájú rẹ̀
    àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀.
11 Bùsi ohun ìní rẹ̀, Olúwa,
    kí o sì tẹ́wọ́gbà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i;
    àwọn tí ó kórìíra rẹ̀,
    kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.”

12 Ní ti Benjamini ó wí pé:

“Jẹ́ kí olùfẹ́ Olúwa máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀,
    òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́,
    ẹni tí Olúwa fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrín èjìká rẹ̀.”

13 Ní ti Josẹfu ó wí pé:

“Kí Olúwa bùkún ilẹ̀ rẹ,
    fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrì
    àti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀;
14 àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wá
    àti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù;
15 pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanì
    àti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé;
16 Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀
    àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó.
Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Josẹfu,
    lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀.
17 Ní ọláńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù;
    ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni.
Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀-èdè,
    pàápàá títí dé òpin ayé.
Àwọn ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún (10,000) Efraimu,
    àwọn sì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún (1,000) Manase.”

18 Ní ti Sebuluni ó wí pé:

“Yọ̀ Sebuluni, ní ti ìjáde lọ rẹ,
    àti ìwọ Isakari, nínú àgọ́ rẹ.
19 Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkè
    àti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo,
wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òkun,
    nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.”

20 Ní ti Gadi ó wí pé:

“Ìbùkún ni ẹni tí ó mú Gadi gbilẹ̀!
    Gadi ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún,
    ó sì fa apá ya, àní àtàrí.
21 Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀;
    ìpín olórí ni a sì fi fún un.
Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ,
    ó mú òdodo Olúwa ṣẹ,
    àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli.”

22 Ní ti Dani ó wí pé:

“Ọmọ kìnnìún ni Dani,
    tí ń fò láti Baṣani wá.”

23 Ní ti Naftali ó wí pé:

“Ìwọ Naftali, kún fún ojúrere Ọlọ́run
    àti ìbùkún Olúwa;
    yóò jogún ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gúúsù.”

24 Ní ti Aṣeri ó wí pé:

“Ìbùkún ọmọ ni ti Aṣeri;
    jẹ́ kí ó rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀
    kí ó sì ri ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú òróró.
25 Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ,
    agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀.

26 “Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jeṣuruni,
    ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ
    àti ní ojú ọ̀run nínú ọláńlá rẹ̀.
27 Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ,
    àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà.
Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ,
    ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!’
28 Israẹli nìkan yóò jókòó ní àlàáfíà,
    orísun Jakọbu nìkan
ní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì,
    níbi tí ọ̀run ti ń sẹ ìrì sílẹ̀.
29 Ìbùkún ni fún ọ, Israẹli,
    ta ni ó dàbí rẹ,
    ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ Olúwa?
Òun ni asà àti ìrànwọ́ rẹ̀
    àti idà ọláńlá rẹ̀.
Àwọn ọ̀tá rẹ yóò tẹríba fún ọ,
    ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”

Ikú Mose

34 Nígbà náà ni Mose gun òkè Nebo láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu sí orí Pisga tí ó dojúkọ Jeriko. Níbẹ̀ ni Olúwa ti fi gbogbo ilẹ̀ hàn án láti Gileadi dé Dani, gbogbo Naftali, ilẹ̀ Efraimu àti Manase, gbogbo ilẹ̀ Juda títí dé Òkun ìwọ̀-oòrùn, gúúsù àti gbogbo Àfonífojì Jeriko, ìlú ọlọ́pẹ dé Soari. Nígbà náà ní Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí mo ṣèlérí lórí ìbúra fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu nígbà tí mo wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú-ọmọ rẹ.’ Mo ti jẹ́ kí o rí i pẹ̀lú ojú rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò dé bẹ̀.”

Bẹ́ẹ̀ ni Mose ìránṣẹ́ Olúwa kú ní ilẹ̀ Moabu, bí Olúwa ti wí. Ó sì sin ín nínú àfonífojì ní ilẹ̀ Moabu, ní òdìkejì Beti-Peori, ṣùgbọ́n títí di òní yìí, kò sí ẹnìkan tí ó mọ ibi tí ibojì i rẹ̀ wà. Mose jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún nígbà tí ó kú, síbẹ̀ ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù. Àwọn ọmọ Israẹli sọkún un Mose ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ọgbọ̀n ọjọ́ títí di ìgbà tí ọjọ́ ẹkún àti ọ̀fọ̀ Mose parí.

Joṣua ọmọ Nuni kún fún ẹ̀mí ọgbọ́n nítorí Mose ti gbọ́wọ́ ọ rẹ̀ lé e lórí. Àwọn ọmọ Israẹli sì fetí sí i wọ́n sì ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Mose.

10 (A)Láti ìgbà náà kò sì sí wòlíì tí ó dìde ní Israẹli bí i Mose, ẹni tí Olúwa mọ̀ lójúkojú, 11 tí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu tí Olúwa rán an láti lọ ṣe ní Ejibiti sí Farao àti sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ àti sí gbogbo ilẹ̀ náà. 12 Nítorí kò sí ẹni tí ó tí ì fi gbogbo ọ̀rọ̀ agbára hàn, tàbí ṣe gbogbo ẹ̀rù ńlá tí Mose fihàn ní ojú gbogbo Israẹli.

Saamu 119:145-176

Kíkígbe fún ìgbàlà

145 Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
    dá mi lóhùn Olúwa,
    èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
146 Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí
    èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́.
147 Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́;
    èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
148 Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru,
    nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.
149 Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ:
    pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
150 Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòsí,
    ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.
151 Síbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa,
    àti gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òtítọ́.
152 Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin rẹ
    tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.

Pípa òfin mọ́ ni ìpọ́njú

153 Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí,
    nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ.
154 Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà;
    pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
155 Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú
    nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ.
156 Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, Olúwa;
    pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
157 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi,
    ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ.
158 Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́
    nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́.
159 Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ;
    pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ.
160 Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ;
    gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.
161 Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí,
    ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ.
162 Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ
    bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.
163 Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe
    ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ.
164 Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́
    nítorí òfin òdodo rẹ.
165 Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ,
    kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.
166 Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, Olúwa,
    èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ.
167 Èmi gba òfin rẹ gbọ́,
    nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀
168 Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ,
    nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.
169 Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, Olúwa;
    fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
170 Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ;
    gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
171 Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde,
    nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
172 Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ,
    nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.
173 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́,
    nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ.
174 Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, Olúwa,
    àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi.
175 Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́,
    kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró.
176 Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó
    sọnù, wá ìránṣẹ́ rẹ,
    nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.

Isaiah 60

Ògo Sioni

60 “Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,
    ògo Olúwa sì ràdàbò ọ́.
Kíyèsi i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayé
    òkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn,
ṣùgbọ́n Olúwa ràn bò ọ́
    ògo rẹ̀ sì farahàn lórí i rẹ.
Àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ,
    àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ.

“Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò:
    Gbogbo wọn ṣa ara jọ pọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ;
àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò wá láti ọ̀nà jíjìn,
    àwọn ọmọ rẹ obìnrin ni a ó tọ́jú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ.
Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán,
    ọkàn rẹ yó fò, yó sì kún fún ayọ̀;
ọrọ̀ inú Òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ,
    sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá.
(A)Ọ̀wọ́ ìbákasẹ yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ,
    àwọn ọ̀dọ́ ìbákasẹ Midiani àti Efani.
Àti gbogbo wọn láti Ṣeba yóò wá,
    wọn yóò mú wúrà àti tùràrí lọ́wọ́
    tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn Olúwa.
Gbogbo agbo ẹran Kedari ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ,
    àwọn àgbò ti Nebaioti yóò sìn ọ́;
wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi,
    bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹmpili ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́.

“Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kurukuru,
    gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn?
Lóòtítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí;
    ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;
mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn,
    pẹ̀lú fàdákà àti wúrà wọn,
fún ti ọlá Olúwa Ọlọ́run rẹ,
    Ẹni Mímọ́ Israẹli,
    nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́.

10 “Àwọn àjèjì yóò tún ògiri rẹ mọ
    àwọn ọba wọn yóò sì sìn ọ́.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ìbínú ni mo lù ọ́,
    ní àánú èmi yóò ṣe inú rere sí ọ.
11 (B)Gbogbo ẹnu-bodè rẹ ni yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀,
    a kì yóò tì wọ́n ní ọ̀sán àti ní òru,
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yóò le è kó
    ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá
tí àwọn ọba wọn yóò ṣáájú ní
    ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ìṣẹ́gun.
12 Nítorí pé orílẹ̀-èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun;
    pátápátá ni yóò sì dahoro.

13 “Ògo Lebanoni yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,
    igi junifa, firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀,
láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi;
    àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo.
14 (C)Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóò
    wá foríbalẹ̀ fún ọ;
gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹ
    wọn yóò sì pè ọ́ ní ìlú Olúwa,
    Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.

15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kórìíra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
    láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá,
Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayé
    àti ayọ̀ àtìrandíran.
16 Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀-èdè
    a ó sì fun ọ́ ni ọmú àwọn ọba.
Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi Olúwa,
    èmi ni Olùgbàlà rẹ,
    Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jakọbu.
17 Dípò idẹ, èmi ó mú wúrà wá fún ọ,
    dípò fàdákà èmi ó mú irin wá. Dípò igi yóò mú idẹ wá fún ọ,
àti irin dípò òkúta.
    Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe àwọn ìjòyè rẹ
    àti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ.
18 A kì yóò gbọ́ nípa rògbòdìyàn ní ilẹ̀ rẹ mọ́,
    tàbí ìdahoro àti ìparun nínú agbègbè rẹ,
ṣùgbọ́n ìwọ yóò pe ògiri rẹ ní ìgbàlà
    àti àwọn ẹnu-bodè rẹ ní ìyìn.
19 Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́,
    tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́,
nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé,
    àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ.
20 Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́,
    àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́;
Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ,
    àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin.
21 Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodo
    àwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé.
Àwọn ni irúgbìn tí mo ti gbìn,
    iṣẹ́ ọwọ́ mi,
    láti fi ọláńlá mi hàn.
22 Èyí tí ó kéré jù nínú yín yóò di ẹgbẹ̀rún kan,
    èyí tí ó kéré yóò di orílẹ̀-èdè ńlá.
Èmi ni Olúwa;
    ní àkókò rẹ̀ Èmi yóò ṣe èyí kánkán.”

Matiu 8

Ọkùnrin adẹ́tẹ̀

Nígbà tí ó ti orí òkè sọ̀kalẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. (A)(B)Sì wò ó, adẹ́tẹ̀ kan wà, ó wá ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ ó wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mi di mímọ́.”

Jesu sì nà ọwọ́ rẹ̀, ó fi bà á, ó wí pé, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́.” Lójúkan náà, ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sì mọ́! (C)Jesu sì wí fún pé, “Wò ó, má ṣe sọ fún ẹnìkan. Ṣùgbọ́n máa ba ọ̀nà rẹ̀ lọ, fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí o sì san ẹ̀bùn tí Mose pàṣẹ ní ẹ̀rí fún wọn.”

Ìgbàgbọ́ balógun ọ̀rún

(D)Nígbà tí Jesu sì wọ̀ Kapernaumu, balógun ọ̀rún kan tọ̀ ọ́ wá, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. O sì wí pé, “Olúwa, ọmọ ọ̀dọ̀ mi dùbúlẹ̀ ààrùn ẹ̀gbà ni ilé, tòun ti ìrora ńlá.”

Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ń bọ̀ wá mú un láradá.”

Balógun ọ̀rún náà dáhùn, ó wí pé, “Olúwa, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ń wọ̀ abẹ́ òrùlé rẹ̀, ṣùgbọ́n sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá. Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹni kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”

10 Nígbà tí Jesu gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Israẹli tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí. 11 Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Abrahamu àti Isaaki àti Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run. 12 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìjọba ni a ó sọ sínú òkùnkùn lóde, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.”

13 Nítorí náà Jesu sì wí fún balógun ọ̀run náà pé, “Máa lọ ilé, ohun tí ìwọ gbàgbọ́ ti rí bẹ́ẹ̀.” A sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ náà láradá ní wákàtí kan náà.

Jesu wo ọ̀pọ̀ aláìsàn sàn

14 (E)Nígbà tí Jesu sì dé ilé Peteru, ìyá ìyàwó Peteru dùbúlẹ̀ àìsàn ibà. 15 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu fi ọwọ́ kan ọwọ́ rẹ̀, ibà náà fi í sílẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì dìde ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

16 Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde. A sì mú gbogbo àwọn ọlọ́kùnrùn láradá. 17 (F)Kí èyí tí a ti sọ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé:

“Òun tìkára rẹ̀ gbà àìlera wa,
    ó sì ń ru ààrùn wa.”

Ohun tí o gbà láti tẹ̀lé Jesu

18 (G)Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó yí i ká, ó pàṣẹ pé kí wọ́n rékọjá sí òdìkejì adágún. 19 Olùkọ́ òfin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí fún un pé, “Olùkọ́, èmi ó má tọ̀ ọ́ lẹ́yìn níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

20 Jesu dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”

21 Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mìíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, kọ́kọ́ jẹ́ kí èmi kí ó kọ́ lọ sìnkú baba mi ná.”

22 (H)Ṣùgbọ́n Jesu wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn, sì jẹ́ kí àwọn òkú kí ó máa sin òkú ara wọn.”

Jesu dá ìjì líle dúró

23 (I)Nígbà náà ni ó bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e. 24 Ní àìròtẹ́lẹ̀, ìjì líle dìde lórí Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí rírú omi fi bò ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n Jesu ń sùn. 25 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn jí i, wọ́n wí pe, “Olúwa, gbà wá! Àwa yóò rì!”

26 (J)Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bẹ̀rù?” Nígbà náà ní ó dìde dúró, ó sì bá ìjì àti rírú Òkun náà wí, gbogbo rẹ̀ sì parọ́rọ́.

27 Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? Kódà ìjì líle àti rírú omi Òkun gbọ́ tirẹ̀?”

Ìwòsàn ọkùnrin ẹlẹ́mìí èṣù méjì

28 (K)Nígbà ti ó sì dé apá kejì ní ilẹ̀ àwọn ara Gadara, àwọn ọkùnrin méjì ẹlẹ́mìí èṣù ti inú ibojì wá pàdé rẹ̀. Wọn rorò gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò le kọjá ní ọ̀nà ibẹ̀. 29 (L)Wọ́n kígbe lóhùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tàwa tìrẹ, Ìwọ Ọmọ Ọlọ́run? Ìwọ ha wá láti dá wa lóró ṣáájú ọjọ́ tí a yàn náà?”

30 Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá tí ń jẹ ń bẹ ní ọ̀nà jíjìn díẹ̀ sí wọn 31 Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bẹ̀ Jesu wí pé, “Bí ìwọ bá lé wa jáde, jẹ́ kí àwa kí ó lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ yìí.”

32 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ!” Nígbà tí wọn sì jáde, wọn lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà; sì wò ó, gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà sì rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ bèbè odò bọ́ sínú Òkun, wọ́n sì ṣègbé nínú omi. 33 Àwọn ẹni tí ń ṣọ wọn sì sá, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n lọ sí ìlú, wọ́n ròyìn ohun gbogbo, àti ohun tí a ṣe fún àwọn ẹlẹ́mìí èṣù. 34 Nígbà náà ni gbogbo ará ìlú náà sì jáde wá í pàdé Jesu. Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́, kí ó lọ kúrò ní agbègbè wọn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.