Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Deuteronomi 1

Àṣẹ láti jáde kúrò ní Horebu

Wọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Mose sọ fún gbogbo Israẹli ní aginjù, aginjù ìlà-oòrùn Jordani, ni Arabah: ní òdìkejì Ṣufi, ní àárín Parani àti Tofeli, Labani, Haserotu àti Disahabu. (Ọjọ́ mọ́kànlá ni ó gbà láti rin ìrìnàjò láti Horebu dé Kadeṣi-Barnea, bí a bá gba ọ̀nà òkè Seiri.)

Ní ìgbà tí ó pé ogójì ọdún, ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kọ́kànlá, Mose sọ ohun gbogbo tí Ọlọ́run pàṣẹ nípa àwọn ọmọ Israẹli fún wọn. Èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣẹ́gun Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni, àti Ogu ọba Baṣani ni ó ṣẹ́gun ní Edrei, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu.

Ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani tí ó wà nínú ilẹ̀ Moabu ni Mose bẹ̀rẹ̀ sísọ àsọyé òfin wọ̀nyí wí pé:

Olúwa Ọlọ́run wa bá wa sọ̀rọ̀ ní Horebu pé, “Ẹ ti dúró ní orí òkè yìí pẹ́ tó. Ẹ yípadà kí ẹ sì tẹ̀síwájú ní ìrìnàjò yín lọ sí ilẹ̀ òkè àwọn ará Amori: Ẹ tọ gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń gbé Arabah lọ ní aginjù, ní àwọn orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní gúúsù àti ní etí Òkun, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani àti lọ sí Lebanoni, títí fi dé odò ńlá Eufurate. Wò ó, èmi tí fi ilẹ̀ yí fún un yín: Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí Olúwa ti búra wí pé òun yóò fún àwọn baba yín: fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu, àti fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn.”

Yíyan àwọn olórí

(A)Mo wí fún un yín nígbà náà pé, “Èmi nìkan kò lè dá ẹrù u yín gbé. 10 Olúwa Ọlọ́run yín ti sọ yín di púpọ̀ lónìí, ẹ̀yin sì ti pọ̀ bí ìràwọ̀ ní ojú ọ̀run. 11 Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín sọ yín di púpọ̀ ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún sí i, kí ó sì bùkún un yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí. 12 Báwo ni èmi nìkan ṣe lè máa ru àjàgà àti ìṣòro yín àti èdè-àìyedè yín? 13 Ẹ yan àwọn ọlọ́gbọ́n, olóye àti àwọn ẹni àpọ́nlé, láti inú ẹ̀yà yín kọ̀ọ̀kan, èmi yóò sì fi wọ́n ṣe olórí yín.”

14 Ẹ̀yin sì dá mi lóhùn wí pé, “Ohun tí ìwọ ti gbèrò láti ṣe nì dára.”

15 Bẹ́ẹ̀ ni mo yan olórí àwọn ẹ̀yà yín, àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin, ẹni àpọ́nlé, mo sì fi jẹ olórí yín: olórí ẹgbẹẹ̀rún, olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, àti olórí mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀yà yín. 16 (B)Mo sì kìlọ̀ fún àwọn onídàájọ́ yín nígbà náà pé: Ẹ gbọ́ èdè-àìyedè tí ó wà láàrín àwọn ènìyàn an yín kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ òdodo, bóyá ẹjọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ láàrín Israẹli sí Israẹli ni tàbí láàrín Israẹli kan sí àlejò. 17 Ẹ má sì ṣe ojúsàájú ní ìdájọ́: Ẹ ṣe ìdájọ́ ẹni ńlá àti kékeré bákan náà. Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹnikẹ́ni torí pé ti Ọlọ́run ni ìdájọ́. Ẹjọ́ tí ó bá le jù fún un yín ni kí ẹ mú wá fún mi. Èmi yóò sì gbọ́ ọ. 18 Nígbà náà ni èmi yóò sọ ohun tí ẹ ó ṣe fún un yín.

A rán àwọn Ayọ́lẹ̀wò jáde

19 Nígbà náà ní a gbéra láti Horebu, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún wá, a sì la àwọn ilẹ̀ lókè Amori kọjá lọ dé gbogbo aginjù ńlá tí ó ba ni lẹ́rù nì tí ẹ̀yin ti rí, bẹ́ẹ̀ ni a sì dé Kadeṣi-Barnea. 20 Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, “Ẹ ti dé ilẹ̀ òkè àwọn ará Amori, èyí tí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa. 21 Ẹ kíyèsi i, Olúwa Ọlọ́run yín ló ni ilẹ̀ náà. Ẹ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín tí sọ fún un yín. Ẹ má bẹ̀rù, Ẹ má sì ṣe fòyà.”

22 (C)Nígbà náà ni gbogbo yín tọ̀ mí wá wí pé, “Jẹ́ kí a yan àwọn ayọ́lẹ̀wò láti yọ́ ilẹ̀ náà wò fún wa, kí wọn sì fún wa ní ìròyìn àwọn ọ̀nà tí a ó gbà àti àwọn ìlú tí a ó bá pàdé.”

23 Èrò náà sì dára lójú mi, torí èyí ni mo ṣe yan àwọn ènìyàn méjìlá nínú yín, ẹnìkan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. 24 Wọ́n sì gòkè lọ sí ilẹ̀ òkè náà, wọ́n sì wá sí Àfonífojì Eṣkolu, wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò. 25 Wọ́n sì mú lára èso ilẹ̀ náà wá fún wa pé, “Ilẹ̀ tí ó dára ni Olúwa Ọlọ́run wa fún wa.”

Ìṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa

26 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́ gòkè lọ; ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run yín. 27 Ẹ kùn nínú àgọ́ ọ yín, ẹ sì wí pé, “Olúwa kórìíra wa, torí èyí ló fi mú wa jáde láti Ejibiti láti fi wá lé àwọn ará Amori lọ́wọ́ láti pa wá run. 28 Níbo la ó lọ? Àwọn arákùnrin wa ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa nípa sísọ pé, ‘Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga jù wá lọ; àwọn ìlú náà tóbi jọjọ bẹ́ẹ̀ ni odi wọn ga kan ọ̀run. A tilẹ̀ rí àwọn òmíràn (ìran Anaki) níbẹ̀.’ ”

29 Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, “Ẹ má ṣojo, ẹ kò sì gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn. 30 Olúwa Ọlọ́run yín, tí ń ṣáájú yín yóò jà fún un yín; bí ó ti ṣe fún un yín ní Ejibiti lójú ẹ̀yin tìkára yín 31 (D)àti ní aginjù. Níbẹ̀ ni ẹ ti rí i bí Olúwa Ọlọ́run yín ti gbé yín, bí baba ti í gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ lọ títí ẹ fi padà dé ibí yìí.”

32 Pẹ̀lú gbogbo èyí tí mo wí, ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run yín, 33 tí ń ṣáájú u yín lọ ní gbogbo ọ̀nà yín, nípa fífi iná ṣe amọ̀nà yín ní òru àti ìkùùkuu ní ọ̀sán, láti fi àwọn ibi tí ẹ lè tẹ̀dó sí hàn yín àti àwọn ọ̀nà tí ẹ ó rìn.

34 Nígbà tí Olúwa gbọ́ ohun tí ẹ sọ, inú bí i, ó sì búra wí pé: 35 “Kò sí ọ̀kan nínú ìran búburú yìí tí yóò dé ilẹ̀ rere tí mo ti búra láti fún àwọn baba ńlá a yín. 36 Bí kò ṣe Kalebu ọmọ Jefunne. Òun ni yóò wọ̀ ọ́. Èmi yóò sì fún òun àti àwọn ìran rẹ̀ ní ilẹ̀ náà tí ó ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ̀; torí pé ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀lé Olúwa.”

37 Torí i tiyín ni Olúwa fi bínú sí mi wí pé, “Ìwọ náà kì yóò wọ ibẹ̀ bákan náà, 38 ṣùgbọ́n Joṣua ọmọ Nuni tí ń ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ ni yóò wọ ibẹ̀. Mú un, ní ọkàn le torí pé, òun yóò ṣáájú àwọn ọmọ Israẹli láti gba ilẹ̀ náà. 39 Àwọn èwe yín tí ẹ sọ pé wọn yóò kó lẹ́rú. Àwọn ọmọ yín tí ko tí ì mọ rere yàtọ̀ sí búburú ni yóò wọ ilẹ̀ náà. 40 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, ẹ yí padà sí aginjù tí ó wà ní ọ̀nà tí ó lọ sí Òkun pupa.”

41 Nígbà náà ni ẹ fèsì wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí Olúwa. A ó sì gòkè lọ láti jà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún wa.” Torí náà gbogbo yín ẹ mú ohun ìjà a yín, ẹ rò pé ó rọrùn láti gòkè lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè olókè náà.

42 Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún mi pé, “Sọ fún wọn, ‘Ẹ má ṣe gòkè lọ láti jà torí pé èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín. Àwọn ọ̀tá a yín yóò sì ṣẹ́gun yín.’ ”

43 Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbọ́, ẹ̀yin ṣọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa, pẹ̀lú ìgbéraga yín, ẹ gòkè lọ sí ìlú olókè náà. 44 Àwọn ará Amori tí ń gbé ní àwọn òkè náà, dojúkọ yín bí àgbájọpọ̀ oyin. Wọ́n sì lù yín bolẹ̀ láti Seiri títí dé Horma. 45 Ẹ padà, ẹ sì sọkún níwájú Olúwa, òun kò sì fetí sí igbe ẹkún yín, Ó sì kọ etí dídi sí i yín. 46 Báyìí ni ẹ sì dúró ní Kadeṣi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ṣe.

Saamu 81-82

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu.

81 Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa
    Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!
Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá,
    tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.

Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun
    àní nígbà tí a yàn;
ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.
Èyí ni àṣẹ fún Israẹli,
    àti òfin Ọlọ́run Jakọbu.
Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu
    nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já.

    Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.

Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín,
    a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.
Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,
    mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá,
    mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela.

“Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,
    bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli.
Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín;
    ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.
10 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
    ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.
    Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.

11 “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;
    Israẹli kò ní tẹríba fún mi.
12 Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn
    láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.

13 “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi
    bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,
14 Ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn
    kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!
15 Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú rẹ̀.
    Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé
16 Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín
    èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”

Saamu ti Asafu.

82 Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,
    ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.

“Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodo
    kí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú?
Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;
    ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.
Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;
    gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.

“Wọn kò mọ̀ ohun kankan,
    wọn kò lóye ohun kankan.
Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn;
    à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.

(A)“Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”;
    ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán;
    ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.”

Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,
    nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.

Isaiah 29

Ègbé ni fún ìlú Dafidi

29 Ègbé ni fún ọ, Arieli, Arieli,
    ìlú níbi tí Dafidi tẹ̀dó sí!
Fi ọdún kún ọdún
    sì jẹ́ kí àwọn àkọlùkọgbà àjọ̀dún un rẹ tẹ̀síwájú.
Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yóò dó ti Arieli
    òun yóò ṣọ̀fọ̀ yóò sì sọkún,
    òun yóò sì dàbí pẹpẹ ọkàn sí mi.
Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo;
    Èmi yóò sì fi ilé ìṣọ́ yí ọ ká:
    èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdó ti ni mi dojúkọ ọ́.
Ní ìrẹ̀sílẹ̀, ìwọ ó sì máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá;
    ọ̀rọ̀ rẹ yóò sì máa kùn jáde láti inú erùpẹ̀.
Ohun rẹ yóò máa jáde bí i ti ẹnìkan tó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ láti ilẹ̀ jáde wá,
    láti inú erùpẹ̀ ni ohùn rẹ
    yóò máa wá wúyẹ́wúyẹ́.

Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná,
    agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù.
    Lójijì, ní ìṣẹ́jú kan,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò wá
    pẹ̀lú àrá, ilẹ̀-rírì àti ariwo ńlá
àti ẹ̀fúùfù líle àti iná ajónirun
    Lẹ́yìn náà,
    ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó bá Arieli jà,
tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódi rẹ̀
    tí ó sì dó tì í,
yóò dàbí ẹni pé nínú àlá,
    bí ìran ní òru
àti bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa ń lá àlá pé òun ń jẹun,
    ṣùgbọ́n ó jí, ebi rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀;
tàbí bí ìgbà tí ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mu omi,
    ṣùgbọ́n nígbà tí ó jí, sì wò ó, ó dákú, òǹgbẹ sì ń gbẹ ọkàn rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè
    tí ń bá òkè Sioni jà.

Ẹ bẹ̀rù kí ẹnu kí ó yà yín,
    ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ má sì ríran;
ẹ mutí yó kì í ṣe ọtí wáìnì,
    ẹ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n, ṣùgbọ́n kì í ṣe ti ọtí líle.
10 Olúwa ti mú oorun ìjìká wá sórí i yín:
    ó ti dì yín lójú ẹ̀yin wòlíì;
    ó ti bo orí yín ẹ̀yin aríran.

11 Fún un yín gbogbo ìran yìí kò yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi èdìdì dì sínú ìwé kíká. Bí ẹ bá sì fún ẹni tí ó lè ka ìwé kíká náà, tí ẹ sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò lè kà á; a ti dì í ní èdìdì.” 12 Tàbí bí ẹ bá fún ẹni tí kò lè ka ìwé kíká náà tí ẹ sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n kà.”

13 (A)Olúwa wí pé:

“Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọn,
    wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn,
ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi.
    Ìsìn wọn si mi
ni a gbé ka orí òfin tí àwọn
    ọkùnrin kọ́ ni.
14 (B)Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya
    àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu
pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu;
    ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé,
    ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.”
15 Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun
    láti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa,
tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùn
    tí wọ́n sì rò pé,
    “Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?”
16 (C)Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀,
    bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀!
Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé
    “Òun kọ́ ló ṣe mí”?
Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé,
    “kò mọ nǹkan”?

17 Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́
    a kò ní sọ Lebanoni di pápá ẹlẹ́tù lójú
    àti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí aginjù?
18 (D)Ní ọjọ́ náà adití yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé kíká náà,
    láti inú fìrífìrí àti òkùnkùn
    ni àwọn ojú afọ́jú yóò ríran.
19 Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú Olúwa:
    àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
20 Aláìláàánú yóò pòórá,
    àwọn tí ń ṣẹlẹ́yà yóò di àwátì,
    gbogbo àwọn tí ó ní ojú ibi ni a ó ké lulẹ̀—
21 àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi,
    ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní ilé ẹjọ́
    tí ẹ fi ẹ̀rí èké dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́.

22 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa, ẹni tí ó ra Abrahamu padà sọ sí ilé Jakọbu:

    “Ojú kì yóò ti Jakọbu mọ́;
    ojú wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́.
23 Nígbà tí wọ́n bá rí i láàrín àwọn ọmọ wọn,
    àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi,
wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́,
    wọn yóò tẹ́wọ́gbà mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jakọbu
    wọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Israẹli.
24 Gbogbo àwọn tí ń rìn ségesège ní yóò jèrè ìmọ̀;
    gbogbo àwọn tí ń ṣe àròyé yóò gba ìtọ́sọ́nà.”

3 Johanu

(A)Alàgbà,

Sì Gaiusi, olùfẹ́, ẹni tí mo fẹ́ nínú òtítọ́.

Olùfẹ́, èmi ń gbàdúrà pé nínú ohun gbogbo kí o lè máa dára fún ọ, kí o sì máa wà ni ìlera, àní bí o tí dára fún ọkàn rẹ. Nítorí mo yọ̀ gidigidi, nígbà tí àwọn arákùnrin dé tí wọn sì jẹ́rìí sí ìwà òtítọ́ inú rẹ̀, àní bí ìwọ tí ń rìn nínú òtítọ́. Èmi ni ayọ̀ tí ó tayọ, láti máa gbọ́ pé, àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.

Olùfẹ́, ìwọ ń ṣe olóòtítọ́ nínú iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún àwọn tí ń ṣe ará, àti pàápàá fún àwọn tí ń ṣe àlejò. Tí wọn ń jẹ́rìí sí ìfẹ́ rẹ̀ níwájú ìjọ: bí ìwọ bá ń pèsè fún wọn ní ọ̀nà àjò wọn gẹ́gẹ́ bí ó tí yẹ nínú Ọlọ́run. Nítorí pé, nítorí iṣẹ́ Kristi ni wọ́n ṣe jáde lọ, láìgba ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn aláìkọlà. Nítorí náà, ó yẹ kí àwa fi inú rere gba irú àwọn wọ̀nyí, kí àwa lè jẹ́ alábáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú òtítọ́.

Èmi kọ̀wé sí ìjọ: ṣùgbọ́n Diotirefe, ẹni tí ó fẹ́ láti jẹ́ ẹni pàtàkì jùlọ, kò gbà wá. 10 Nítorí náà bí mo bá dé, èmi yóò mú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ṣe wá sì ìrántí rẹ, tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ búburú àti ìsọkúsọ sí wa: èyí kò sì tún tẹ́ ẹ lọ́rùn, síbẹ̀ òun fúnrarẹ̀ kọ̀ láti gba àwọn ará, àwọn tí ó sì ń fẹ́ gbà wọ́n, ó ń dá wọn lẹ́kun, ó sì ń lé wọn kúrò nínú ìjọ.

11 Olùfẹ́, má ṣe ṣe àfarawé ohun tí í ṣe ibi bí kò ṣe ohun tí ṣe rere. Ẹni tí ó bá ń ṣe rere ti Ọlọ́run ni; ẹni tí ó ba ń ṣe búburú kò rí Ọlọ́run. 12 (B)Demetriusi ní ẹ̀rí rere lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn àti ní ti òtítọ́ fúnrarẹ̀ pẹ̀lú; nítòótọ́, àwa pẹ̀lú sì gba ẹ̀rí rẹ̀ jẹ́; ẹ̀yin sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí wa.

13 (C)Èmí ní ohun púpọ̀ láti kọ sínú ìwé sí ọ, ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ fi kálàmù àti tawada kọ wọ́n sínú ìwé. 14 Mo ni ìrètí láti rí ọ láìpẹ́, tí àwa yóò sì sọ̀rọ̀ lójúkojú.

15 Àlàáfíà fún ọ.

Àwọn ọ̀rẹ́ wa tó wà níbí kí ọ. Kí àwọn ọ̀rẹ́ wa tó wà lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.