M’Cheyne Bible Reading Plan
Dina àti àwọn ará Ṣekemu
34 Ní ọjọ́ kan, Dina ọmọbìnrin tí Lea bí fún Jakọbu jáde lọ bẹ àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ náà wò. 2 Nígbà tí Ṣekemu ọmọ ọba Hamori ará Hifi rí i, ó mú un, ó sì fi ipá bá a lo pọ̀ 3 Ọkàn rẹ sì fà sí Dina ọmọ Jakọbu gan an, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ó sì bá ọmọbìnrin náà sọ̀rọ̀ ìfẹ́. 4 Ṣekemu sì wí fún Hamori baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ọmọbìnrin yìí fún mi bí aya.”
5 Nígbà tí Jakọbu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ pé a fi ipá bá Dina ọmọbìnrin òun ní ògo jẹ́, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀ wà nínú pápá níbi tí wọ́n ti ń daran nítorí náà ó mú sùúrù títí tí wọ́n fi dé.
6 Hamori baba Ṣekemu sì jáde wá láti bá Jakọbu sọ̀rọ̀. 7 Àwọn ọmọ Jakọbu sì ti oko dé, wọ́n sì gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ inú wọn sì bàjẹ́, ó sì ń bí wọn nínú gidigidi, nítorí tí ó ṣe ohun búburú ní Israẹli, ní ti ó bá ọmọbìnrin ọmọ Jakọbu lòpọ̀—irú ohun tí kò yẹ kí ó ṣẹlẹ̀ rárá.
8 Hamori sì bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkàn ọmọ mi Ṣekemu fà sí ọmọ rẹ. Jọ̀wọ́ fi fún un gẹ́gẹ́ bí aya. 9 Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ìgbéyàwó láàrín ara wa, kí àwọn ọmọ yín kó máa fẹ́ àwọn ọmọ wa. 10 Ẹ lè máa gbé láàrín wa, ibikíbi tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn láàrín wa ni ẹ lè gbé, ẹ máa ṣe òwò yín kí ẹ sì kó ọrọ̀ jọ fún ara yín.”
11 Ṣekemu sì wí fún baba àti arákùnrin Dina pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n rí ojúrere yín, èmi yóò sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ̀yin bá fẹ́ gbà. 12 Iyekíye tí owó orí rẹ̀ bá jẹ́ àti ẹ̀bùn gbogbo tí ẹ bá fẹ́, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó, èmi yóò san án, kí ẹ sá à jẹ́ kí ń fi ọmọ náà ṣe aya.”
13 Àwọn ọmọ Jakọbu sì fi ẹ̀tàn dá Ṣekemu àti Hamori baba rẹ̀ lóhùn, wọ́n sì wí pé, nítorí tí ó ti ba ògo Dina arábìnrin wọn jẹ́. 14 Wọ́n wí fún wọn pé, “Àwa kò le ṣe nǹkan yìí láti fi arábìnrin wa fún aláìkọlà, nítorí àbùkù ni èyí yóò jẹ́ fún wa. 15 Àwa yóò fi ara mọ́ ọn bí ẹ̀yin yóò bá gbà láti dàbí i tiwa, wí pé ẹ̀yin pẹ̀lú yóò kọ gbogbo ọkùnrin yín ní ilà. 16 Nígbà náà ni àwa yóò le máa fún yín ní ọmọ wa, tí àwa náà yóò máa fẹ́ ẹ yín. A ó máa gbé láàrín yín, a ó sì di ara kan pẹ̀lú yín. 17 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti kọlà, àwa yóò mú arábìnrin wa, á ó sì máa lọ.”
18 Àbá náà sì dùn mọ́ Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀. 19 Ọ̀dọ́mọkùnrin náà, ẹni tí ó jẹ́ ẹni iyì jùlọ ní ilé baba rẹ̀, kò jáfara láti ṣe ohun tí wọ́n wí. Nítorí tí ó fẹ́ràn ọmọbìnrin Jakọbu. 20 Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀ sì wá sí ẹnu ibodè ìlú náà wọn sì bá àwọn ará ìlú náà sọ̀rọ̀. 21 Wí pé, “Ìwà àwọn ọkùnrin wọ̀nyí dára, ẹ jẹ́ kí wọn máa gbé ní àárín wa, kí wọn sì máa ṣòwò, ilẹ̀ kúkú wà rẹpẹtẹ tó gba ààyè dáradára. A lè fẹ́ àwọn ọmọ wọ́n, ki wọn sì fẹ́ tiwa pẹ̀lú. 22 Ṣùgbọ́n kín ní kan ni a lè ṣe kí wọn tó gbà láti gbé pẹ̀lú wa, ìyẹn sì ni pé àwọn ọkùnrin wa yóò kọlà bí i tiwọn 23 Ṣe bí àwọn ẹran wọn àti ẹrú wọn àti àwọn ohun ọ̀sìn wọn ni yóò di tiwa bí a bá lè gbà bẹ́ẹ̀, wọn yóò sì máa gbé ni àárín wa.”
24 Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ń jáde ní ẹnu-bodè ìlú náà sì gbọ́ ti Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀. Gbogbo ọkùnrin ìlú náà sì kọlà.
25 Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta, nígbà tí gbogbo wọn sì wà nínú ìrora. Àwọn ọmọ Jakọbu méjì, Simeoni àti Lefi tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Dina, sì mú idà wọn pẹ̀lú ìgboyà, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin ìlú náà. 26 Wọ́n sì fi idà pa Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀, wọ́n mú Dina kúrò ní ilé wọn, wọ́n sì jáde. 27 Àwọn ọmọ Jakọbu sì wọlé àwọn tí a pa, wọ́n sì kó ẹrù ìlú tí a ti ba ògo arábìnrin wọn jẹ́. 28 Wọ́n kó màlúù wọn àti agbo ẹran wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìlú àti ní oko. 29 Gbogbo ọrọ̀ wọn, gbogbo obìnrin ìlú àti àwọn ọmọ wẹẹrẹ pátápátá ni wọ́n kó. Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé wọn bí ìkógun.
30 Nígbà náà ni Jakọbu wí fún Simeoni àti Lefi wí pé, “Ẹ̀yin ti kó ìyọnu bá mi nípa sísọ mí di olóòórùn láàrín ará Kenaani àti Peresi, tí ó ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwa kò pọ̀, bí wọn bá wá parapọ̀ ṣígun sí wa, gbogbo wa pátápátá ni wọn yóò parun.”
31 Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí ó ṣe arábìnrin wa bí panṣágà?”
Ìwòsàn ọkùnrin ẹlẹ́mìí èṣù
5 (A)Wọ́n lọ sí apá kejì adágún ní ẹ̀bá ilẹ̀ àwọn ará Gadara. 2 Bí Jesu sì ti ń ti inú ọkọ̀ ojú omi jáde. Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́ jáde ti ibojì wá pàdé rẹ̀. 3 Ọkùnrin yìí ń gbé nínú ibojì, kò sí ẹni tí ó lè dè é mọ́, kódà ẹ̀wọ̀n kò le dè é. 4 Nítorí pé nígbà púpọ̀ ni wọ́n ti ń fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀, tí ó sì ń já a dànù kúrò ni ẹsẹ̀ rẹ̀. Kò sí ẹnìkan tí ó ní agbára láti káwọ́ rẹ̀. 5 Tọ̀sán tòru láàrín àwọn ibojì àti ní àwọn òkè ni ó máa ń kígbe rara tí ó sì ń fi òkúta ya ara rẹ̀.
6 Nígbà tí ó sì rí Jesu látòkèrè, ó sì sáré lọ láti pàdé rẹ̀. Ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 7 (B)Ó sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tèmi tìrẹ, Jesu Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.” 8 Nítorí tí Ó wí fún un pé, “Jáde kúrò lára ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́!”
9 Jesu sì bi í léèrè pé, “Kí ni orúkọ rẹ?”
Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì dáhùn wí pé, “Ligioni, nítorí àwa pọ̀.” 10 Nígbà náà ni ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jesu gidigidi, kí ó má ṣe rán àwọn jáde kúrò ní agbègbè náà.
11 Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá kan sì ń jẹ lẹ́bàá òkè. 12 Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ Jesu pé, “Rán wa lọ sínú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ wọ̀n-ọn-nì kí àwa le è wọ inú wọn lọ.” 13 Jesu fún wọn láààyè, àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà tí ó tó ìwọ̀n ẹgbàá sì túká lọ́gán, wọ́n sì sáré lọ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè rọ́ sínú Òkun, wọ́n sì ṣègbé.
14 Àwọn olùtọ́jú ẹran wọ̀nyí sì sálọ sí àwọn ìlú ńlá àti ìlú kéékèèkéé, wọ́n sì ń tan ìròyìn náà ká bí wọ́n ti ń sáré. Àwọn ènìyàn sì tú jáde láti fojú gán-án-ní ohun náà tí ó ṣẹlẹ̀. 15 Nígbà tí wọ́n péjọ sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkùnrin náà, ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù, tí ó jókòó níbẹ̀, ó wọ aṣọ ìyè rẹ sì bọ̀ sípò, ẹ̀rù sì bà wọ́n. 16 Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn sì ń ròyìn rẹ̀ fún àwọn ènìyàn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin ẹlẹ́mìí àìmọ́, wọ́n si sọ nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà pẹ̀lú. 17 Nígbà náà, àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ Jesu pé kí ó fi agbègbè àwọn sílẹ̀.
18 Bí Jesu ti ń wọ inú ọkọ̀ ojú omi lọ, ọkùnrin náà tí ó ti ní ẹ̀mí àìmọ́ tẹ́lẹ̀ bẹ̀ Ẹ́ pé kí òun lè bá a lọ. 19 Jesu kò gbà fún un, ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Lọ sí ilé sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sì sọ fún wọn bí Ọlọ́run ti ṣe ohun ńlá fún ọ, àti bí ó sì ti ṣàánú fún ọ.” 20 (C)Nítorí naà, ọkùnrin yìí padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ní Dekapoli nípa ohun ńlá tí Jesu ṣe fún un. Ẹnu sì ya gbogbo ènìyàn.
Òkú ọmọbìnrin kan àti obìnrin aláìsàn
21 (D)Nígbà tí Jesu sì ti inú ọkọ̀ rékọjá sí apá kejì Òkun, ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọ yí i ká ní etí Òkun. 22 (E)Ọ̀kan nínú àwọn olórí Sinagọgu tí à ń pè ni Jairu wá sọ́dọ̀ Jesu, nígbà tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 23 (F)Ó sì bẹ̀ ẹ́ gidigidi pé, “Ọmọbìnrin mi wà lójú ikú, mo bẹ̀ ọ́, wá fi ọwọ́ rẹ lé e, kí ara rẹ̀ lè dá, kí ó sì yè.” 24 Jesu sì ń bá a lọ.
Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn. 25 Obìnrin kan sì wà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá. 26 Ẹni tí ojú rẹ̀ sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, tí ó sì ti ná gbogbo ohun tí ó ní, síbẹ̀ kàkà kí ó san, ó ń burú sí i. 27 Nígbà tí ó sì gbúròó iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe, ìdí nìyìí tí ó fi wá sẹ́yìn rẹ̀, láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀. 28 Nítorí ti ó rò ní ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à lè fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.” 29 Ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì gbẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun sì mọ̀ lára rẹ̀ pé, a mú òun láradá kúrò nínú ààrùn náà.
30 (G)Lọ́gán, Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé agbára jáde lára òun. Ó yípadà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì béèrè, “Ta ni ó fi ọwọ́ kan aṣọ mi?”
31 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó rọ̀gbà yí ọ ká, ìwọ sì tún ń béèrè ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn ọ́?”
32 Síbẹ̀, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí wò yíká láti rí ẹni náà, tí ó fi ọwọ́ kan òun. 33 Nígbà náà, obìnrin náà kún fún ìbẹ̀rù àti ìwárìrì nítorí ó ti mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun. Ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ gbogbo òtítọ́ fún un. 34 (H)Jesu sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá: Máa lọ ní àlàáfíà, ìwọ sì ti sàn nínú ààrùn rẹ.”
35 Bí Jesu sì ti ń ba obìnrin náà sọ̀rọ̀, àwọn ìránṣẹ́ dé láti ilé Jairu olórí Sinagọgu wá, wọ́n wí fún un pé, ọmọbìnrin rẹ ti kú, àti pé kí wọn má ṣe yọ Jesu lẹ́nu láti wá, nítorí ó ti pẹ́ jù.
36 Ṣùgbọ́n bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jairu pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbàgbọ́ nìkan.”
37 (I)Nígbà náà, Jesu dá ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró. Kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jairu, bí kò ṣe Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin Jakọbu. 38 Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jesu rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún. 39 Ó wọ inú ilé lọ, o sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohùnréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni.” 40 Wọ́n sì fi í rẹ́rìn-ín.
Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́ta. Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí. 41 (J)Ó gbá a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Talita kuumi” (tí ó túmọ̀ sí, ọmọdébìnrin, dìde dúró). 42 Lẹ́sẹ̀kan náà, ọmọbìnrin náà sì dìde. Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì bà wọ́n, ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi. 43 (K)Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó sì wí fún wọn kí wọn fún ọmọbìnrin náà ní oúnjẹ.
Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé Jobu
1 Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Usi, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Jobu; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́, ó dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó kórìíra ìwà búburú, 2 A sì bi ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta fún un. 3 Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ìbákasẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀jù gbogbo àwọn ará ìlà-oòrùn lọ.
4 Àwọn ọmọ rẹ̀ a sì máa lọ í jẹun àsè nínú ilé ara wọn, olúkúlùkù ní ọjọ́ rẹ̀; wọn a sì máa ránṣẹ́ pé arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti jẹun àti láti pẹ̀lú wọn. 5 Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àsè wọn pé yíká, ni Jobu ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jobu wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́kàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jobu máa ń ṣe nígbà gbogbo.
Ìdánwò Jobu àkọ́kọ́
6 Ǹjẹ́ ó di ọjọ́ kan, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá í pé níwájú Olúwa, Satani sì wá pẹ̀lú wọn. 7 Olúwa sì bi Satani wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?”
Nígbà náà ní Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Ní ìlọ-síwá-sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”
8 Olúwa sì sọ fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí í ṣe olóòtítọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti ó sì kórìíra ìwà búburú.”
9 Nígbà náà ni Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Jobu ha bẹ̀rù Ọlọ́run ní asán bí?” 10 “Ìwọ kò ha ti ṣọgbà yìí ká, àti yí ilé rẹ̀ àti yí ohun tí ó ní ká, ní ìhà gbogbo? Ìwọ bùsi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì ń pọ̀ si ní ilẹ̀. 11 Ǹjẹ́, nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó sì fi tọ́ ohun gbogbo tí ó ni; bí kì yóò sì bọ́hùn ni ojú rẹ.”
12 Olúwa sì dá Satani lóhùn wí pé, “Kíyèsi i, ohun gbogbo tí ó ní ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, kìkì òun tìkára rẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ rẹ kàn.”
Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú Olúwa.
13 Ó sì di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, tí wọ́n mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin, 14 oníṣẹ́ kan sì tọ Jobu wá wí pé: “Àwọn ọ̀dá màlúù ń tulẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹ ní ẹ̀gbẹ́ wọn; 15 Àwọn ará Sabeani sì kọlù wọ́n, wọ́n sì ń kó wọn lọ pẹ̀lú, wọ́n ti fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa, èmi nìkan ṣoṣo ní ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ.”
16 Bí ó ti ń sọ ní ẹnu; ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé, “Iná ńlá Ọlọ́run ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́; èmi nìkan ṣoṣo ní ó sálà láti ròyìn fún ọ.”
17 Bí ó sì ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan sì dé pẹ̀lú tí ó wí pé, “Àwọn ará Kaldea píngun sí ọ̀nà mẹ́ta, wọ́n sì kọlù àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì kó wọn lọ, pẹ̀lúpẹ̀lú wọ́n sì fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ!”
18 Bí ó ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin ń jẹ, wọ́n ń mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n. 19 Sì kíyèsi i, ẹ̀fúùfù ńláńlá ti ìhà ijù fẹ́ wá kọlu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wó lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkan ṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ.
20 Nígbà náà ni Jobu dìde, ó sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, ó sì fá orí rẹ̀ ó wólẹ̀ ó sì gbàdúrà 21 wí pé:
“Ní ìhòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá,
ni ìhòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ.
Olúwa fi fún ni, Olúwa sì gbà á lọ,
ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa.”
22 Nínú gbogbo èyí Jobu kò ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi òmùgọ̀ pe Ọlọ́run lẹ́jọ́.
Àlàáfíà àti ayọ̀
5 (A)Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. 2 (B)Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró. Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run. 3 (C)Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú: bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń ṣiṣẹ́ sùúrù; 4 àti pé sùúrù ń ṣiṣẹ́ ìwà rere; àti pé ìwà rere ń ṣiṣẹ́ ìrètí: 5 (D)Ìrètí kì í sì í dójúti ni nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa.
6 Nítorí ìgbà tí àwa jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó yẹ, Kristi kú fún àwa aláìwà-bí-Ọlọ́run. 7 Nítorí ó ṣọ̀wọ́n kí ẹnìkan tó kú fún olódodo: ṣùgbọ́n fún ènìyàn rere bóyá ẹlòmíràn tilẹ̀ lè dábàá láti kú. 8 (E)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.
9 (F)Mélòó mélòó sì ni tí a dá wa láre nísinsin yìí nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó gbà wá là kúrò nínú ìbínú nípasẹ̀ rẹ̀. 10 (G)Ǹjẹ́, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀. 11 (H)Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsin yìí.
Ikú nípasẹ̀ Adamu, iyè nípasẹ̀ Jesu
12 (I)Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipa ọ̀dọ̀ ènìyàn kan wọ ayé, àti ikú nípa ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ikú sì kọjá sórí ènìyàn gbogbo, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo ènìyàn ti dẹ́ṣẹ̀:
13 Nítorí kí òfin tó dé, ẹ̀ṣẹ̀ ti wà láyé; ṣùgbọ́n a kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí ni lọ́rùn nígbà tí òfin kò sí. 14 (J)Ṣùgbọ́n ikú jẹ ọba láti ìgbà Adamu wá títí fi di ìgbà ti Mose, àti lórí àwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò dàbí irú ìrékọjá Adamu, ẹni tí í ṣe àpẹẹrẹ ẹni tí ń bọ̀.
15 (K)Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kò dàbí ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí nípa ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí o bá jẹ pé ẹnìkan ẹni púpọ̀ kú, mélòó mélòó ni oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, àti ẹ̀bùn nínú oore-ọ̀fẹ́ ọkùnrin kan, Jesu Kristi, di púpọ̀ fún ẹni púpọ̀. 16 (L)Kì í ṣe nípa ẹnìkan tí ó sẹ̀ ni ẹ̀bùn náà: Nítorí ìdájọ́ ti ipasẹ̀ ẹnìkan wá fún ìdálẹ́bi, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ti inú ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ wá fún ìdáláre, 17 Ǹjẹ́ bí o bá jẹ pé nípa ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin kan, ikú jẹ ọba nípasẹ̀ ẹnìkan náà; mélòó mélòó ni àwọn tí ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bùn òdodo yóò jẹ ọba nínú ìyè nípasẹ̀ ẹnìkan, Jesu Kristi.
18 Ǹjẹ́ bí o bá jẹ pé nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan ìdájọ́ dé bá gbogbo ènìyàn sí ìdálẹ́bi; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni nípa ìwà òdodo ẹnìkan, ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ dé sórí gbogbo ènìyàn fún ìdáláre sí ìyè. 19 (M)Nítorí gẹ́gẹ́ bí nípa àìgbọ́ràn ọkùnrin kan, ènìyàn púpọ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni nípa ìgbọ́ràn ẹnìkan, a ó sọ ènìyàn púpọ̀ di olódodo.
20 (N)Ṣùgbọ́n òfin bọ́ sí inú rẹ̀, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè di púpọ̀, ṣùgbọ́n ni ibi ti ẹ̀ṣẹ̀ di púpọ̀, oore-ọ̀fẹ́ di púpọ̀ rékọjá. 21 (O)Pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti jẹ ọba nípa ikú bẹ́ẹ̀ ni kí oore-ọ̀fẹ́ sì lè jẹ ọba nípa òdodo títí ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.