M’Cheyne Bible Reading Plan
10 Samuẹli sì mú ìgò kékeré tí òróró wà nínú rẹ̀, ó sì dà á sí orí Saulu. Ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu, wí pé, “Olúwa kò ha tí fi òróró yàn ọ ní olórí lórí ohun ìní rẹ̀? 2 Bí ìwọ bá kúrò lọ́dọ̀ mi lónìí, ìwọ yóò bá ọkùnrin méjì pàdé lẹ́bàá ibojì Rakeli ní Ṣelṣa, ní agbègbè Benjamini. Wọ́n yóò sọ fún ọ pé, ‘Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ìwọ jáde lọ láti wá ní wọn tí rí. Nísinsin yìí, baba à rẹ tí dákẹ́ kò ronú nípa wọn mọ́, ó sì ń dààmú nípa à rẹ. Ó ń béèrè, “Kí ni èmi yóò ṣe nípa ọmọ mi?” ’
3 “Nígbà náà, ìwọ yóò lọ láti ibẹ̀ títí yóò fi dé ibi igi ńlá Tabori. Ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní Beteli yóò pàdé rẹ níbẹ̀. Ọ̀kan yóò mú ọmọ ewúrẹ́ mẹ́ta lọ́wọ́, èkejì, ìṣù àkàrà mẹ́ta àti ẹ̀kẹta yóò mú ìgò wáìnì. 4 Wọ́n yóò kí ọ, wọn yóò sì fún ọ ní ìṣù àkàrà méjì, tí ìwọ yóò gbà lọ́wọ́ wọn.
5 “Lẹ́yìn náà, ìwọ yóò lọ sí òkè Ọlọ́run, níbi tí ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini wà. Bí ìwọ ti ń súnmọ́ ìlú náà, ìwọ yóò bá àwọn wòlíì tí ó tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ bọ̀ láti ibi gíga, pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn, tambori àti fèrè àti haapu níwájú wọn, wọn yóò sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. 6 Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé ọ, ìwọ yóò sì sọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú wọn, ìwọ yóò sì di ẹni ọ̀tọ̀. 7 Bí ìwọ bá ti rí ààmì wọ̀nyí, ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà láti ṣe, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.
8 “Lọ ṣáájú mi sí Gilgali. Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá láti rú ẹbọ sísun àti láti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ dúró fún ọjọ́ méje títí èmi yóò fi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti sọ fún ọ ohun tí ó yẹ tí ìwọ yóò ṣe.”
A fi Saulu jẹ ọba
9 Bí Saulu ti yípadà láti fi Samuẹli sílẹ̀, Ọlọ́run yí ọkàn Saulu padà àti pé gbogbo ààmì wọ̀nyí sì wá sí ìmúṣẹ ní ọjọ́ náà. 10 Nígbà tí wọ́n dé òkè Gibeah náà, àwọn wòlíì tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ pàdé rẹ̀, Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e nínú agbára, ó sì darapọ̀ bá wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀. 11 Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn wòlíì, wọ́n bi ara wọn, “Kí ni ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kiṣi yìí. Ṣé Saulu wà lára àwọn wòlíì ni?”
12 Ọkùnrin kan tí ó ń gbé níbẹ̀ dáhùn pé, “Ta ni baba wọn?” Ó ti di ohun tí a fi ń pa òwe pé, ǹjẹ́ Saulu náà wà lára àwọn wòlíì bí? 13 Lẹ́yìn tí Saulu dákẹ́ sísọ àsọtẹ́lẹ̀, ó lọ sí ibi gíga.
14 Nísinsin yìí, arákùnrin baba Saulu béèrè lọ́wọ́ Saulu àti ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni ẹ lọ?”
Ó wí pé, “À ń wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,” ṣùgbọ́n nígbà tí a kò rí wọn, a lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli.
15 Arákùnrin baba Saulu wí pé, “Sọ fún mi ohun tí Samuẹli wí fún un yín.”
16 Saulu dáhùn pé, “Ó fi dá wa lójú pé wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún arákùnrin baba a rẹ̀ ohun tí Samuẹli sọ nípa ọba jíjẹ.
17 Samuẹli pé àwọn ọmọ Israẹli jọ sí iwájú Olúwa ní Mispa. 18 Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ: ‘Èmi mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti, Èmi sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ agbára Ejibiti àti gbogbo ìjọba tí ó ń pọ́n ọn yín lójú.’ 19 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti kọ Ọlọ́run yín, tí ó gbà yín kúrò nínú gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú yín. Ẹ̀yin sì ti sọ pé, ‘Rárá, yan ọba kan fún wa.’ Báyìí, ẹ kó ara yín jọ níwájú Olúwa ní ẹ̀yà àti ìdílé yín.”
20 Nígbà tí Samuẹli mú gbogbo ẹ̀yà Israẹli súnmọ́ tòsí, ó yan ẹ̀yà Benjamini. 21 Ó kó ẹ̀yà Benjamini síwájú ní ìdílé ìdílé, a sì yan ìdílé Matiri. Ní ìparí a sì yan Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí wọ́n wá a, a kò rí i, 22 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Olúwa pé, “Ṣé ọkùnrin náà ti wá sí bí ni?”
Olúwa sì sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ láàrín àwọn ẹrù.”
23 Wọ́n sáré, wọ́n sì mú un jáde wá. Bí ó ti dúró láàrín àwọn ènìyàn, ó sì ga ju gbogbo àwọn tí ó kù lọ láti èjìká rẹ̀ sókè. 24 Samuẹli sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé, “Ṣé ẹ ti ri ọkùnrin tí Olúwa ti yàn? Kò sí ẹnìkan bí i rẹ̀ láàrín gbogbo àwọn ènìyàn.”
Nígbà náà àwọn ènìyàn kígbe pé, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn!”
25 Samuẹli ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn àwọn ìlànà ìjọba. Ó kọ wọ́n sínú ìwé, ó sì fi lélẹ̀ níwájú Olúwa. Lẹ́yìn náà, Samuẹli tú àwọn ènìyàn ká olúkúlùkù sí ilé e rẹ̀.
26 Saulu náà padà sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah. Àwọn akọni ọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi ọwọ́ tọ́ ọkàn wọ́n sì sìn ín. 27 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Beliali wí pé, “Báwo ni ọkùnrin yìí yóò ti ṣe gbà wá?” Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn wá fún un, ṣùgbọ́n Saulu fọwọ́ lérán.
Ìyè nípasẹ̀ ẹ̀mí
8 (A)Nítorí náà, kò sí ìdálẹ́bi nísinsin yìí fún àwọn tí ó wà nínú Kristi Jesu, àwọn tí kò rìn nípa ti ara, bí kò ṣe nípa ti Ẹ̀mí. 2 (B)Nítorí nípasẹ̀ òfin ti ẹ̀mí ìyè nínú Kristi Jesu ti sọ mí di òmìnira kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. 3 (C)Nítorí ohun tí òfin kò lè ṣe, bí ó ti jẹ aláìlera nítorí ara, Ọlọ́run rán ọmọ òun tìkára rẹ̀ ní àwòrán ara ẹ̀ṣẹ̀, ó sì di ẹ̀ṣẹ̀; àti bi ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi nínú ara, 4 (D)kí a lè mú òdodo òfin ṣẹ, nínú wa, nítorí tí àwa yé gẹ́gẹ́ bí ohun ti ara, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ti Ẹ̀mí.
5 (E)Àwọn tí ń gbe nípa ti ara, wọn a máa ronú ohun ti ara; ṣùgbọ́n àwọn ti ń gbe nípa ti Ẹ̀mí, wọn a máa ronú ohun ti Ẹ̀mí. 6 (F)Nítorí èrò ti ara ikú ni; ṣùgbọ́n èrò ti ẹ̀mí ni ìyè àti àlàáfíà. 7 Nítorí èrò ti ara ọ̀tá ni sí Ọlọ́run, nítorí kì í tẹríba fún òfin Ọlọ́run, òun kò tilẹ̀ le ṣe e. 8 (G)Ìdí nìyìí tí àwọn tí ó wà lábẹ́ àkóso ara ẹ̀ṣẹ̀, kò le è tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn.
9 (H)Ṣùgbọ́n ẹyin kò sí nínú ti ara, bí kò ṣe nínú ti Ẹ̀mí, bí ó bá ṣe pé Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín, Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá ní Ẹ̀mí Kristi, òun kò sí nínú ẹni tirẹ̀. 10 (I)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristi ń gbé inú yín síbẹ̀síbẹ̀, ara yín jẹ́ òkú nítorí ẹ̀ṣẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀mí mímọ́ tí ń gbé inú yín yóò fún yín ní ìyè, nítorí ó ti fún un yín ní òdodo. 11 (J)Àti pé, bí ẹ̀mí Ọlọ́run, ẹni tí ó jí Jesu kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, ẹni tí ó jí Kristi Jesu dìde kúrò nínú òkú, yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ tí ń gbé inú yín sọ ara kíkú yín di ààyè pẹ̀lú.
12 Nítorí náà ará a ni ojúṣe láti ṣe, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa nǹkan tí ara, tí a ó fi máa gbé nípa ti ara. 13 (K)Nítorí pé bí ẹ̀yin bá ń tẹ̀lé, ẹ̀ṣẹ̀ ti ara ẹ̀yin yóò sọnù, ẹ ó sì ṣègbé, ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ń gbé nípa ti ara, ẹ̀yin yóò kú, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yín bá ń gbé nípa ti Ẹ̀mí, ẹ ó pa iṣẹ́ ti ara run, ẹ̀yin yóò yè.
14 (L)Nítorí pé, iye àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí ni ọmọ Ọlọ́run. 15 (M)Nítorí ẹ̀yin kò tún gba ẹ̀mí ẹrú láti máa bẹ̀rù mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, nípa èyí tí àwa fi ń ké pé “Ábbà, Baba.” 16 (N)Nítorí ẹ̀mí mímọ́ ń sọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ọkàn wa, ó sì ń sọ fún wa pé, nítòótọ́, àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. 17 (O)Níwọ́n ìgbà tí a jẹ́ ọmọ rẹ̀, ǹjẹ́ ajogún ni àwa, ajogún Ọlọ́run, àti àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, bí ó bá ṣe àwa jìyà, kí a sì le ṣe wá lógo pẹ̀lú rẹ̀.
Ìgbádùn tí ń bọ̀ àti ìjìyà ìsìn yìí
18 (P)Síbẹ̀síbẹ̀, ìyà tí a ń jẹ nísinsin yìí kò jámọ́ nǹkan nígbà tí a bá fiwé ògo tí yóò fún wa ní ìkẹyìn. 19 (Q)Nítorí ẹ̀dá ń dúró ní ìfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run. 20 (R)Nítorí a tẹrí ẹ̀dá ba fún asán, kì í ṣe bí òun ti fẹ́, ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ẹni tí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní ìrètí. 21 (S)Nítorí a ó sọ ẹ̀dá tìkára rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ẹrú ìdíbàjẹ́, sí òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọ́run.
22 (T)Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ẹ̀dá ni ó jùmọ̀ ń kérora tí ó sì ń rọbí pọ̀ títí di ìsinsin yìí. 23 (U)Kì í ṣe àwọn nìkan, ṣùgbọ́n àwa tìkára wa pẹ̀lú, a ni àkóso ẹ̀mí, àní àwa tìkára wa ń kérora nínú ara wa, àwa ń dúró de ìsọdọmọ àní ìdáǹdè ara wa. 24 (V)Nítorí nípa ìrètí ni a fi gbà wá là: ṣùgbọ́n ìrètí tí a bá rí kì í ṣe ìrètí nítorí ta ni ń retí ohun tí ó bá rí? 25 Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń retí èyí tí àwa kò rí, ǹjẹ́ àwa ń fi sùúrù dúró dè é.
26 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí pẹ̀lú sì ń ran àìlera wa lọ́wọ́: nítorí a kò mọ bí a ti ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ: ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń fi ìrora tí a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ̀ fún wa. 27 (W)Ẹni tí ó sì ń wá inú ọkàn wò, ó mọ ohun ti ẹ̀mí, nítorí tí ó ń bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run.
28 Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀. 29 (X)Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn arákùnrin púpọ̀ 30 Àti pé lẹ́yìn tí òun ti pè wá wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sọ wá di “aláìjẹ̀bi” lẹ́yìn èyí, ó fi rere Kristi kún inú ọkàn wa. Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún wa ní ìdúró rere pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pinu ògo rẹ̀ fún wa.
Jíju aṣẹ́gun lọ
31 (Y)Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa? 32 (Z)Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti fi Ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le ṣòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí? 33 (AA)Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀. Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dáríjì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀. 34 (AB)Ta ni ẹni náà tí yóò dá wa lẹ́bi? Kò sí. Kristi Jesu tí ó kú, kí a sá à kúkú wí pé tí a ti jí dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí ó sì wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, tó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa? 35 Ta ni yóò ha yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni, tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ìyàn, tàbí ìhòhò, tàbí ewu tàbí idà? 36 (AC)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Nítorí rẹ̀ ni a ṣe ń pa wá kú ní gbogbo ọjọ́;
À ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.”
37 (AD)Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ju ẹni tí ó ṣẹ́gun lọ nípasẹ̀ Kristi ẹni tí ó fẹ́ wa. 38 Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kì í ṣe ikú tàbí ìyè, kì í ṣe àwọn angẹli tàbí ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe ohun ìgbà ìsinsin yìí tàbí ohun tí ó ń bọ̀, tàbí àwọn agbára, 39 tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.
Àṣọtẹ́lẹ̀ ní tí àwọn ará Filistini
47 (A)Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tó tọ wòlíì Jeremiah wá nípa àwọn Filistini, kí ó tó di pé Farao dojúkọ Gasa:
2 Báyìí ni Olúwa wí:
“Wo bí omi ti ń ru sókè ní àríwá,
wọn ó di odò tí ń bo bèbè mọ́lẹ̀.
Wọn kò ní borí ilẹ̀ àti ohun gbogbo tó wà lórí rẹ̀,
ìlú àti àwọn tó ń gbé nínú wọn.
Àwọn ènìyàn yóò kígbe;
gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà yóò hu
3 Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ìró títẹ̀lé pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin alágbára
nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ọ̀tá ńlá
àti iye kẹ̀kẹ́ wọn.
Àwọn baba kò ní lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́;
ọwọ́ wọn yóò kákò.
4 Nítorí tí ọjọ́ náà ti pé
láti pa àwọn Filistini run,
kí a sì mú àwọn tí ó là
tí ó lè ran Tire àti Sidoni lọ́wọ́ kúrò.
Olúwa ti ṣetán láti pa Filistini run,
àwọn tí ó kù ní agbègbè Kafitori.
5 Gasa yóò fá irun orí rẹ̀ nínú ọ̀fọ̀.
A ó pa Aṣkeloni lẹ́nu mọ́;
ìyókù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀,
ìwọ yóò ti sá ara rẹ lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?
6 “Ẹ̀yin kígbe, ‘Yé è, idà Olúwa,
yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò sinmi?
Padà sínú àkọ̀ rẹ;
sinmi kí o sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.’
7 Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe sinmi,
nígbà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un,
nígbà tí ó ti pa á láṣẹ
láti dojúkọ Aṣkeloni àti agbègbè rẹ̀.”
Saamu ti Dafidi.
23 Olúwa ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
2 (A)Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù
Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́;
3 Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò
Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo
nítorí orúkọ rẹ̀.
4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn
Láàrín àfonífojì òjìji ikú,
èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;
nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;
ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ
wọ́n ń tù mí nínú.
5 Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi
ní ojú àwọn ọ̀tá à mi;
ìwọ ta òróró sí mi ní orí;
ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
6 Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn
ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,
èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa
títí láéláé.
Ti Dafidi. Saamu.
24 (B)Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀,
ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;
2 Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí Òkun
ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.
3 Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ?
Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?
4 (C)Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,
ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán
tí kò sì búra èké.
5 Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,
àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.
6 Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀,
tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.
7 Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà;
Kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé!
Kí ọba ògo le è wọlé.
8 Ta ni ọba ògo náà?
Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le,
Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.
9 Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà;
kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,
kí Ọba ògo le è wọlé wá.
10 Ta ni Ọba ògo náà?
Olúwa àwọn ọmọ-ogun
Òun ni Ọba ògo náà. Sela.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.