Read the Gospels in 40 Days
Jesu gbàdúrà fún ara rẹ̀
17 (A)Nǹkan wọ̀nyí ni Jesu sọ, ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ó sì wí pé:
“Baba, wákàtí náà dé, yin ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ kí ó lè yìn ọ́ lógo pẹ̀lú. 2 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fún un ní àṣẹ lórí ènìyàn gbogbo, kí ó lè fi ìyè àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó fi fún un. 3 Ìyè àìnípẹ̀kun náà sì ni èyí, kí wọn kí ó lè mọ ìwọ nìkan Ọlọ́run òtítọ́, àti Jesu Kristi, ẹni tí ìwọ rán. 4 Èmi ti yìn ọ́ lógo ní ayé: èmi ti parí iṣẹ́ tí ìwọ fi fún mi láti ṣe. 5 (B)Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Baba, ṣe mí lógo pẹ̀lú ara rẹ, ògo tí mo ti ní pẹ̀lú rẹ kí ayé kí ó tó wà.
Jesu gbàdúrà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn
6 “Èmi ti fi orúkọ rẹ hàn fún àwọn ènìyàn tí ìwọ ti fún mi láti inú ayé wá: tìrẹ ni wọ́n ti jẹ́, ìwọ sì ti fi wọ́n fún mi; wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́. 7 Nísinsin yìí, wọ́n mọ̀ pé ohunkóhun gbogbo tí ìwọ ti fi fún mi, láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni. 8 Nítorí ọ̀rọ̀ tí ìwọ fi fún mi, èmi ti fi fún wọn, wọ́n sì ti gbà á, wọ́n sì ti mọ̀ nítòótọ́ pé, lọ́dọ̀ rẹ ni mo ti jáde wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi. 9 (C)Èmi ń gbàdúrà fún wọn: èmi kò gbàdúrà fún aráyé, ṣùgbọ́n fún àwọn tí ìwọ ti fi fún mi; nítorí pé tìrẹ ni wọ́n í ṣe. 10 Tìrẹ sá à ni gbogbo ohun tí í ṣe tèmi, àti tèmi sì ni gbogbo ohun tí í ṣe tìrẹ, a sì ti ṣe mí lógo nínú wọn. 11 (D)Èmi kò sí ní ayé mọ́, àwọn wọ̀nyí sì ń bẹ ní ayé, èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́, ní orúkọ rẹ, kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, àní gẹ́gẹ́ bí àwa. 12 (E)Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn ní ayé, mo pa wọ́n mọ́ ní orúkọ rẹ; àwọn tí ìwọ fi fún mi, ni mo ti pamọ́, ẹnìkan nínú wọn kò sọnù bí kò ṣe ọmọ ègbé; kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ.
13 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, nǹkan wọ̀nyí ni mo sì ń sọ ní ayé, kí wọn kí ó lè ní ayọ̀ mi ní kíkún nínú àwọn tìkára wọn. 14 (F)Èmi ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn; ayé sì ti kórìíra wọn, nítorí tí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. 15 Èmi kò gbàdúrà pé, kí ìwọ kí ó mú wọn kúrò ní ayé, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó pa wọ́n mọ́ kúrò nínú ibi. 16 Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. 17 Sọ wọ́n di mímọ́ nínú òtítọ́: òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ. 18 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti rán mi wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán wọn sí ayé pẹ̀lú. 19 Èmi sì ya ara mi sí mímọ́ nítorí wọn, kí a lè sọ àwọn tìkára wọn pẹ̀lú di mímọ́ nínú òtítọ́.
Jesu gbàdúrà fún gbogbo onígbàgbọ́
20 “Kì sì í ṣe kìkì àwọn wọ̀nyí ni mo ń gbàdúrà fún, ṣùgbọ́n fún àwọn pẹ̀lú tí yóò gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn; 21 (G)Kí gbogbo wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan; gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti jẹ́ nínú mi, àti èmi nínú rẹ, kí àwọn pẹ̀lú kí ó lè jẹ́ ọ̀kan nínú wa: kí ayé kí ó lè gbàgbọ́ pé, ìwọ ni ó rán mi. 22 Ògo tí ìwọ ti fi fún mi ni èmi sì ti fi fún wọn; kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́ ọ̀kan; 23 Èmi nínú wọn, àti ìwọ nínú mi, kí a lè ṣe wọ́n pé ní ọ̀kan; kí ayé kí ó lè mọ̀ pé, ìwọ ni ó rán mi, àti pé ìwọ sì fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́ràn mi.
24 (H)“Baba, èmi fẹ́ kí àwọn tí ìwọ fi fún mi, kí ó wà lọ́dọ̀ mi, níbi tí èmi gbé wà; kí wọn lè máa wo ògo mi, tí ìwọ ti fi fún mi: nítorí ìwọ sá à fẹ́ràn mi síwájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.
25 “Baba olódodo, ayé kò mọ̀ ọ́n; ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, àwọn wọ̀nyí sì mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi. 26 Mo ti sọ orúkọ rẹ di mí mọ̀ fún wọn, èmi ó sì sọ ọ́ di mí mọ̀: kí ìfẹ́ tí ìwọ fẹ́ràn mi, lè máa wà nínú wọn, àti èmi nínú wọn.”
Wọ́n mú Jesu
18 (I)Nígbà tí Jesu sì ti sọ nǹkan wọ̀nyí tán, ó jáde pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sókè odò Kidironi, níbi tí àgbàlá kan wà, nínú èyí tí ó wọ̀, Òun àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
2 Judasi, ẹni tí ó fihàn, sì mọ ibẹ̀ pẹ̀lú: nítorí nígbà púpọ̀ ni Jesu máa ń lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 3 (J)Nígbà náà ni Judasi, lẹ́yìn tí ó ti gba ẹgbẹ́ ọmọ-ogun, àti àwọn oníṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi wá síbẹ̀ ti àwọn ti fìtílà àti ògùṣọ̀, àti ohun ìjà.
4 (K)Nítorí náà bí Jesu ti mọ ohun gbogbo tí ń bọ̀ wá bá òun, ó jáde lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni ẹyin ń wá?”
5 Wọ́n sì dá a lóhùn wí pé, “Jesu ti Nasareti.”
Jesu sì wí fún wọn pé, “Èmi nìyí.” (Àti Judasi ọ̀dàlẹ̀, dúró pẹ̀lú wọn.) 6 Nítorí náà bí ó ti wí fún wọn pé, “Èmi nìyí,” wọ́n bì sẹ́yìn, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀.
7 Nítorí náà ó tún bi wọ́n léèrè, wí pé, “Ta ni ẹ ń wá?”
Wọ́n sì wí pé, “Jesu ti Nasareti.”
8 Jesu dáhùn pé, “Mo ti wí fún yín pé, èmi nìyí: ǹjẹ́ bí èmi ni ẹ bá ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí máa lọ: 9 (L)Kí ọ̀rọ̀ nì kí ó lè ṣẹ, èyí tó wí pé, Àwọn tí ìwọ fi fún mi, èmi kò sọ ọ̀kan nù nínú wọn.”
10 Nígbà náà ni Simoni Peteru ẹni tí ó ní idà, fà á yọ, ó sì ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì ké etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù. Orúkọ ìránṣẹ́ náà a máa jẹ́ Mákọ́ọ̀sì.
11 (M)Nítorí náà Jesu wí fún Peteru pé, “Tẹ idà rẹ bọ inú àkọ̀ rẹ: ago tí baba ti fi fún mi, èmi ó ṣe aláìmu ún bí?”
Jesu níwájú Annasi
12 (N)Nígbà náà ni ẹgbẹ́ ọmọ-ogun àti olórí ẹ̀ṣọ́, àti àwọn oníṣẹ́ àwọn Júù mú Jesu, wọ́n sì dè é. 13 Wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sọ́dọ̀ Annasi; nítorí òun ni àna Kaiafa, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà. 14 (O)Kaiafa sá à ni ẹni tí ó ti bá àwọn Júù gbìmọ̀ pé, ó ṣàǹfààní kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn.
Peteru sẹ́ Jesu ní àkọ́kọ́
15 (P)Simoni Peteru sì ń tọ Jesu lẹ́yìn, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn kan: ọmọ-ẹ̀yìn náà jẹ́ ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà, ó sì bá Jesu wọ ààfin olórí àlùfáà lọ. 16 Ṣùgbọ́n Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà lóde. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà tí í ṣe ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà jáde, ó sì bá olùṣọ́nà náà sọ̀rọ̀, ó sì mú Peteru wọlé.
17 (Q)Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà tí ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà wí fún Peteru pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkùnrin yìí bí?”
Ó wí pé, “Èmi kọ́.”
18 Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àti àwọn aláṣẹ sì dúró níbẹ̀, àwọn ẹni tí ó ti dáná nítorí ti òtútù mú, wọ́n sì ń yáná: Peteru sì dúró pẹ̀lú wọn, ó ń yáná.
Alábojútó àlùfáà fi ọ̀rọ̀ wá Jesu lẹ́nu wò
19 (R)Nígbà náà ni olórí àlùfáà bi Jesu léèrè ní ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ní ti ẹ̀kọ́ rẹ̀.
20 Jesu dá a lóhùn pé, “Èmi ti sọ̀rọ̀ ní gbangba fún aráyé; nígbà gbogbo ni èmi ń kọ́ni nínú Sinagọgu, àti ní tẹmpili níbi tí gbogbo àwọn Júù ń péjọ sí: èmi kò sì sọ ohun kan ní ìkọ̀kọ̀. 21 Èéṣe tí ìwọ fi ń bi mí léèrè? Béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ó ti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ohun tí mo wí fún wọn: wò ó, àwọn wọ̀nyí mọ ohun tí èmi wí.”
22 Bí ó sì ti wí èyí tan, ọ̀kan nínú àwọn aláṣẹ tí ó dúró tì í fi ọwọ́ rẹ̀ lu Jesu, pé, “alábojútó àlùfáà ni ìwọ ń dá lóhùn bẹ́ẹ̀?”
23 (S)Jesu dá a lóhùn pé, “Bí mo bá sọ̀rọ̀ búburú, jẹ́rìí sí búburú náà: ṣùgbọ́n bí rere bá ni, èéṣe tí ìwọ fi ń lù mí?” 24 (T)Nítorí Annasi rán an lọ ní dídè sọ́dọ̀ Kaiafa olórí àlùfáà.
Peteru sẹ́ Jesu ní ìgbà kejì àti ìgbà kẹta
25 (U)Ṣùgbọ́n Simoni Peteru dúró, ó sì ń yáná. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀?”
Ó sì sẹ́, wí pé, “Èmi kọ́.”
26 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, tí ó jẹ́ ìbátan ẹni tí Peteru gé etí rẹ̀ sọnù, wí pé, “Èmi ko ha rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ ní àgbàlá?” 27 Peteru tún sẹ́: lójúkan náà àkùkọ sì kọ.
Jesu níwájú Pilatu
28 (V)Nígbà náà, wọ́n fa Jesu láti ọ̀dọ̀ Kaiafa lọ sí ibi gbọ̀ngàn ìdájọ́: ó sì jẹ́ kùtùkùtù òwúrọ̀; àwọn tìkára wọn kò wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́, kí wọn má ṣe di aláìmọ́, ṣùgbọ́n kí wọn lè jẹ àsè ìrékọjá. 29 (W)Nítorí náà Pilatu jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí pé, “Ẹ̀sùn kín ní ẹ̀yin mú wá fun ọkùnrin yìí?”
30 Wọ́n sì dáhùn wí fún un pé, “Ìbá má ṣe pé ọkùnrin yìí ń hùwà ibi, a kì bá tí fà á lé ọ lọ́wọ́.”
31 Nítorí náà Pilatu wí fún wọn pé, “Ẹ mú un tìkára yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òfin yín.”
Nítorí náà ni àwọn Júù wí fún un pé, “Kò tọ́ fún wa láti pa ẹnikẹ́ni.” 32 (X)Kí ọ̀rọ̀ Jesu ba à lè ṣẹ, èyí tí ó sọ tí ó ń ṣàpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóò kú.
33 Nítorí náà, Pilatu tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì pe Jesu, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ha ni a pè ni ọba àwọn Júù bí?”
34 Jesu dáhùn pé, “Èrò ti ara rẹ ni èyí, tàbí àwọn ẹlòmíràn sọ ọ́ fún ọ nítorí mi?”
35 Pilatu dáhùn wí pé, “Èmi ha jẹ́ Júù bí? Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ, àti àwọn olórí àlùfáà ni ó fà ọ́ lé èmi lọ́wọ́: kín ní ìwọ ṣe?”
36 (Y)Jesu dáhùn wí pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí. Ìbá ṣe pé ìjọba mi jẹ́ ti ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ìbá jà, kí a má ba à fi mí lé àwọn Júù lọ́wọ́: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba mi kì í ṣe láti ìhín lọ.”
37 (Z)Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “ọba ni ọ́ nígbà náà?”
Jesu dáhùn wí pé, “Ìwọ wí pé, ọba ni èmi jẹ́. Nítorí èyí ni a ṣe bí mí, àti nítorí ìdí èyí ni mo sì ṣe wá sí ayé kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́, olúkúlùkù ẹni tí í ṣe ti òtítọ́ ń gbọ́ ohùn mi.”
38 (AA)Pilatu wí fún un pé, “Kín ni òtítọ́?” Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó tún jáde tọ àwọn Júù lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀. 39 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní àṣà kan pé, kí èmi dá ọ̀kan sílẹ̀ fún yín nígbà àjọ ìrékọjá: nítorí náà ẹ ó ha fẹ́ kí èmi dá ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yín bí?”
40 Nítorí náà gbogbo wọn tún kígbe pé, “Kì í ṣe ọkùnrin yìí, bí kò ṣe Baraba!” Ọlọ́ṣà sì ni Baraba.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.