Historical
Hesekiah ṣe àsè ìrékọjá
30 Hesekiah sì ránṣẹ́ sí gbogbo Israẹli àti Juda, ó sì kọ ìwé sí Efraimu àti Manase, kí wọn kí ó wá sínú ilé Olúwa ní Jerusalẹmu láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli. 2 Nítorí tí ọba ti gbìmọ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo ìjọ ènìyàn ní Jerusalẹmu, láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní oṣù kejì. 3 Nítorí wọn kò lè pa á mọ́ ní àkókò náà, nítorí àwọn àlùfáà kò tí i ya ara wọn sí mímọ́ tó; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò tí ì kó ara wọn jọ sí Jerusalẹmu. 4 Ọ̀rọ̀ náà sí tọ́ lójú ọba àti lójú gbogbo ìjọ ènìyàn. 5 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi àṣẹ kan lélẹ̀, láti kéde ká gbogbo Israẹli láti Beerṣeba àní títí dé Dani, láti wá pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ní Jerusalẹmu: nítorí wọn kò pa á mọ́ ní ọjọ́ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.
6 Bẹ́ẹ̀ àwọn oníṣẹ́ tí ń sáré lọ pẹ̀lú ìwé láti ọwọ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ sí gbogbo Israẹli àti Juda; àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, wí pé:
“Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ẹ yí padà sí Olúwa Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki, àti Israẹli, òun ó sì yípadà sí àwọn ìyókù nínú yín, tí ó sálà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọba Asiria. 7 Kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe dàbí àwọn baba yín, àti bí àwọn arákùnrin yín tí ó dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn, nítorí náà ní ó ṣe fi wọ́n fún ìdahoro bí ẹ̀yin ti rí. 8 Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣe ọlọ́rùn líle, bí àwọn baba yín, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ara yín lọ́wọ́ fún Olúwa, kí ẹ sì wọ inú ibi mímọ́ rẹ̀ lọ, ti òun ti ìyàsímímọ́ títí láé: Kí ẹ sì sin Olúwa, Ọlọ́run yín kí gbígbóná ìbínú rẹ̀ kí ó lè yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ yín. 9 Nítorí bí ẹ̀yin bá tún yípadà sí Olúwa, àwọn arákùnrin yín, àti àwọn ọmọ yín, yóò rí àánú níwájú àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, kí wọn kí ó lè tún padà wá sí ilẹ̀ yí: nítorí Olúwa Ọlọ́run yín, oníyọnu àti aláàánú ni, kì yóò sì yí ojú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ yín, bí ẹ̀yin bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀.”
10 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ náà kọjá láti ìlú dé ìlú, ní ilẹ̀ Efraimu àti Manase títí dé Sebuluni: Ṣùgbọ́n wọ́n fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, wọ́n sì gàn wọ́n. 11 Síbẹ̀ òmíràn nínú àwọn ènìyàn Aṣeri àti Manase àti Sebuluni rẹ̀ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Jerusalẹmu. 12 Ní Juda pẹ̀lú, ọwọ́ Ọlọ́run wá láti fún wọn ní ọkàn kan láti pa òfin ọba mọ́ àti tí àwọn ìjòyè, nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.
13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì péjọ ní Jerusalẹmu, láti pa àjọ àkàrà àìwú mọ́ ní oṣù kejì. 14 Wọ́n sì dìde, wọ́n sì kó gbogbo pẹpẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu lọ, àti gbogbo pẹpẹ tùràrí ni wọ́n kó lọ, wọ́n sì dà wọ́n sí odò Kidironi.
15 Nígbà náà ni wọ́n pa ẹran ìrékọjá náà ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì: ojú sì ti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì yà ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì mú ẹbọ sísun wá sínú ilé Olúwa. 16 Wọ́n sì dúró ní ipò wọn, bí ètò wọn gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, ènìyàn Ọlọ́run: àwọn àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà, tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Lefi. 17 Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà nínú ìjọ ènìyàn náà tí kò yà ara wọn sí mímọ́: nítorí náà ni àwọn ọmọ Lefi ṣe ń tọ́jú àti pa ẹran ìrékọjá fún olúkúlùkù ẹni tí ó ṣe aláìmọ́, láti yà á sí mímọ́ sí Olúwa. 18 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú Efraimu àti Manase, Isakari, àti Sebuluni kò sá wẹ̀ ara wọn mọ́ síbẹ̀ wọ́n jẹ ìrékọjá naà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. Ṣùgbọ́n Hesekiah bẹ̀bẹ̀ fún wọn, wí pé, Olúwa, ẹni rere, dáríjì olúkúlùkù, 19 tí ó múra ọkàn rẹ̀ láti wá Ọlọ́run, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kì í ṣe nípa ìwẹ̀nùmọ́ mímọ́ 20 Olúwa sì gbọ́ ti Hesekiah, ó sì mú àwọn ènìyàn náà láradá.
21 Àwọn ọmọ Israẹli tí a rí ní Jerusalẹmu fi ayọ̀ ńlá pa àjọ àkàrà àìwú mọ́ ní ọjọ́ méje: àwọn ọmọ Lefi, àti àwọn àlùfáà yin Olúwa lójoojúmọ́, wọ́n ń fi ohun èlò olóhùn gooro kọrin sí Olúwa.
22 Hesekiah sọ̀rọ̀ ìtùnú fún gbogbo àwọn ọmọ Lefi, tí ó lóye ní ìmọ̀ rere Olúwa: ọjọ́ méje ni wọ́n fi jẹ àsè náà wọ́n rú ẹbọ àlàáfíà, wọ́n sì ń fi ohùn rara dúpẹ́ fún Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn.
23 Gbogbo ìjọ náà sì gbìmọ̀ láti pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́: wọ́n sì fi ayọ̀ pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́. 24 Nítorí Hesekiah, ọba Juda, ta ìjọ ènìyàn náà ní ọrẹ, ẹgbẹ̀rún akọ màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin àgùntàn: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà sì ya ara wọn sí mímọ́. 25 Gbogbo ìjọ ènìyàn Juda pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó ti inú Israẹli jáde wá, àti àwọn àjèjì tí ó ti ilẹ̀ Israẹli jáde wá, àti àwọn tí ń gbé Juda yọ̀. 26 Bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ńlá sì wà ní Jerusalẹmu: nítorí láti ọjọ́ Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli, irú èyí kò sí ní Jerusalẹmu. 27 Nígbà náà ni àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi dìde, wọ́n sì súre fún àwọn ènìyàn náà: a sì gbọ́ ohùn wọn, àdúrà wọn sì gòkè lọ si ibùgbé mímọ́ rẹ̀, àní sí ọ̀run.
31 Nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ti dé òpin, àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀ jáde lọ sí àwọn ìlú Juda, wọ́n fọ́ àwọn òkúta ìyàsọ́tọ̀ sí wẹ́wẹ́, wọ́n gé àwọn ère Aṣerah lulẹ̀. Wọ́n ba àwọn ibi gíga jẹ́ àti àwọn pẹpẹ jákèjádò Juda àti Benjamini àti ní Efraimu àti Manase. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti pa gbogbo wọn run, àwọn ọmọ Israẹli padà sí ìlú wọn àti sí nǹkan ìní wọn.
Ìdáwó fún ìjọ́sìn
2 Hesekiah fi lé àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi lọ́wọ́ sí àwọn ìpín olúkúlùkù wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí ará Lefi láti tẹ́ ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ láti fi ọpẹ́ fún àti láti kọ àwọn orin ìyìn ní ẹnu-ọ̀nà ibùgbé Olúwa. 3 Ọba fi sílẹ̀ láti ara ohun ìní rẹ̀ fun ẹbọ sísun àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti fún ẹbọ sísun ní ọjọ́ ìsinmi, òṣùpá tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn gẹ́gẹ́ bi a ti ṣe kọ ọ́ nínú òfin Olúwa. 4 Ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu láti fi ìpín tí ó yẹ fún àlùfáà fún un àti àwọn ará Lefi, kí wọn kí ó lè fi ara wọn jì fún òfin Olúwa. 5 Ní kété tí àṣẹ náà jáde lọ, àwọn ọmọ Israẹli fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àkọ́so ti ọkà wọn, ọtí tuntun, òróró àti oyin àti gbogbo ohun tí pápá mú jáde lélẹ̀. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ iye, àti ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan wá. 6 Àwọn ọkùnrin Israẹli àti Juda ti gbe inú àwọn ìlú Juda pẹ̀lú mú ìdámẹ́wàá agbo ẹran àti ohun èlò àti ohun ọ̀sìn àti ìdámẹ́wàá ti àwọn nǹkan mímọ́ tí a ti yà sọ́tọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkìtì. 7 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe èyí ní oṣù kẹta, wọ́n sì parí ní oṣù keje. 8 Nígbà tí Hesekiah àti àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá, tí wọ́n sì rí òkìtì náà, wọ́n yin Olúwa, pẹ̀lú ìbùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli.
9 Hesekiah béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi nípa òkìtì; 10 àti Asariah olórí àlùfáà ti ìdílé Sadoku sì dáhùn pé, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ìdáwó wọn wá sí ilé Olúwa àti ní èyí tí yóò tó jẹ àti ọ̀pọ̀ láti tọ́jú pamọ́ nítorí Olúwa ti bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ṣẹ́kù lọ́pọ̀lọpọ̀.”
11 Hesekiah pàṣẹ láti tọ́jú àwọn yàrá ìṣúra nínú ilé Olúwa, wọ́n sì ṣe èyí. 12 Nígbà náà wọ́n mú ọrẹ àti ìdámẹ́wàá àti àwọn ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ wọ ilé náà wá nítòótọ́. Lórí èyí tí Konaniah ọmọ Lefi, ń ṣe olórí, Ṣimei arákùnrin rẹ̀ ni igbákejì rẹ̀. 13 Jehieli, Asasiah, Nahati, Asaheli, Jerimoti, Josabadi, Elieli, Ismakia, Mahati àti Benaiah jẹ́ àwọn alábojútó lábẹ́ Konaniah àti Ṣimei arákùnrin rẹ̀ nípa ipá ọba Hesekiah àti Asariah olórí ti ó wà ní ìkáwọ́ ilé Ọlọ́run.
14 Kore ọmọ Imina ará Lefi Olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn, wà ní ìkáwọ́ àwọn ọrẹ àtinúwá tí a fi fún Ọlọ́run, o ń pín ìdáwó tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ 15 Edeni, Miniamini, Jeṣua, Ṣemaiah, Amariah àti Ṣekaniah ràn án lọ́wọ́ tọkàntọkàn nínú àwọn ìlú àwọn àlùfáà tí ń dáwó fún àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àgbà àti kékeré.
16 Ní àfikún, wọ́n pín sí àwọn ọkùnrin àgbà ọdún mẹ́ta tàbí ọ̀pọ̀ tí orúkọ wọn wà nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn. Gbogbo àwọn ti yóò wọ ilé Olúwa láti ṣe oríṣìí iṣẹ́ ti a gbà wọ́n fún gẹ́gẹ́ bí ìgbẹ́kẹ̀lé wọn àti ìpín wọn. 17 Wọ́n sì pín àwọn àlùfáà, wọn kọ orúkọ àwọn ìdílé wọn sínú ìtàn ìdílé àti sí àwọn ará Lefi ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu àti ìpín wọn. 18 Wọ́n fi gbogbo àwọn ọmọ kéékèèkéé sí i, àwọn ìyàwó, àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin gbogbo ará ìlú tí a kọ lẹ́sẹẹsẹ sínú ìtàn ìdílé ti baba ńlá wọn fún ìrántí. Nítorí tí wọ́n ṣe òtítọ́ ní yíya ara wọn sí ọ̀tọ̀.
19 Ní ti àwọn àlùfáà, àwọn ìran ọmọ Aaroni, tí ń gbé ni àwọn ilẹ̀ oko lẹ́bàá àwọn ìlú wọn tàbí ní àwọn ìlú mìíràn. A yan àwọn ọkùnrin pẹ̀lú orúkọ láti pín ìlú fún gbogbo ọkùnrin láàrín wọn àti sí gbogbo àwọn tí a kọ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá àwọn ará Lefi.
20 Èyí ni Hesekiah ṣe jákèjádò Juda, ó sì ṣe ohun tí ó dára àti tí ó tọ́ àti ohun òtítọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. 21 Nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé ní ti iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Ọlọ́run àti ní ìgbọ́ràn sí òfin àti àwọn àṣẹ. Ó wá Ọlọ́run rẹ̀, ó sì ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn. Ó sì ṣe rere.
Sennakeribu dẹ́rùba Jerusalẹmu
32 (A)Lẹ́yìn gbogbo èyí ti Hesekiah ti fi òtítọ́ ṣe, Sennakeribu ọba Asiria wá ó sì gbógun ti Juda. Ó gbógun ti àwọn ìlú ààbò, ó ń ronú láti ṣẹ́gun wọn fún ara rẹ̀. 2 Nígbà tí Hesekiah rí i pé Sennakeribu ti wá, àti pé ó fẹ́ láti dá ogun sílẹ̀ lórí Jerusalẹmu, 3 Ó gbèrò pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ láti di orísun omi ní ìta ìlú ńlá, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́. 4 Ọ̀pọ̀ ogun ọkùnrin péjọ, wọ́n sì dí gbogbo àwọn orísun àti àwọn omi tó ń sàn tí ó ń sàn gba ti ilẹ̀ naà. “Kí ni ó dé tí àwọn ọba Asiria fi wá tí wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ omi?” Wọ́n wí. 5 Nígbà náà ó ṣiṣẹ́ gidigidi ní títún gbogbo ara ògiri tí ó ti bàjẹ́ ṣe, ó sì ń kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ gíga sókè rẹ̀. Ó kọ́ ògiri mìíràn sí ìta. Ó sì tún pẹ̀lú ibi ìtẹ́jú ilé ní ti ìlú ńlá Dafidi. Ó ṣe ọ̀pọ̀ iye ohun ìjà àti àwọn àpáta.
6 Ó yan àwọn ìjòyè ológun sórí àwọn ènìyàn, ó sì pè wọ́n jọ, níwájú rẹ̀ ní ìbámu ní ìlú ńlá ti Dafidi. Ó sì ki wọ́n láyà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: 7 “Ẹ jẹ́ alágbára, àti kí ẹ sì ní ìgboyà. Ẹ má ṣe bẹ̀rù tàbí ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nítorí tí ọba Asiria àti ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ̀, nítorí tí agbára ńlá wà pẹ̀lú wa ju òun lọ. 8 Agbára ẹran-ara nìkan ni ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣùgbọ́n, Ọlọ́run wa pẹ̀lú wa láti ràn wá lọ́wọ́ àti láti ja ìjà wa.” Àwọn ènìyàn sì ní ìgboyà láti ara ohun tí Hesekiah ọba Juda wí.
9 (B)Lẹ́yìn ìgbà tí Sennakeribu ọba Asiria àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ ń gbógun sí Lakiṣi. Ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú iṣẹ́ yí fún Hesekiah ọba Juda àti fún gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí ó wà níbẹ̀:
10 “Èyí ni ohun tí Sennakeribu ọba Asiria wí: Lórí kí ni ẹ̀yin gbé ìgbẹ́kẹ̀lé yín lé, tí ẹ̀yin fi dúró sí Jerusalẹmu lábẹ́ ìgbógun sí? 11 Nígbà tí Hesekiah wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run wa yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria,’ ó ń ṣì yín tọ́ ṣọ́nà, kí ẹ bá lè kú fún ebi àti òǹgbẹ. 12 Ṣé Hesekiah fúnrarẹ̀ kò mú àwọn ọlọ́run ibi gíga àti àwọn pẹpẹ kúrò, tí ó ń wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ kan àti láti sun àwọn ẹbọ lórí rẹ̀’?
13 “Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ ohun tí èmi àti àwọn baba mi ti ṣe sí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn? Ǹjẹ́ àwọn Ọlọ́run tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ní agbára láti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi? 14 Ta ni nínú gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tí àwọn baba mi ti parun, tí ó le gbà ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ mi, tí Ọlọ́run yín yóò fi le gbà yín lọ́wọ́ mi? 15 Nísinsin yìí, ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah ó tàn yín àti ṣì yín tọ́ ṣọ́nà báyìí. Ẹ má ṣe gbà á gbọ́, nítorí tí kò sí ọlọ́run orílẹ̀-èdè mìíràn tàbí ìjọba tí ó ní agbára láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi tàbí lọ́wọ́ àwọn baba mi, mélòó mélòó wa ni Ọlọ́run yín tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi!”
16 Àwọn ìjòyè Sennakeribu sọ̀rọ̀ síwájú sí i ní ìlòdì sí Olúwa Ọlọ́run àti sí ìránṣẹ́ rẹ̀ Hesekiah. 17 Ọba pẹ̀lú sì kọ àwọn ìwé ní bíbú Olúwa Ọlọ́run Israẹli àti ní sísọ èyí ní ìlòdì sí: “Ní gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn kò ṣe gba àwọn ènìyàn wọn kúrò lọ́wọ́ mi. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run Hesekiah kì yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi.” 18 Lẹ́yìn náà wọ́n pè jáde ní èdè Heberu sí àwọn ènìyàn Jerusalẹmu tí ó wà lára ògiri, láti dá ọjọ́ fún wọn, ki wọn kí ó lè fi agbára mú ìlú náà. 19 Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run Jerusalẹmu bí wọ́n ti ṣe nípa àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn mìíràn ti àgbáyé, iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn.
20 Ọba Hesekiah àti wòlíì Isaiah ọmọ Amosi sọkún jáde nínú àdúrà sí ọ̀run nípa èyí. 21 Olúwa sì ran angẹli tí ó pa gbogbo àwọn ọmọ-ogun àti àwọn adarí àti àwọn ìjòyè tí ó wà nínú àgọ́ ọba Asiria run. Bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí ilẹ̀ rẹ̀ ní ìtìjú. Nígbà tí ó sì lọ sínú ilé ọlọ́run rẹ̀, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.
22 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yọ Hesekiah àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu kúrò lọ́wọ́ Sennakeribu ọba Asiria àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn mìíràn. Ó tọ́jú wọn ní gbogbo ọ̀nà. 23 Ọ̀pọ̀ mú ọrẹ wá sí Jerusalẹmu fún Olúwa àti àwọn ẹ̀bùn iyebíye fún Hesekiah ọba Juda. Ó sì gbéga lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́yìn náà.
Ìgbéraga, àṣeyọrí àti ikú Hesekiah
24 (C)Ní ọjọ́ wọ́n nì Hesekiah ṣe àárẹ̀, ó sì dójú ikú. Ó gbàdúrà sí Olúwa tí ó dá a lóhùn, tí ó sì fún un ní ààmì àgbàyanu. 25 Ṣùgbọ́n ọkàn Hesekiah ṣe ìgbéraga, kò sì kọbi ara sí i inú rere tí a fihàn án. Nítorí náà, ìbínú Olúwa wà lórí rẹ̀ àti lórí Juda àti Jerusalẹmu. 26 Nígbà náà ni Hesekiah ronúpìwàdà ní ti ìgbéraga ọkàn rẹ̀, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu sì ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà, ìbínú Olúwa kò wá sí orí wọn ní ìgbà àwọn ọjọ́ Hesekiah.
27 Hesekiah ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá àti ọlá, ó sì ṣe àwọn ilé ìṣúra fún fàdákà àti wúrà rẹ̀ àti fún àwọn òkúta iyebíye rẹ̀, àwọn tùràrí olóòórùn dídùn àwọn àpáta àti gbogbo oríṣìí nǹkan iyebíye. 28 Ó kọ́ àwọn ilé pẹ̀lú láti tọ́jú àwọn ọkà àwọn tí wọ́n ka, ọtí tuntun àti òróró; ó sì ṣe àwọn àtíbàbà fún oríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn àti àwọn àṣémọ́ fun àwọn ọ̀wọ̀ ẹran. 29 Ó kọ́ àwọn ìletò, ó sì gba ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran, nítorí tí Ọlọ́run ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá.
30 Hesekiah ni ó dí ojú ìṣúra apá òkè ti orísun Gihoni. Ó sì gbe gba ìsàlẹ̀ sí ìhà ìwọ oòrùn ìlú ńlá ti Dafidi. Ó ṣe àṣeyọrí rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé. 31 Ṣùgbọ́n nígbà tí a rán àwọn oníṣẹ́ ọba wá láti Babeli láti bi í lérè nípa ààmì ìyanu tí ó ṣẹlẹ̀ nì, Ọlọ́run fi sílẹ̀ láti dán an wò àti láti mọ gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́kàn rẹ̀.
32 Gbogbo iṣẹ́ yòókù ti ìjọba Hesekiah àti àwọn ìṣe rẹ̀, ìfarajì rẹ̀ ni a kọ sínú ìwé ìran wòlíì Isaiah ọmọ Amosi nínú ìwé àwọn ọba Juda àti Israẹli 33 Hesekiah sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sórí òkè níbi tí àwọn ibojì àwọn àtẹ̀lé Dafidi wà. Gbogbo Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni ó bu ọlá fún un nígbà tí ó kú. Manase ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.