Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Historical

Read the books of the Bible as they were written historically, according to the estimated date of their writing.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Esra 3-5

Títún pẹpẹ kọ́

Nígbà tí ó di oṣù keje tí àwọn ọmọ Israẹli sì ti wà nínú àwọn ìlú wọn, àwọn ènìyàn péjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ní Jerusalẹmu. (A)Nígbà náà ni Jeṣua ọmọ Josadaki àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti àwọn ènìyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ pẹpẹ Ọlọ́run Israẹli láti rú ẹbọ sísun níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a ti kọ sínú ìwé òfin Mose ènìyàn Ọlọ́run Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ẹ̀rù àwọn ènìyàn tí ó yí wọn ká ń bà wọ́n síbẹ̀, wọ́n kọ́ pẹpẹ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ sí Olúwa, ọrẹ àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́. Nígbà náà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ, wọ́n ṣe àjọ àgọ́ ìpàdé pẹ̀lú iye ẹbọ sísun tí a fi lélẹ̀ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun àtìgbàdégbà, ẹbọ oṣù tuntun àti gbogbo àwọn ẹbọ fún gbogbo àpèjẹ tí a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, àti àwọn tí a mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá fún Olúwa. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní rú ẹbọ sísun sí Olúwa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ì tí ì fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀.

Títún tẹmpili kọ́

Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ní owó, wọ́n sì tún fi oúnjẹ, ohun mímu àti òróró fún àwọn ará Sidoni àti Tire, kí wọ́n ba à le è kó igi kedari gba ti orí omi Òkun láti Lebanoni wá sí Joppa, gẹ́gẹ́ bí Kirusi ọba Persia ti pàṣẹ.

Ní oṣù kejì ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n ti padà dé sí ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Jeṣua ọmọ Josadaki àti àwọn arákùnrin yòókù (àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti gbogbo àwọn tí ó ti ìgbèkùn dé sí Jerusalẹmu) bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Wọ́n sì yan àwọn ọmọ Lefi tí ó tó ọmọ-ogun ọdún sókè láti máa bojútó kíkọ́ ilé Olúwa. Jeṣua àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti Kadmieli àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ Juda (àwọn ìran Hodafiah) àti àwọn ọmọ Henadadi àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn—gbogbo ará Lefi—parapọ̀ láti bojútó àwọn òṣìṣẹ́ náà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí í kíkọ́ ilé Ọlọ́run.

10 Nígbà tí àwọn ọ̀mọ̀lé gbé ìpìlẹ̀ ilé Olúwa kalẹ̀, àwọn àlùfáà nínú aṣọ iṣẹ́ àlùfáà wọn pẹ̀lú fèrè, àti àwọn ará Lefi (àwọn ọmọ Asafu) pẹ̀lú símbálì, dúró ní ipò wọn láti yin Olúwa, bí Dafidi ọba Israẹli ti fi lélẹ̀. 11 Pẹ̀lú ìyìn àti ọpẹ́ ni wọ́n kọrin sí Olúwa:

“Ó dára;
    ìfẹ́ rẹ̀ sí Israẹli dúró títí láé.”

Gbogbo àwọn ènìyàn sì fi ohùn ariwo ńlá yin Olúwa, nítorí tí a ti fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀. 12 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ lára àwọn àgbà àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti àwọn olórí ìdílé, tí ó ti rí tẹmpili Olúwa ti tẹ́lẹ̀, wọ́n sọkún kíkorò nígbà tí wọ́n rí ìpìlẹ̀ tẹmpili Olúwa yìí tí wọ́n fi lélẹ̀, nígbà tí ọ̀pọ̀ kígbe fún ayọ̀. 13 Kò sí ẹni tí ó le mọ ìyàtọ̀ láàrín igbe ayọ̀ àti ẹkún, nítorí tí ariwo àwọn ènìyàn náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. Wọ́n sì gbọ́ igbe náà ní ọ̀nà jíjìn réré.

Àtakò sí àtúnkọ́ tẹmpili

Nígbà tí àwọn ọ̀tá Juda àti Benjamini gbọ́ wí pé àwọn ìgbèkùn tí ó padà dé ń kọ́ tẹmpili fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Serubbabeli àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé, wọ́n sì wí pé, “Jẹ́ kí a bá a yín kọ́ nítorí pé, bí i tiyín, a ń wá Ọlọ́run yín, a sì ti ń rú ẹbọ sí i láti ìgbà Esarhadoni ọba Asiria, tí ó mú wa wá sí ibi yìí.”

Ṣùgbọ́n Serubbabeli, Jeṣua àti ìyókù àwọn olórí àwọn ìdílé Israẹli dáhùn pé, “Ẹ kò ní ohunkóhun pẹ̀lú wa ní kíkọ́ ilé fún Ọlọ́run wa. Àwa nìkan yóò kọ́ ọ fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, bí Kirusi, ọba Persia, ti pàṣẹ fún wa.”

Nígbà náà ni àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú ọwọ́ àwọn ènìyàn Juda rọ, wọ́n sì dẹ́rùbà wọ́n ní ti kíkọ́ ilé náà. Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn láti ṣiṣẹ́ lòdì sí wọn àti láti sọ ète wọn di asán ní gbogbo àsìkò ìjọba Kirusi ọba Persia àti títí dé ìgbà ìjọba Dariusi ọba Persia.

Títako títún Jerusalẹmu kọ́

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Ahaswerusi wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu.

Àti ní àkókò ìjọba Artasasta ọba Persia, Biṣilami, Mitredati, Tabeli àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù kọ̀wé sí Artasasta. A kọ ìwé náà ní ìlànà ìkọ̀wé Aramaiki èdè Aramaiki sì ní a fi kọ ọ́.

Rehumu balógun àti Ṣimṣai akọ̀wé jùmọ̀ kọ́ ìwé láti dojúkọ Jerusalẹmu sí Artasasta ọba báyìí:

Rehumu balógun àti Ṣimṣai akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tókù—àwọn ará Dina, ti Afarsatki, ti Tarpeli, ti Afarsi, Ereki àti Babeli, àwọn ará Elamu ti Susa, 10 pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn tí ẹni ọlá àti ẹni ọ̀wọ̀ Asnappari kó jáde, tí ó sì tẹ̀ wọ́n dó sí ìlú Samaria àti níbòmíràn ní agbègbè e Eufurate.

11 (Èyí ni ẹ̀dà ìwé tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i.)

Sí ọba Artasasta,

Láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin agbègbè Eufurate:

12 Ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé àwọn ará Júù tí ó gòkè wá sọ́dọ̀ wa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ti lọ sí Jerusalẹmu wọ́n sì ń tún ìlú búburú àti ìlú ọlọ̀tẹ̀ ẹ nì kọ́. Wọ́n ń tún àwọn ògiri náà kọ́, wọ́n sì ń tún àwọn ìpìlẹ̀ náà ṣe.

13 Síwájú sí i, ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé tí a bá kọ́ ìlú yìí àti tí a sì tún àwọn ògiri rẹ̀ mọ, kò sí owó orí, owó òde tàbí owó ibodè tí a ó san, owó tí ó sì ń wọlé fún ọba yóò sì dínkù. 14 Nísinsin yìí níwọ̀n ìgbà tí a ní ojúṣe sí ààfin ọba, kò sì bójúmu fún wa láti rí ìtàbùkù ọba, àwa ń rán iṣẹ́ yìí láti sọ fún ọba, 15 kí a bá a lè ṣe ìwádìí ní inú ìwé ìrántí àwọn aṣíwájú rẹ̀. Nínú ìwé ìrántí wọn yìí, ìwọ yóò rí i wí pé, ìlú yìí jẹ́ ìlú aṣọ̀tẹ̀, oníwàhálà sí àwọn ọba àti àwọn ìgbèríko, ibi ìṣọ̀tẹ̀ láti ìgbà àtijọ́. Ìdí ni èyí tí a ṣe pa ìlú yìí run. 16 A fi dá ọba lójú wí pé tí a bá tún ìlú kọ́ àti ti àwọn ògiri rẹ̀ si di mímọ padà, kì yóò sì ohun ti yóò kù ọ́ kù ní agbègbè Eufurate.

17 Ọba fi èsì yìí ránṣẹ́ padà:

Sí Rehumu balógun, Ṣimṣai akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù tí ń gbé ní Samaria àti ní òpópónà Eufurate:

Ìkíni.

18 A ti ka ìwé tí ẹ fi ránṣẹ́ sí wa, a sì ti túmọ̀ rẹ̀ níwájú mi. 19 Mo pa àṣẹ, a sì ṣe ìwádìí, nínú ìtàn ọjọ́ pípẹ́ àti ti ìsinsin yìí ti ìṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba pẹ̀lú, ó sì jẹ́ ibi ìṣọ̀tẹ̀ àti ìrúkèrúdò. 20 Jerusalẹmu ti ní àwọn ọba alágbára tí ń jẹ ọba lórí gbogbo àwọn agbègbè Eufurate, àti àwọn owó orí, owó òde àti owó ibodè sì ni wọ́n ń san fún wọn. 21 Nísinsin yìí pa àṣẹ fún àwọn ọkùnrin yìí láti dá iṣẹ́ dúró, kí a má ṣe tún ìlú náà kọ títí èmi yóò fi pàṣẹ. 22 Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe àìkọbi-ara sí ọ̀rọ̀ yìí. Èéṣe tí ìbàjẹ́ yóò fi pọ̀ sí i, sí ìpalára àwọn ọba?

23 Ní kété tí a ka ẹ̀dà ìwé ọba Artasasta sí Rehumu àti Ṣimṣai akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, wọ́n yára lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní Jerusalẹmu pẹ̀lú, wọ́n fi agbára mú wọn láti dáwọ́ dúró.

24 Báyìí, iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu wá sí ìdúró jẹ́ẹ́ títí di ọdún kejì ìjọba Dariusi ọba Persia.

Lẹ́tà Tatenai sí Dariusi

(B)Nígbà náà wòlíì Hagai àti wòlíì Sekariah, láti ìran Iddo, sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ará Júù ní Juda àti Jerusalẹmu ní orúkọ Ọlọ́run Israẹli tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bẹ lára wọn. Nígbà náà Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti Jeṣua ọmọ Josadaki gbáradì fún iṣẹ́ àti tún ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu kọ́. Àwọn wòlíì Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, tí wọ́n ń ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ní àkókò náà Tatenai, baálẹ̀ ti agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹgbẹgbẹ́ wọn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n sì béèrè pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún tẹmpili yìí kọ́ àti láti tún odi yìí mọ?” Wọ́n sì tún béèrè pé, “Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí ó ń kọ́ ilé yìí?” Ṣùgbọ́n ojú Ọlọ́run wọn wà lára àwọn àgbàgbà Júù, wọn kò sì dá wọn dúró títí ìròyìn yóò fi dè ọ̀dọ̀ Dariusi kí wọ́n sì gba èsì tí àkọsílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà tí Tatenai, olórí agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn. Àwọn olóyè ti agbègbè Eufurate, fi ránṣẹ́ sí ọba Dariusi. Ìròyìn tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i kà báyìí pé:

Sí ọba Dariusi:

Àlàáfíà fún un yín.

Kí ọba kí ó mọ̀ pé a lọ sí ẹ̀kún Juda, sí tẹmpili Ọlọ́run tí ó tóbi. Àwọn ènìyàn náà ń kọ́ ọ pẹ̀lú àwọn òkúta ńláńlá àti pẹ̀lú fífi àwọn igi sí ara ògiri. Wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àìsimi, ó sì ń ní ìtẹ̀síwájú kíákíá lábẹ́ ìṣàkóso wọn.

A bi àwọn àgbàgbà, a sì fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún ilé Olúwa yìí kọ́ àti láti tún odi rẹ̀ mọ?” 10 A sì tún béèrè orúkọ wọn pẹ̀lú, kí a lè kọ àwọn orúkọ àwọn olórí wọn sílẹ̀ kí ẹ ba à le mọ ọ́n.

11 Èyí ni ìdáhùn tí wọ́n fún wa:

“Àwa ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, àwa sì ń tún tẹmpili ilé Olúwa tí a ti kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kọ́, èyí tí ọba olókìkí kan ní Israẹli kọ́, tí ó sì parí i rẹ̀. 12 Ṣùgbọ́n nítorí tí àwọn baba wa mú Ọlọ́run ọ̀run bínú, ó fi wọ́n lé Nebukadnessari ti Kaldea, ọba Babeli lọ́wọ́, ẹni tí ó run tẹmpili Olúwa yìí tí ó sì kó àwọn ènìyàn náà padà sí Babeli.

13 (C)“Ṣùgbọ́n ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba Kirusi ọba Babeli, ọba Kirusi pàṣẹ pé kí a tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́. 14 Òun tilẹ̀ kò jáde láti inú tẹmpili ní babeli fàdákà àti ohun èlò wúrà ilé Ọlọ́run, èyí tí Nebukadnessari kó láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu wá sí inú tẹmpili ní Babeli. Ọba Kirusi kó wọn fún ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣeṣbassari, ẹni tí ó ti yàn gẹ́gẹ́ bí i baálẹ̀, 15 ó sì sọ fún un pé, ‘Kó àwọn ohun èlò yìí kí o lọ, kí o sì kó wọn sí inú ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, kí ẹ sì tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí ipò o rẹ̀.’

16 “Nígbà náà ni Ṣeṣbassari náà wá, ó sí fi ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run tí ó wá ní Jerusalẹmu lélẹ̀, láti ìgbà náà àní títí di ìsinsin yìí ni o ti n bẹ ní kíkọ́ ṣùgbọ́n, kò sí tí ì parí tán.”

17 Nísinsin yìí tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí ní ilé ìṣúra ọba ní Babeli láti rí bí ọba Kirusi fi àṣẹ lélẹ̀ lóòótọ́ láti tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́ ní Jerusalẹmu. Nígbà náà jẹ́ kí ọba kó fi ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sí wa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.